Previous Chapter -- Next Chapter
43. Báwo ni Olúwa yóò ṣe dá yín lẹ́jọ́?
“17 Gbogbo igi rere a máa so èso rere; ṣugbọn igi buburu nso eso buburu. 18 Igi rere kò lè so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé lulẹ̀, a óo sì sọ ọ́ sínú iná. 20 Nítorí náà, ẹ óo mọ̀ wọ́n nípa èso wọn. 21 Kì í ṣe gbogbo ẹni tí ó wí fún mi pé, ‘Oluwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run; bikoṣe ẹniti o nṣe ifẹ Baba mi ti mbẹ li ọrun. 22 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò sọ fún mi ní ọjọ́ náà pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, ní orúkọ rẹ ni a fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ?’ 23 Nígbà náà ni èmi yóò sì sọ fún wọn pé, ‘Emi ko mọ ọ; ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin tí ń hùwà àìlófin.” (Mátíù 7:17-23)