4.02 - ÌFÀÁRÀ SÍ ÒFIN MẸ́WÀÁ: Ọlọ́run fí ara rẹ̀ hàn
EKISODU 20:2
Èmí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Egypt wá, láti ilẹ̀ ìgbèkùn.
Òfin mẹ́wàá kò la ètọ̀ òfin tí ó jẹ́ ìtéwúgbà èyí tí ańgẹ́lì là sílẹ̀ lé àwọn ènìyàn lórí, yálà béẹ̀ Ọlọ́run fúnrarẹ̀ bá ènìyàn sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ wọn, asẹ́dàá súnmọ́ àwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀, ẹni mímọ́ nì sì súnmọ́ àwọn ẹlésẹ̀.
4.02.1 - Àbùdá Ọlọ́run
Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú àkọ́jọpọ̀ òfin mẹ́wàá ni “Èmí” Ọlọ́run alaàyè bá wa sọ̀rọ̀ fúnrarẹ̀ kìí ṣe bí ẹ̀mí àìrí kan tàbí ìró àrá tí ó dérùbani tí a gbọ́ lokeere. Èdè rẹ̀ kò nira láti gbọ́. O sì fẹ́ láti ní ìfarakínra tí ó ṣe é fọkàntán dẹ́ni sí ẹni pẹ̀lú wa. Ó ń fi oorẹ ọ̀fẹ́ bá wà sọ̀rọ̀, kìí ṣe nipá òfin tàbí ìbínú. Irú ànfààní ńlá wo ni èyí nínú èyí tí Ọlọ́run ń fí àánú àti ifẹ́ bá wá lò.
Ènìyàn lè fi oríkunkun gbìyànjú láti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run alágbára, kí wọn ó sì pàdánù ìbùkún rẹ̀. Síbẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ rí wa níbikíbi tí a bá wà. Nítorí pé, ojú Olúwa wà ní ibi gbogbo. Ìdí niyí tí gbogbo ọlọ́gbọ́ ẹ̀nìyàn fi gbọ́dọ̀ gbà ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Nítorí pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀mí tumọ sí pé a tí gbé wa ga sí àkàbà “iwọ” a sì ní oorẹ ọ̀fẹ́ láti bá a sọ̀rọ̀ nítorí pé a ní àmì ìdánimọ̀ kan náà pẹ̀lú rẹ̀.
Nítorí ìdí èyí, ó hàn gbangba gbàngbà pé Ọlọ́run ayérayé fúnra rẹ̀ òpómúléró gbogbo ènìyàn àti onídájọ́ ayérayé ń bá wa sọ̀rọ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jé síi, kí á sì fí àyọ̀ àti ìdùnnú pá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.
4.02.2 - Ìwàláàyè Ọlọ́run
Ọlọ́run fí isé pàtàkì rẹ̀ sí a hàn nígbà tí ó sọ pé “ẹ̀mí ni”. Kí lọ́ wá fàá tí àwọn ènìyàn kan fí ń pàríwó pé kò sí Ọlọ́run? Gbogbo àwáwí àwọn ènìyàn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà yìí forísánpọ́n níwájú ẹ̀rí Ọlọ́run yìí, níwọ̀n bí ó tí jẹ́ pé “ẹ̀mí ni” fúnra rẹ̀ ni ìdí ìwàláàyè wa. Ọlọ́run wà láàyè bí ohun gbogbo tilẹ̀ ń kọjá lọ. Òun nìkan ni ó wà títí layé. Bí ẹni tí ó ń kojú ìjà sí òkè ńlá ní àkókò àti ènìyàn pẹ̀lú ń sọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, òtítọ́ ìwàláàyè rẹ̀ kò wà nínú ohun tí ènìyàn sọ nípa Ọlọ́run tàbí àwárí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì kọ nípa rẹ̀. Òun ni ọ̀nà òtítọ́, agbára rẹ̀ sì kárí gbogbo ayé. Ní ìwọn ègbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, àwọn ènìyàn kan sẹ́ òtítọ́ yìí, ní akókó Dáfídì wọ̀n sì jẹ́wọ pé kò sí Ọlọ́run (Orin Dáfídì 14). Onísáàmù pè wọ́n ní asiwèrè oníbájẹ̀ nítorí pé wọ́n kọ ẹ̀yìn sí òtítọ́, wọ́n sì sáátá ẹni náà tí ó di gbogbo ayé mú tí ó sì gbé e dúró, síbẹ̀, àwọn aláìgbàgbọ́ ń mòòkùn nínú ẹ̀sẹ̀ wọn láìní ẹ̀rí ọkàn. Èrí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ tòdi sí gbèdéke lórí èyí tí ẹ̀sìn Búdi dúró lé. Nirvana tòun tẹ̀kó rẹ̀ nípa ìsẹ́-ara ẹni àti pípa ewù run de ibi tí a ó fí gbà ọkàn wa láye láti mòòkùn nínú nnkan tí kò si ko tọ̀nà. Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ènìyàn wà láàyè. Òun fúnrarẹ̀ wà làyé, ó sì jẹ́rí síi “Èmi ni”. Pé ó wà láyé fún ayé wa ní èrèdí àti ìtumọ̀. ó fẹ́ kí á wà bi òun ṣe wà, kò sí nínú èròńgbà rẹ̀ pé kí a parun.
Ẹ̀rí Ọlọ́run tún pa gbogbo ẹ̀kọ́ ìkọ́rọ̀jo run. Ẹ̀nìyàn ẹlérò kúkúrú nìkan ni ò lé sẹ ìjótítọ́ ayé nínú ẹ̀mí. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ dàbí òkuta tí ó wà nílẹ̀ nígbà tí ẹyẹ rí fò lójú òrùn. Ọlọ́run wà láàyè, ó sì bá ọ sọ̀rọ̀. Ó tilẹ̀ bá àwọn tí ó ń kó ọ̀rọ̀ jọ lasan, àwọn tó ní kò sọ̀lọ́run àti àwọn alágbàgbó kí gbogbo ènyàn bá lé yí padà síi kí á sì gbọ́n. Bí ẹnikẹ́ni bá kò láti tẹ́tí tí ó sì ṣe ọkàn rẹ̀ lè, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò dàbí ọkùnrin afọ́jú tí ó sọ pé kò sí òòrùn nítorí òun kò lè rí i.
4.02.3 - Ta ni Yahweh?
Ọlọ́run sọ fún Mọse pé “Èmí ni Ọlọ́run”, “Èmí ni tí ń jẹ́ Èmí ni”. Ìtumọ̀ gbòógì fún ìpèdè yìí ní èdè Heberu nínú (Ekisodu 3:14) ni. Èyí sì ń sàfihàn ìwàláàyè ayérayé, tòótọ́, aláìlégbé tí Ọlọ́rún. Ọlọ́run wà ni ọ̀nà àrà tí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkohun le è rò. Kò yí pàdà, èyí sì ni ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa àti òkúta pàtàkì igunlé ìgbàgbọ́ wa pẹ̀lú gbogbo kùdìè kudìè àti ẹ̀sẹ̀ wa Ọlọ́run tí kìí yí padà jẹ́ olọ́títọ́ sí wa. A lẹ́tọ̀ọ́ láti padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ìjólótítọ́ rẹ̀, koda nígbà tí a ń dọjúkọ òpin ayé yìí. Ọlọ́run tù wá nínú. “Ayé òun ọ̀rùn yóò kojá, ṣùgbọ́n kíún nínú ọ̀rọ̀ mi kí yóò kojá bí ó tí wù kí ó rí (Matiu 24:35).
Ọlọ́run nínú agbára rẹ̀ rọ̀gbà yí ká ohun gbogbo, òun ní ó mọ́ ohun gbogbo, ó rí ohun gbogbo, àrágbáyamùyamú ìmọ̀ àti Ọlọ́run tí ó gbọn ju ẹnikẹ́ni lọ. Nígbà tí gbogbo ìlẹ̀kùn ṣé, ó la ọ̀nà àbáyọ sílẹ̀ fún wa. Ìmọ̀lára àti èrò wa yé ẹ. Kò fẹ́ kí a fí ìpọ́njú wọ́lẹ̀ ní ẹsẹ rẹ̀. Dipo bẹ́ẹ̀, ó gbín ìrèti àti ìgbàgbọ́ tí ó jìnlẹ̀ sí wa nínú. Ó bá wa sọ̀rọ̀ kí a baà lè fí ìgbàgbọ́ gbe ojú wa sòkè síí. Ohun ni ó jẹ́ Olúwa ayé wa, kí ẹnikẹ́ni máa báa pàdánù kúrò níwájú Ọlọ́run wa ó kún fún ìrẹ̀lẹ̀ nítorí ó ń dúró de ìdáhùn wa! Nígbà tí ẹnikan bá padà sí ọdọ ẹlẹ́dàá rẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń dáhùn sí àanú tí ó fí hàn pẹ̀lú ìfẹ́. Nígbà tí Ọlọ́run sọ pé, “Ẹ̀mi ni Oluwa”. Ó tún ń sọ pé òun ní Oluwa kansoso, kò sí elòmìíràn. Gbogbo àwọn ẹ̀mí àti òrìsà kéékèèkéé mìíràn si jẹ́ asán.
Ní òde òní, bí ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀mí àti àwọn nnkan meeriri tílẹ̀ tí yípadà sí ẹ̀sìn ìgbàlóde, síbẹ̀, àwọn tí ó ní ẹ̀mí èsù ń gba ìdándè nípa fífi ìgbékèlé wọn sínú Ọlọ́run tòótọ́. Lóde òní, ìgbàgbọ́ nínú isiyemeji pé Ọlọ́run wà tí ń dínkù, àwọn ẹ̀nìyàn sì ń fí gbogbo ọ̀nà wá agbára nínú èyí tí wọ́n ń fí ara wọn sínú ide ẹ̀mí òkùnkùn. Wọn sì ń fọn rere ayédèrú ìgbàgbọ́ wọn yí lórí rédíò, telifìsan, ìwé ìròyìn àti ní gbogbo ayé.
Nínú ìwé ihinrere, Jésù sọ wí pé, “Emi ni ẹni náà”, èyí tí ó jẹ́ apa kan nínú òfin méwàá bàyìí Jésù fi ìdí jíjẹ́ Olúwa rẹ múlẹ̀ nípa èyí àti pé òun sì ni kókó ìròyìn ayọ̀ tí áwọn áńgẹ́lì fifún àwọn olùsọ́ àgùntàn ni Bẹ́tílẹ́émù.
Jésù tún tèsíwájú nígbà tí ó sọ pé, “Emi ni ouńjẹ ìyè”, “Emi ni ìmólẹ̀ ayé”, “Emi ni ẹnu ọ̀nà”, “Emi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè”. Ò tún sọ wí pé, “Ọba ni mi”, “Emi ni ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin”. Láti ìgbà náà ni àwọn ọmọ èyìn rẹ̀ tí ń fọnrere rẹ pé “Jésù ni Olúwa” Kò yí padà, òun ni ó sì gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ ó fi ìdí àsẹ àti agbára rẹ̀ múlẹ̀ nípa jíjí wa dide kúrò nínú òkú. Láti ìgbà náà ni òfin mẹ́wàá tí ń fọn ìró ìtẹ́wọ́gbà pé “Emi ni Oluwa”. Mósè kò ní òye tí ó pé nípa èdá Olúwa rẹ̀ tí ó ń bọ̀. Ṣùgbọ́n, ó gba ìfihàn tí ó sẹ kókó nínú èyí tí Ọlọ́run tí sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún kan àti àádótadínníírinwó ọdún sáàjú ìbí Jésù. “Emi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ”.
4.02.4 - Ta ni Ọlọ́run
Ní èdè Hébérù, Ọlọ́run pé ara rẹ ní ELOHIM, èyí tí ó túmọ̀ sí “Allahu” ní èdé Árábíìkì”. A lè pé “ELOHIM” ni “ELOH-IM”, kí á sì pé ALLAH ni “Al-ei-hu”. Nínú àsà àwọn Áráàbù, átíkù a sọpatò ni Al nígbàti El jẹ́ orúkọ Ọlọ́run gan, ó sì túmọ̀ sí “agbára”.Jésù polongo ìsẹ pátàkì ìtúmọ̀ orúkọ yìí “EL”, ó sì fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nígbà tí ó ń jẹ́rìí níwájú ilé ejọ, “Lẹ́yìn èyí ni ẹ̀yin ó rí ọmọ ènìyàn tí ó jókòó ní owó òtún agbára” (Matiu 26:64). Àfòmó ìparí ni “-Im” àti “-hu”. Nínú èdè Heberu, ‘Im” dúró fún ọ̀pọ̀, nígbà tí “-hu” ní èdè Àrábíkì ní èdè túmọ̀ sí eyọ. Nítorí ìdí èyí, Allah kò fàyè gba ìsọ̀kàn métalọ̀kan mímó nígbà tí “Elohim” fí àyè gba Ọlọ́run métalọ̀kan.
Ọlọ́run ayérayé kìí ṣe pátápátá ìmọ́, pátápátá ọ̀gbọ́n, tàbí Ọlọ́run tí ó wà ní ibi gbogbo nìkan ṣùgbọ́n òun ni Ọlọ́run Olódùmarè. Òun ní agbára kan soso tí ó fi ọ̀rọ̀ sẹ̀dá ni gbogbo àgbáyé. Ó dá ayé láti inú asán. Ó ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. Ọlọ́run wa kìí ṣe apanirun tàbí ònroro tí ó lè dáàbò bo ẹni tí ó bá fẹ́ tàbí kí ó sí ẹni tí ó bá fẹ́ lọ̀nà (Sura al-fatir 35:8 àti al – Muddethir 74:31). Lọ̀nà mìíràn ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ kí “gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ òtítọ̀ (Tìmótíù Kínní 2:4).
Nínú májẹ̀mú láíláí, orúkọ àwọn ènìyàn kan àti orílẹ̀-èdè wọn so pọ̀ mọ́ EL. Wọn ń sọ́ àwọn ọmọ wọ́n ní orúkọ bí Samuẹlì, Elijah, Eliezar àti Dáníélì. Wọn a sì máa sọ ìlù ní orúkọ bí Bétẹ́lì, Jésírẹ́ẹ́lì àti Isírẹ́lì. Nípa báyìí, wọ́n sọ ara wọn mọ́ “agbára” tí ó ń dárí gbogbo àgbáyé. Nínú Májẹ̀mú Titun, àwọn ènìyàn wà ní ìsọ̀kàn pipe pẹ̀lú Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí ó ti sẹ̀lérí fún àwọn àtèle rẹ̀ pé, “Èyìn yóò gba agbára nígbàtí Èmí Mímọ́ bá bà lée yín” (Ise Àwọn Àpọ́sítélì 1:8). Ọlọ́run kò ko ẹlẹ́sẹ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n ó wẹ̀ wọ́n nù, ó sì ń gbé inú wọn.
Ọlọ́run wa nìkan, Jésù Kírístì pátápátá agbára ni a sì tí fí gbogbo agbára lọ́run àti ní ayé fún. Agbára rẹ̀ ju tí àdó olóró lọ, ìjọba rẹ̀ kò sì lópin.
4.02.5 - Ta ní Ọlọ́run Nínú Ẹ̀sìn Isíláàmù?
Ìfiraẹnijì fún Ọlọ́run alágbára ni ó ṣokùnfà ìpè “Allahu Akbar” tí àwọn Mùsùlùmí máa ń pè. Èyí tí ó túmọ́ sí pé, “Allah ni ó tóbi”, ìdí nìyí tí àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí fi gbà àwọn ìyókù lọ. Nítorí ìdí èyí, Àlláhù nínú ẹ̀sìn Islam fi di alágbára ńlá tí ó sì di ẹni àìrí tórí àwọn ẹrú rẹ̀. Èrò rẹ̀ kọjá ìmọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n, òun mọ̀ wà. Àlláhù nínú ẹ̀sìn Islam sàjèjì. Gbogbo èrò nípa rẹ̀ kò tọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni kò sì tó. Wọ́n gbàgbọ́ wí pé ènìyàn kò lè ní ìmọ̀ Olódùmarè. Àwọn Mùsùlùmí kàn lè bẹ̀rù kí wọn sì sín in ní ìdọ̀bálẹ̀ lásán.
Àwọn Sufi tí gbìyànjú láti sàfara àtọwọ́dá láti ṣe àgbéyèwò àwọn Àlláhù tí a kò lè rí ṣùgbọ́n, Kùránì kò fàyè gba ìyànjú tímọ́tímọ́ kankan nípasẹ̀ ọ̀gbọ́n ìrònú afòyemọ̀ tí Bedouin.
Nínú ẹ̀sìn Islam, ẹmí àìrí ni Àlláhù, kò sì tíì ṣe àgbékalẹ̀ májẹ̀mú kankan pẹ̀lú àwọn olùtẹ̀lé rẹ̀. Wọn kò rí Muhammadu gẹ́gẹ́ bí onílàrà láàárin Àlláhù àti àwọn Mùsùlùmí, ní àtàrí àti sọ wọ́n pọ̀ mọ́ Àlláhù nínú májẹ̀mú Isíláàmù. O pàse pé kí gbogbo wọ́n tẹ́ríba fún oluwa wọn láìsí ojúùsáájú.
Òye bí Ọlọ́run ṣe é ṣe pàtàkì tó kò yé àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. Nítorí ìdí èyí, wọn kò ní òye ẹ̀sẹ̀ wọn tòótọ́, bẹ́ẹ̀ni, wọn kò ní ìrírí ore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ní tòótọ́. Isìn nínú ẹ̀sìn Islam kìí ṣe fífí okàn ìmoore hàn sí Olùgbàlà fún gbígbà tí ó gbà wọ́n là kúrò nínú ẹ̀sẹ̀, tàbí iyìn fún ìdándè kúrò nínú ìdájọ́ dípò bẹ́ẹ̀, ìbọlá fún Àlláhù àlágbára tí ó jẹ́ àjẹ̀jí bí ẹrú tí ó wárírí lábé esẹ̀ Olúwa wa nítorí ẹ̀rù àti iyèméjì. Wọ́n gba ìhúrí láti tẹ̀lé Muhammadu nítorí pé ẹ̀sìn Islam gbóríyín fún Allah tí ó ń dérùbà wọ́n láìsọ wọ́n di mímọ́. Wọ́n kùnà láti mọ rírí Olùgbàlà fún gbígbà tí ó gbà wọn là láìgbowó, nítorí pé kò sí Olùgbàlà nínú ẹ̀sìn Islam. Abálájọ tí fi ń rà nínú ìdèẹ̀sìn ìbọ̀rìsà wọn.
Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run tòótọ́ tí ó fí ara rẹ̀ hàn nínú Bíbélì kò jìnà sí àwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀. Ó súnmọ́ wa, ó sì fí ìdí májẹ̀mú rẹ mulẹ̀ pẹ̀lú awa irú ọmọ Ádámù, bí ó tí sọ pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ”.
4.02.6 - Májẹ̀mú Pẹ̀lú Ọlọ́run
Ọ̀rọ̀-arópọ̀ orúkọ ‘rẹ’ nínú “Ọlọ́run rẹ” jẹ́ èyí tí ó ń fí ìní hàn. Èyí túmọ̀ sí pé, Ọlọ́run gbà wá láàyè láti ni”. A lè gbẹ́kẹ̀lé ẹ bí ọmọ ṣe gbẹ́kẹ̀lé baba rẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo ìsọ̀tẹ̀ wa, Ọlọ́run alágbára lósòó tì wa, bí ẹni pé, ó ń sọ pé, “Mo jẹ tirẹ̀”. Ẹ̀ésè tí ó kò ronúpìwàdà kí ó sì padà sí ọ̀dọ̀ mi, kí ó sì fí ara rẹ̀ jìn fún mi títí láí?
Ìròyìn tí ó dá ni lójú ni pé, òfin mẹ́wàá bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú májẹ̀mú tí a fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ láàárin Ọlọ́run àti ènìyàn. Ó jẹ́ májẹ̀mú tí Ọlọ́run nìkan bá àwọn àti ìfẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ fún wa. Ó sì ń retí kí a fèsì sí ìwàláàyè rẹ̀ ní onírúurú ipò pẹ̀lú igbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́.
Nínú májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú ẹlẹ́sẹ̀, Ọlọ́run fí ìdáríjì ìgbàlà, ààbò àti ìbùkún rẹ̀ dá wọ̀n lójú. “Tí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni ó lè kojú ìjà sí wá?” (Romu 8:31) ó gba wá níyànjú nípa fífi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, òun wà pẹ̀lú wa nígbàgbogbo, ó sì ń la àìsera wa kọjá. Ẹ̀sẹ̀ ènìyàn kò dá ìjólótítọ́ Ọlọ́run dúró. Abálájọ tí àwọn ènìyàn mímọ́ yóò fí dá ẹ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, bí ó tí wù kí ó kéré tó, ìdájọ́ pipe rẹ̀ pè fún ìdálébi ẹ̀sẹ̀ kọ̀ọkan síbẹ̀, ìfẹ́ ayérayé rẹ̀ nínú Kírístì wẹ̀ ẹ̀sẹ̀ gbogbo àwọn tí ó bá dá májẹ̀mú pẹ̀lú rẹ̀. Kírísítì pèsè ìdánilójú pé májẹ̀mú Ọlọ́run tí ní ipa nípa kíkú ni ipò wa. Láti ìgbà yìí ni agbélèbú tí di àmì ìtẹ̀síwájú oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.
4.02.7 - Ọlọ́run Baba Wa
Òpìn dé bá ìyapa tí ó yà wá kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nípasẹ̀ ìbí Kírísítì. Ọlọ́run farahàn nínú ara, kí àwọn ọmọ léyìn rẹ̀ má baà di ẹrú ẹ̀sẹ̀ mọ́, níwọ̀n ìgbà tí Jésù tí sọ wọn di òmìnira kúrọ̀ nínú ìdè ẹ̀sẹ̀, sẹ́kẹ́sẹkẹ̀ esu, nínú ikú àti ìdájọ́ Ọlọ́run. A ta èjè Jésù sílẹ̀ fún ètùtù fún ìtúsílẹ̀ wa. Nítorí náà a ó wẹ̀ ẹ̀sẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ nínú Kírísítì nu, a ó sì sọ wọn di ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run. Nípasẹ̀ Kírísítì, Ọlọ́run alágbára tí di baba nípà òfin àti nínú ẹ̀mí. Ó sì fún wa ní ìdánilójú pé, bí a tilẹ̀ dá ẹ̀sẹ̀ tí ó buru, “Emi ni Olúwa, baba rẹ̀”.
Ọlọ́run baba Olúwa wa Jésù Kírísítì, yònda agbára Ẹ̀mí mímọ́ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́, tí ó sì ń tẹ̀lé Jésù tí a kàn mọ́ àgbélèbú tí ó sì jí dìde. Àwọn onígbàgbọ́ tí ó tí di àtúnbí nínú Jésù ń gbé ìgbé ayé Jésù, wọ́n sì ní ìwà bíi baba wọn ọrun. Wọ́n tí dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìdè ìbẹ̀rù àti agbára ikú tí ẹ̀mí. Nínú Kírísítì, Ọlọ́run mímọ́ tí so wá mọ́ ara rẹ̀, ó sọ wá di tẹ́mípíìlì rẹ̀, ìbùgbé rẹ̀. Ó jẹ́ baba fún wa, àwa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀. A jẹ́ tirẹ̀ bí òun pẹ̀lú tíjẹ́ tiwa. A mú májẹ̀mú tuntun yìí sẹ nípasè ikú wa tí Kírísítì gbà kú. Láti ìgbà yìí lọ ni gbogbo onígbàgbọ́ nínú Kírísítì tí ń ní ìrírí ìfarakínra pẹ̀lú Ọlọ́run. Nígbà tí ó bá ń gbàdúrà, kìí ṣe sí ilẹ̀ òfìfò, dípò bẹ́ẹ̀, àdúrà dàbí ìtakùròsọ pẹ̀lú Ọlọ́run, tí ó kún fún ìdúpẹ́, ìjẹ́wọ́, ìbéèrè àti ẹ̀bẹ̀. Baba wa ọ̀run ń fi òtítọ́ gbọ́ tiwa. Nínú ìjọ́lọ́run rẹ̀ ni ààbò wá wà. Ó yí wa ká pẹ̀lú, ó sì dáàbò bò wá pẹ̀lú agbára òdodo rẹ̀. Àwọn onígbàgbó tòótọ́ kò jìnnà sí Ọlọ́run wọn bí i tí àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí. Wọn kò sìn àwọn òrìsà bíi tí àwọn ẹlẹ́sìn Hindus tàbí máa sàfẹ́ẹ̀rí ohun asán bí tí àwọn ẹlẹ́sìn Budli.
Ọlọ́run alágbára so ara rẹ̀ mó àwọn ọmọlẹ́yìn Kírísítì nípasè ìfẹ́ rẹ̀, kí wọn baà lè wà ní iwájú rẹ̀, kí wọn kí ó sì dàbí rẹ̀. Bàbá wa ọ̀run kò fẹ́ fi wá sí ipò àìnírètí, sùgbọ́n ó tí pinnu láti gbà wá là kí ó sì sọ wa di tuntun. Ó pè wá níjà, pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́ bí èmi tí jẹ́ mímọ́” (Lefitiku 11:45). Ìdàpò pẹ̀lú Ọlọ́run kìí ṣe ìgbàgbọ́ orí nìkani ṣùgbọ́n, ó tún yọrísí àyípadà ìwà ọmọlúàbí. Tí a bá ń gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ẹ̀dá wa yóò yípadà níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ayérayé ti pinnu láti mú àwọn ọmọ rẹ̀ kún ojú òsùwọ̀n rẹ̀. Bàbá wa fẹ́ kí á dàbí òun, bí Jésù ṣe sọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́ bí baba yín tí ń bẹ́ẹ̀ ní ọ̀un ṣe jẹ́ mímọ́”) (Matiu 5:48). Ìpele nínú ìgbésẹ̀ láti rà wá padà gẹ́gẹ́bí ẹni tí ó nù sí ọmọ Ọlọ́run ni òfin mẹ́wàá jẹ́. Kódà, òpó tí ó sọ wá ró kúrò nínú ìsubú nípasẹ̀ ore-ò́fẹ́ rẹ̀ ni wọ́n sì jẹ́.
Bóyá ó tilẹ̀ tí rò ó pé kò ṣe é ṣe láti mú òfin Kírísítì sẹ tàbí pé báwo ni á ṣe lè jẹ́ pipe bí Ọlọ́run tí jẹ́ pipe? Njẹ́ irú èyí kò dàbí àtúnwí tàbí atẹnumọ́ ìdanwò Éfà ní paradise nígbà tí ó gbọ́ tí èsù sọ pé, “Ẹ̀yìn yóò dàbí Ọlọ́run” Ènìyàn kò lè gbà ara rẹ̀ là tàbí kí ó di olódodo nípa ìyànjú rẹ̀.
Lórí ìpìlẹ̀ òfin tí ó lè sokùnfà ìsọ̀tẹ̀ tí yóò sì yọrísí ìdájó, ni a mọ òdodo ara ẹni lé ṣùgbọ́n ìwẹ̀numọ́ wa ni iṣẹ́ rere tí baba ọ̀run ṣé lórí wa. O mú wa rìn ní ọ̀na òdodo rẹ, ó pè wa lojojumo láti borí ibi tí ó wà ní inú wa. Ó ń mí si wa láti ka ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí á sì gbé ìgbésẹ̀ lórí rẹ̀. Ó fún wan í ìfẹ́ rẹ̀, èyí tí ó sọ onímọ́ tara ẹni di ìránsẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí ọlọ́run wa hàn gbangba débí pé, Muhammadu gan jéwọ́ wọn, ó sì sàpèjúwe àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn ọ̀títọ̀ tí kò ní ìgbéraga, àwọn tí ó gba ìfẹ́ àti àánú sínú ọkàn wọn. (Sur al-Maida 5:82 àti l-Hadid 57:22)
4.02.8 - Àṣeparí Ìgbàlà tí ó Pe
Ọlọ́run fẹ́ láti dá wa nídè kúró nínú ìdè ẹ̀sẹ̀. Nípasẹ̀ gbólóhùn kejì nínú òfin mẹ́wàá, ó sọ fún wa wí pé, a kò lè tú ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdè ẹ̀sẹ̀. Ọlọ́run ni yóò ṣe ẹlẹ́yìí nípasẹ̀ ìgbọràn wa nínú ìgbàgbọ́. Ọlọ́run gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúró lọ́wọ́ ìsìnrú tó gbópọn nípasẹ̀ Mose, ó sí fí ìdí májèmú òrun múlẹ̀ pẹ̀lú wọn. Ọlọ́run kò gbà wọ́n nítorí òdodo wọn, Ṣùgbọ́n ó fi oore-ofẹ fún wọ́n, ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé “Ẹ̀mi ni Olúwa Ọlọ́ruun rẹ̀ tí ó mú ọ jade láti ilẹ̀ Egypítì wa, láti ilẹ̀ ìgbèkùn”.
Àwọn ọmọ Jákọ́bù kúrò ní orí òkè asálẹ̀ olọ́kúta ní ìhà ìwò òòrùn afonífojì Jọ́dánì ní ìwọ̀n ọgọ́rùnun mẹta ó lé ní ọgọ́rùn-ún méfà ọdún sẹ́yìn nígbà tí òdá dá agbegbè wọn. Ebi lé wọn jáde ní àfonífojì ọlọ́ràá. Nílẹ̀ ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ibùsọ̀ sí ilẹ̀ abínibí wọn, wn ń gbé ìgbéayé ìrọ̀rùn níbẹ̀. Ọdọ̀ọ̀dún ní odò nile sì ń kún kúnya tí ó sì ń bomirin ilẹ̀ wọn. Àwọn ọmọ Jákọ́bù ń pọ̀ si kíákíá, wọn sì ń di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ fún àwọn ará Egypitì. Farao fí àwọn ọmọ Hébérù sínú ìgbèkùn, ó sì ń ni wọ́n lára gidigidi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ́n rántí Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn ní ilẹ̀ ìgbèkùn, wọ́n sì ké pè é fún ìrànlọ́wọ́. Wọn tí gbàgbé Ọlọ́run wọ́n ní àkókò ìgbáadún, ṣùgbọ́n ìpónnjú àti òsí lé wọn padà sí ọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá àti Olùgbalà wọn.
Ọlọ́run gbọ́ igbe wọn, ó sì ran Mósè, ìránsẹ rẹ̀, ẹni tí ó tí yan láti àáfin Fáráò w àti nínú aginjù láti mú ìpè rẹ̀ ṣẹ̀. Olúwa farahàn Mose nínú papa tí ó ń jó tí ìgbé ò sì run. Ọlọ́run fí ara rẹ̀ hàn fún Mósè gẹ́gẹ́ bí “Ẹmi ni” èyí tí ó túmọ̀ sí pé “Ẹ̀mi ni ẹni tí ń jẹ́ Èmi ni”, N kò yí padà ṣùgbọ́n, mo jẹ́ Ọlóòtọ́ sí ó síbẹ̀” Nítorí náà, “Èyìn ó wá Mi, ẹ ó sì rí Mi, nígbá tí ẹ bá fí gbogbo ọkàn yín wá Mi” (Jeremiah 29: 3).
Ọlọ́run rán Mósè sí Fáráò, òorìsa àwọn ará Egypitì láti jọ̀wọ́ àwọn ọmọ ìgbèkùn Hébérù lọ́wọ́ ṣùgbọ́n, olórí àfonífojì nílẹ̀ ko fẹ́ láti tú àwọn alágbàse olówo póọkú rẹ̀ sílẹ̀. Ó sé ọkàn rẹ̀ le si kò si setán láti dá àwọn ọmọ Ábúráhámù sílè títí ọlọ́run fi kàn-án nípa fún ún nípasẹ̀ àfikún àjálù ati ìpóńjú. A dá wọn sílẹ̀ ni oko ẹ́rú, kìí ṣe nípa òdodo wọn ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìgbọran tí ìgbàgbọ́. Wọn saláìní àwọn ohun ẹ̀lọ̀ ìjà, wọn sá àsálà lọ sínú aginjù ní òru ní abé apá ẹ̀jẹ tó ń daábòbò tí ìrékọjá òdò àgùntan tí a pa fún wọ́n, ọ̀dọ́ àgùntàn kan ni wọn fí ń rúbọ̀ fún ìdílé kan. Wọn jẹ ouńjẹ ọ̀dọ́ agùntàn, wọn sì ń fò nínú agbára Ọlọ́run. Líla ọkun pupa kọjá ati ìṣẹ́gun lórí àwọn òtá tí ó ń lé wọn ni ẹ̀rí ìkẹ̀yìn ìdáǹdè náa. Lónìí, lè rí òkú Farao tí ó rì sínú òkùn pẹ̀lú ìpẹ̀ǹpẹ́ láti inú òkùn pupa nínú oọkàn re nínú ilé ìsọnnkan lọ́jò fún ìrántí tí àwọn ara Egypitì ni Cairo.
Àwọn ẹlésìn ìmọ̀lẹ ká ìsẹ́gun wọn lórí àwọn ọ̀tá wọn sí pé Ọlórun gbe ìja wọ́n jà ni ojú ogún. Ìsẹ́gun Muhmmadu lórí awọn onísòwò tí ìlú Mecca nínú ogún Badiri kìí ṣe nípa oọwọ́ ìyanu Ọlọ́run bí kò ṣe nípa ipá àti agbára ohun ìjà. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sa gbogbo agbár wọn, ábálájọ tí wọ́n fí fi ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá lélẹ̀. Ohun tí Mósè pè ní iṣẹ́ ìyanu, ìdáǹdè láti òkè láìsí ìtàjẹsílẹ̀ bí ó ti wù kí ó kere tó ní àwọn ẹlẹ́sìn Islam ní pè ní ogún mímọ́ (Jihad) èyí tí ó pọn dandan fún gbogbo ènìyàn láti darapọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n, Allah ni ó pa wọn. ‘Ìwọ́ kọ́ ni ó ta ọfà, ṣùgbọ́n Allah ni ó ta á” (Sura al-Anfal 8:17)
Lẹ́yìn tí Ọlọ́run gbà àwọn ọmọ Isírẹ́lì là pẹ̀lú ọwọ́ ìyanu kúrò ní ilẹ Egypitì, ó darí wọn lọ sínú oorun aginju gbígbẹ, ó sì ṣe àsè fún ọn. Ó fẹ́ ṣe àṣeprí Májẹ̀mú ọ̀run pẹ̀lú wọn, kí á baà lè jẹ́ mímọ́ nínú ìfarakínra wọn pẹ̀lú rẹ̀. Ó pè wọ́n láti sìn ín gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè Olúàlùfáà. Àwọn ni ó yẹ kí wọ́n jẹ́ agbátẹrù iṣẹ́ ìránsẹ́ìlàjà níwájú itẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ènìyàn. Òfin méwàá ni ó sì jẹ́ ààrin gbuǹgbùn ìwé májèmú àti òfin iyebíyè fún ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run wọn. A gbé Ọlọ́run ga ju wàálà òfin rẹ̀ méjéèjì tí ó wà nínú àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run.
4.02.9 - Ìgbàlà Nínú Májẹ̀mú Tuntun àti Èròńgbà Òfin Mẹ́wàá
Tí a bá ṣe àsàrò lórí ìsẹ́gun ńlá tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Jákóbù níwọ̀n bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọ̀gọ́rùn mẹ́ta ọdún sẹ́yìn tí a sì wá ṣe àfiwé rẹ̀ pẹ̀lú àṣeparí iṣẹ́ ìgbàlà tí Jésù nínú májẹ̀mú titun, a lè ṣe ìsọnísókí ìbẹ̀rẹ̀ òfin mẹ́wàá báyìí pé, “Èmi ni OLUWA, Ọlọ́run àti Baba rẹ̀, mọ tí rà ọ́ padà títí ayé”.
Láti 1gbà tí Jésù ti wá sínú ayé tí ó sì ru erù ẹ̀sẹ̀ wa ní orí àgbélèbú, tí ó sì tún kú bí ọ̀dọ́ àgùntàn Ọlọ́run fún wa á kédè àánú Ọlọ́run fún gbogbo orílẹ̀-èdè, a sì wàásù Jésù gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà fún gbogbo ènìyan. Jésù já gbogbo sẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ẹ̀sẹ̀, ó sì sẹ́gun agbára sátáni nípasẹ̀ ìjìya àti ikú lórí àgbélèbú. Ó paná ìbínú Ọlọ́run, ó sì gbà ìdájọ́ wa. Nípasẹ̀ Kírísítì nìkan ni a gbà àṣeparí ìgbàlà wa. Ìdí nìyí tí á fí nílò láti dúpé lọ́wọ́ rè kí á sì gbà ìràpadà rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.Ìgbàlà Ọlọ́run dájú ó sì wà fún gbogbo ènìyàn. A ti gbàwálà lọ́na tóyàtọ̀ tó sì lágbára láìlo ohun ìjà. Lóòtọ́ ní a ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n, kìí ṣe ẹ̀jẹ̀ ọ̀tà tí á sẹ́gun bíkòse ẹ̀jẹ̀ ọmọ bíbí kan soso, ẹni tí ó fí ara rẹ̀ rúbo fún wa.
Èrèdi pípa òfin mẹ́wàá mọ́ kìí ṣe láti fí gbà ara wa yálà bẹ́ẹ̀ wọ́n ń kọ́ awa àyànfẹ́ tí a ti gbàlà bí a tí lè mọ rírì igbàlà tí a tí gbà lọ́fẹ̀ẹ́. Ẹníkẹ́ni tí ó bá lérò é òun lè gbà ara òun là lọ́wọ́ ẹ̀sẹ̀, èsù, ikú ààti ìbínú Ọlọ́run nípa agbára ènìyàn tí ṣe asìsẹ ńlá. Dájúdájú irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fí ara rẹ̀ sínú ìdè ẹ̀sẹ̀ sí òfin mẹ́waá kò lè sọ wá di mímọ́ pátápátá, yálà bẹ́ẹ̀ wọ́n kàn ń darí wa sí ìrònúpìwadà àti ìgbọ́ran ìgbàgbọ́ kí á sì máa yọ lórí ìgbàlà tí a ti rí gbà. A lè kògo èrèdí òfin Mọse já nígbà tí a bá fi yín fún bàbá wa ọ̀run pẹ̀lú Jésù nínú aagbára Ẹ̀mí Mímọ́.Ọlọ́run kò fẹ́ fí wá gún tàbí dá lẹ́bii tàbí sọ òfin mẹ́wàá di àjàgà wúwo èyí tí ó mú wa rẹ̀wẹ̀sì.Dajúdájú kò rí bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run tí sẹ̀tò ìgbàlà sáájú ìfihàn òfin. Ó gé òfin kalẹ̀ láti darí àwọn tí a ti gbàlà sí ìrònúpìwàdà kí ó sì sọ ìsọ̀lẹ̀ dí ìwà pẹ̀lẹ́ tí Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà ète òfin ní ìdàpọ̀wa pẹ̀lú Ọlọ́run bàbá a, kìí ṣe ìparun ní ìgbà ìdájọ́ ìkẹyìn.
Òfin mẹ́wàá yóò túbọ̀ yé wa tí a bá tí jẹ́ ẹrú rí. Gẹ́gẹ́ bí ẹrú, a ò bá ti dààmú kódà nínú ìmọ̀lára tí a bá ní nínú ìlera tàbí àìlera, ní kékeré tàbí àgbà. A ò bá tí pọn ón ní dandan fún wa láti ṣíṣẹ́ kódà nígbà tí ara wa kò fẹ́ bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹrú, a ò bá ní amì ìdánímọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò sì ní bìkítà nípa wa.
Ọlọ́run tú àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ̀ òsì fún ìdí èyí, a ka òfin mẹ́wàá sí ìwé ìléwó tí ó ń tọ́ àwọn onígbàgbọ́ tí a tí dá nídè sọ́nà kí wọ́n bà lé mọ̀ bí a ṣe ń gbé ìgbé yé ìrẹ̀lẹ̀ àti ogbọ́n nínú òmìnira wọn. Oríṣiirísìí ìdánwò ni ó wà nínú òmìnira. Tí a bá ń gbé ìgbé ayé tí kò fògo fún Ọlọ́run, a ò ní pẹ́ di ẹrú ẹ̀sẹ̀ àti ìfẹ́ inú wa. Síbẹ̀, Ọlọ́run dá ènìyàn ní awọ̀rán ara rẹ̀. Láìsì Ọlọ́run, ènìyàn kò lè gbé bí olódodo kò sí òmìnira tí ó pé láìsì Ọlọ́run.
Ẹnìkẹ́ni tí ó bá ń gbé nínú ẹ̀sẹ̀ di ẹrú ẹ̀sẹ̀. Oríṣìírísìí ẹ̀sẹ̀ bí mímú ògùn ọlóró, àgbèrè, olè jíjáá, ọ̀lẹ, ìfipá-bánilòpọ̀ àti odì yóò wá dí ẹ̀wọn fún un. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà nínú ìrọra àrékérekè, ìdè àìrí bí ọ̀tí, sìga mímú, òògun oloro àti irọ́ tí ó tí dí bárákú, kí á má sọ áfòse àti ẹ̀mí èsù, àwọn tí ẹ̀sù ń fí ọkàn wọn ṣeré, ṣùgbọ́n Jésù tú gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú rẹ̀ sílẹ̀, ó sí fí wọ́n sínú òmìnira mímó tí àwọn ọmọ Ọlọ́run. Kírísitì ní asẹ́gun gidi, Olùgbàlà, onísẹgun tí ó gbọ́n, olùsọ́ Àgùntàn rere àti ọ̀rẹ́ òtító, kò sí ẹni tí ó lè tọ̀ ọ́ wá láìrí ìrànlọ́wọ́ àti ìyanjú gbà.
Òfin mẹ́wàá jẹ́ ògirí ààbò fún àwọn tí a tí tú sílẹ̀ nípa oorè-ọ̀fẹ́.Àwọn tí Ọlọ́run tí di baba fún, Kírísitì Olùgbàlá wọ̀n, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ Olùtùnú wọn. Wọ́n tí ní òye Ọ́lọ́run baba, Ọmọ Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́rún kan. Wọ́n tí ní ìrírí ìtúsílè gidi nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti àlàáfíà.Abájọ tí òfin mẹ́wàá tí fi di àmì àtọ́ni Ọlọ́ruun fún wọn, tí ó sì fún wọn ní orin ìyìn la asálẹ̀ ayé wọn já.