Grace and Truth

This website is under construction !

Search in "Yoruba":
Home -- Yoruba -- 09. Comparisons -- 4.04 Second Commandment: Do Not Make Idols
This page in: -- Afrikaans -- Arabic? -- Armenian? -- Azeri? -- Bulgarian? -- Cebuano? -- Chinese -- English -- Farsi? -- French -- German -- Gujarati? -- Hebrew -- Indonesian -- Norwegian? -- Polish? -- Russian -- Serbian? -- Spanish? -- Tamil -- Turkish? -- Uzbek -- Yiddish? -- YORUBA

Previous part -- Next part

09. Ìyatọ̀ tó wà láàárín Ẹsìn Músúlúùmì àti tí Kírísítẹ́nì
Comparisosns 4 - The Ten Commandments

4.04 - ÒFIN KEJÌ: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya èèreEKÍSÓDÙ 20:4-6

Òfin kejì jẹ́ àmúpé àti àfikun fún òfin kínní. Fún ìdí èyí, àwọn ìlànà èkọ́ kan sì gbà wí pé ara òfin àkókó ni. Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan sì rí òfin ìkejì yìí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó le ju nítorí pé ó tí máa ń dá àdèàìyede ńlá sílẹ̀.


4.04.1 - Lòdì sí àwòrán Kírísítẹ́nì

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí àti àwọn Júù máa ń fí ẹ̀sùn títápá sí òfin ọ̀gá ògo kan àwọn Kìrìsìtẹ́nì. Wón máa ń sọ pé, “Ẹ̀yin ni ẹ ń rú èyí tí ó ṣe kókó nínú òfin Ọlọ́run” Ẹ̀ ń fí Ọlọ́run wé oríṣìíríṣìí nnkan, ẹ sì ń sọ fún àwọn ènìyàn ohun tí èrò yin tí ó tò tí bi. Àgbékalẹ̀ ofin yìí tí fa oríṣìíríṣìí àríyànjiyàn ńlá kódà láàárín àwọn ìjọ Kírísítẹ́nì. Àwọn ọmọ ìjọ kan tí fi ìbínú wọ àwọn ìjọ mìíràn, tí wọ́n sì tí jọ́ ibi pẹpẹ wọn. A gbọ́dọ̀ gbà pé àwòrán Ọlọ́run nínú ògo rẹ̀ kò ṣe é yà. Àwọ̀ránkáwòrán Ọlọ́run ń tàbùkù rẹ̀ ó sì ń gan Ọláńlá agbára rẹ̀. Asán ni àwòrán àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn áńgẹ́lì sì máa ń jásí. Ọlọ́run ní ó lágbára jù, òun ni ó mọ́ jù, tí agbára rẹ̀ kò sì lópin jù ohun tí a lè rò lọ. Ó yàtọ̀ gédégédé sí ohun tí ènìyàn lè rò lọ. Lará àwọn ẹlẹ́yìí ni àwòrán dárádárá tí àwọn ayawòrán bí Michelangelo!

Ọ̀nà méjì ní Ọlọ́run gbà láti fí ara rẹ̀ hàn àwọn ènìyàn nínú Bíbélì. Ó fí ara rẹ̀ hàn lọ́nà àkọ́kọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó sọ sí àwọn olùgbọ́, lọ́nà kejì nípasẹ̀ ìran tí ó fí hàn àwọn wòólì tàbí aríran. ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní Ọlọ́run fí ara rẹ̀ hàn nínú Májẹ̀mú láíláí láti inú ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ní ìdákọ̀ọ̀kan nínú ìran. Ṣùgbọ́n, nígba tí a ra ọmọ Ọlọ́run padà sínú ògo rẹ̀ níwájú àwọn àpọ́sítélì, wọ́n subú lulẹ̀ bí ẹni pé wọ́n tí kú níorí ìwà mímọ́ Ọlọ́run farahàn, ó sì bá àìmọ́ wọn wí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá rí ìran kò lè sọ ní pàtó ohun tí wọ́n rí, wọ́n kàn lè ṣàpèjúwe rẹ̀ lásán ni.


4.04.2 - Kíkojú Ìjà sí Ìbọ̀rìsà

Tí a bá wo òfin kejì fínnífínní, a ó ríi pé kò tàko yíyàwòrán Ọlọ́run. Dípọ̀ bẹ́ẹ̀, ó kilo fún wa nípa oríṣìíríṣìí ìbọ̀rìsà. Gbogbo àwọn tí ó ń sìn òrìsà, èère tàbí àwọn ohun àfọwọ́gbẹ́ jẹ́ àpẹẹrẹ ìbínú rẹ̀.

Èère gbígbẹ́ ńlá kan wà ní orí òkè ní ẹ̀bá ìlá-oòrùn ní àkókó májẹ̀mú láíláí. Òkuta ni wọ́n fí gbẹ́ wọn, wọ́n a sì máa lò wọn ní ibi ìsìn ní gbangba. Àwọn èère onígi, olókúta, oníwúrà tàbí onígóòlù wà nínú ilé tí àwọn ènìyàn ń sìn. Ṣùgbọ́n, ẹniẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo fí àyè sílẹ̀ fún Ọlọ́run láti jade, kí ẹ̀mí àìmọ́ sì dípò ẹ̀mí Ọlọ́run. Àwọn Gíríkì ní àkókò Jésù a máa wọ́ tẹ̀lé àwọn òrìsà wọn láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.

Àwọn ara Egypti, àwọn ara Syria àti Bábílónì sì ṣe bẹ́ẹ̀ sáájú. Idi nìyí tí Mósè àti àwọn wòólì fí gbé ogun ńlá dìde sí ìbọ̀rìsà. Loni, a lè rí àwọn òrìsà tí àwọn wòólì tí fi gún ní àtijó tí a ṣe àfihàn wọn nínú àwọn ilé ipankànatíjọ́mọ́ ní Cairo, Baghdad àti Beirut. Gbogbo àwọn gbọ̀ngàn yìí ni ó sì tí di ibi ìsojúlóore fún àwọn arìnrìnajò afẹ́. Tí wọn ń lọ sókè sódò gún àtẹ̀gùn Ákírópólíìsì àti ibojì Ọba Júù àwọn Greek àti Egyptì lọ. Àwọn ènìyàn ń gbìyànjú mú rírí jade nínú àìrí síbẹ̀ ìwàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò tẹ́ wọ́n lọ́rùn. Ènìyàn fẹ́ láti rí ju gbigbọ́ lọ. Àwọn nnkan àìrí àti àìlèfọwọ́kàn wá di àjèjì fún un. Ìdí nìyí tí tẹlifísàn wíwò fí jẹ́ ẹ̀sẹ̀ fún àwọn ènìyàn tí ó fẹ́ láti gbọ́ràn sì òfin kejì.


4.04.3 - Àwọn àwòrán tí àwọn Júù àti Mùsùlùmí kọ̀ sílẹ̀

Pẹ̀lú gbogbo ìfòfindè àwòrán tàbí ère ní nnkan bí 1,350 ọdún sẹ̀yìn, síbẹ̀, àwọn Mùsùlùmí fí àyè gbà tẹlífísàn, fídio, magasíìnì kíákíá pẹ̀lú ìrọ̀hìn ìfòfindè àwọn àwòrán yìí tí yọrísì ọ̀sọ̀ tí àwọn Áráàbù, tí a lè rí ní ibi gbogbo nínú àsà Islam ní Saudi, Áráàbù, ní Mọ́sálásí ilẹ̀ China, ní ilé ìsọ́ tí Morocco àti ní apá Gúsù Áfírííkà.

Ipá òfin kejì hàn ní ara àwọn Mùsùlùmí nípa àwòrán òdòdó àti tí ọgba onígun ìsirò wọn lára bébà, igi, irin àti òkúta. Pàápàá jùlọ lára àwọn ẹni ni àwọn orílẹ̀-èdè apá ìla oòrùn pẹ̀lú àwọn ọ̀sọ́ ńláńlá tí ọgbà tàbí tí paradise, gbogbo agbáyé ni ó sì sagbátẹrù wọn.

Àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ní orílẹ̀-èdè Saudi Árabia gbọ́dọ̀ lọ àwòrán ènìyàn tí kò ní orí fún àmì láti fí hàn ní òpópónà pé àwọn tí ó ń fí ẹ̀sẹ̀ rìn ń kojà ní àwọn oríta wọn kò bá òfin mú láti ya àwòrán orí di òní olónìí. Ṣùgbọ́n, ní àwọn orílẹ̀-èdè bí Iran, Turkey àti India àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ibẹ̀ kìí ṣe bẹ́ẹ̀ kọbiara sí irú ìfòfindè Àlìkùránì yìí. Wọ́n tílẹ̀ máa ń ya àwòrán Mùhámmádù àti Gábúrẹ́lì èyí tí kò bófinmú fún àwọn Mùsùlùmí ní ilé Áràbù di òmí olónìí. Láìpẹ́ yìí tí àwọn orílẹ̀-èdè Áràbù gbé fíìmù kan jade nípa Mùhámmádù, wọn kò jẹ́ kí ojú rẹ̀ hàn. Gbogbo iṣe inú fíìmù náà dàbí ìgbà tí Mùhámmádù fí ojú ara rẹ̀ ríi tí ó sì ń sọ ọ́ pẹ̀lú ohùn rẹ̀. Kò farahàn bí ènìyàn. Fún ìdí elẹ́yìí, àwọn tí ó ń gbé fíìmù Kìrìsítẹni jade máa ń kíyèsára nígbà tí wọn bá ń ṣe àfihàn àwòrán àwọn wòlíì Ọlọ́run, áńgẹ́lì tàbí Kírísítì nínú fíìmù fún àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí.

Àwọn Júù pẹ̀lú Súnrakì nípa yíya àwòrán Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú kejì. Nígbà tí Titu olórí Róòmù gbà ìjọba Jèrúsalẹ́ẹ̀mù ní AD 70, tí ó sì wọ inú tẹ́mpìlì, ó wọ inú ibi mímọ́ jùlọ, ó ń retí láti rí àwòrán góòlù tàbí àwọn ohun èlò iyebíye, ṣùgbọ́n, ó bá ìjákulẹ̀ pàdé. Ibi mímọ́ jùlọ sófo nítorí pé ẹ̀mí ni Ọlọ́run kìí ṣe ohun èlò. A kò leè dín in kù sí ère tàbí àwòrán.


4.04.4 - Njẹ́ àwọn àwòrán Jésù lòdì sí Ìwé Mímọ́?

Àwọn onígbàgbọ́ kò túmọ̀ òfin kejì bí àwọn Júù àti àwọn Mùsùlùmí ṣe túmọ̀ rẹ̀. Kírísítì di ènìyàn ní àkókò ìbí rẹ̀. Gbogbo ojú ni ó sì lè ríi. Ó sọ pé, “Ẹni tí ó bá rí mi tí rí bàbá” (Jòhánù 14:9). A mú èrèdí ìsẹ̀dá sẹ nínú Kírístì. Bíbélì sọ pé, “Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ní ó dá a; akọ àti abo ní ó sì dá wọ́n”. (Jẹ́nẹ́síìsì 1:27). A yan Ádámù àti Éfà láti sojú Ọlọ́run. Àwòrán ènìyàn wà láti fí ògo Ọlọ́run hàn kódà títí dí òní olónìí.

A ní ànfààní láti jẹ̀gbádùn ìsẹ̀dá Ọlọ́run kí a sì ya àwòrán òdòdó, eranko àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ bá wọ́n jẹ́ tàbí kí a máa sìn wọ́n. Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run sì ni wọ́n. Kò lè dé òdiwọ̀n asẹ̀dá fúnrarẹ̀, a kò sì gbọ́dọ̀ sìn wọ́n. Àwòrán Ọlọ́run nínú ènìyan sákìí lẹ́yìn tí ènìyàn subú sínú ẹ̀sẹ̀, tí ibis ì gbà gbogbo ayé. Ṣùgbọ́n, Jésù, Ádámù kejì dá àwòrán Ọlọ́run padà nínú ènìyàn. Abálájọ tí Pọ́ọ̀lù fí pé Jésù ní “Àwòrán Ọlọ́run àìrí” (Kòlósè 1:15).

A bí Jésù, ó kú, ó sì jínde fún gbogbo ènìyàn. Nítorí náa gogbo ènìyàn ní ó ní ànfààní láti yà á bí ó bá ṣe rí sí wa, pẹ̀lú àwọn àbùdá lóríṣìíríṣìí bíi tí Áfííkà, orílẹ̀-èdè ìlà oòrùn, Íeóòpù tàbí àwọn tí ó súnmọ́ tí apá ìlà-oòrùn. Àwòrán Ọlọ́run ní àwọ̀ ènìyàn ní gbogbo ẹ̀yà àti àṣà ni. Ayọ̀, àlàáfíà àti sùúrù rẹ̀ hàn gbangba kìí ṣe ẹ̀kọ́ lásán. Nínú Kírísítì ni Ọlọ́run ti súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí. Ọlọ́run kò farahàn wá ní àwòrán olórí ogun gbígbóná tàbí pẹ̀lú ojú búburú ṣùgbọ́n, ní àwòrán ọ̀dọ́ àgùntàn tí ó kún fún ìrẹ̀lẹ̀ tí ó ṣetán láti farada ìbínú Ọlọ́run fún wa, tí ó sì kú fún ẹ̀sẹ̀ wa, kí a bá lè wà pẹ̀lú rẹ̀ títí, ó tí kọ́ wan í ìtúmọ̀ ètùtù. Àgbélèbú rẹ̀ sì di àmì ìfẹ́ Ọlọ́run ńlá. A ṣe àṣepé àjínde Kírísítì kúrò nínú òkú nínú ìfarahàn rẹ̀, èyí tí ó fí ara ẹ̀mí tí ó ṣe yebíye rẹ̀ hàn (Lúùkù 24:39).


4.04.5 - Àwòrán Kírísítì nínú àwọn Àtẹ̀lé Rẹ

Jésù fí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kún ọkàn àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí ìfẹ́ ìwàmímọ́ ati ayọ̀ lọ́run bà lè farahàn nínú wọn. Ó tí yàn wá láti jẹ́ àwòrán Ọlọ́run ní àárín ayé tí ó kún fún ìkórira àti ikú. Ó sì fún wan í oore-ọ̀fẹ́ láti jẹ́ “lẹ́tà ààyè Kírísítì” tí ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìsesí wa fún ẹbí, alábágbé àti òré wa. Jésù tí fi àwòrán rẹ̀ sínú wa kí á bá lè fí àbùdá rẹ̀ hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe alábápàdé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní Áfíríkà, Asia, Íróòpù tàbí Amẹ́ríkà tàbí níbikíbi yóò rí tàbí kíyèsí ìmọ́lẹ̀ àlàáfíà Kírísítì tí ó ń tàn lójú wọn. Nígbà tí ẹ̀mí ìkànmọ́gi àti tí àjínde Jésù Olúwa wa bá ń gbé inú ọkàn ènìyàn, olówó tàbí tálákà, òmòwé tàbí púrúùtù, àgbàlagbà tàbí ọmọdé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò fí ìjáfáfá ìlú ọ̀run hàn. Kò tó láti pín ayé sí ìpín tálákà tàbí olówó, orílẹ̀-èdè tí àwọn ènìyàn ń darí ọrọ̀ ayé tàbí èyí tí ìjọba ń darí ọrọ̀ ayé nìkan, ṣùgbọ́n ó yẹ kí á pín ayé sí àwọn tó tí I àtúnbí àti àwọn tó ń móòkùn tí wọn sì ń sègbé nínú ẹ̀sẹ̀. Nígbàkúgbà tí Kírísítì bá ráyè fún ara rẹ̀ nínú ọkàn ènìyàn, iyè Ọlọ́run yóò farahàn gbogbo ènìyàn yóò sì ríi.

Ẹ̀mí mímọ́ kìí rànwálọ́wọ́ láti gbéraga dípò bẹ́ẹ̀ ó rànwálọ́wọ́ láti fí ògo fún ọmọ Ọlọ́run. A kò gbọ́dọ̀ rí ara wa bíi ààrín gbọ̀ngbọ̀n ayé. Òdọ́ àgùntà tí a pa fún wa nìkan ni ó yẹ kí á fí gbogbo ògo fún. Maria, ìyà Jésù àti àwọn ẹni mímọ́ yóò gbójú agan sí àwọn tó gbósùbà fún èère àti àwòrán wọ́n. Wọ́n á sì pa wọ́n run níbikíbi tí wọ́n bá tí rí wọn, ní orí pẹpẹ nínú ilé tàbí ní àwùjo. Kò sí ẹni tí ó tíi fí ògo Ọlọ́run hàn àfi Jésù. Kò sí ẹni rere kan àyàfi Ọlọ́run. Oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ nìkan ní a fí wẹ̀ wá mọ́ tí a sì fí dá wa láre. Gbígbàdúrà sí Màríà àti àwọn àyànfédfún ìrànlọ́wọ́ lòdì sí Bíbélì. Ìtasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀ ní ẹlẹ́yìí jẹ́ fún òfin kejì bí ẹni pé a kò gbẹ́kẹ̀lé bàbá wa òrun ṣùgbọ́n, tí a wá ń gbẹ́kẹ̀lé wa láàáín rẹ̀ àti àwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀. Kò sí èère, àwòrán tàbí ìrántí kankan tí ó lè ṣe iṣẹ́ ìyanu tàbí kí o fún ni ní agbára ìwòsàn. Nípasẹ̀ Jésù Kírísítì ọmọ Ọlọ́run nìkan ní Ọlọ́run fí gbà wá là. Ohun ìríra ni gbogbo èère kódà ní ilé Ọlọ́run jẹ́ níwájú Olúwa.

Nínú májẹ̀mú tuntun, a ní ìrírí ìfarakínra pẹ̀lú Ọlọ́run bàbá wa gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ ọmọ rẹ̀. Ikú ètùtù Jésù àtin ìsìpẹ̀ olórí àlùfà rẹ̀ láídákẹ́ ní apá òtun bàbá rẹ̀ ní ó sì fún wan í ìdánilójú ànfààní yìí. Ọmọ sì tí mú kí ìfarakínra tààrà láàrín àwa àti bàbá ṣe é ṣe. Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì lo ànfààní yìí kò gbàgbọ́ nínú ìjẹ́ bàbá Ọlọ́run. A tí rí oore-ọ̀fẹ́, òdodo, ìdáríjì àti iyè láti ọwọ́ bàbá àti ọmọ rẹ̀ gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀. Fún ìdí èyí, ó yẹ́ kí á dupe lọ́wọ́ Ọlọ́run òtítọ́ nìkan pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa.


4.04.6 - Èdìdí Ọlọ́run

Ààlà tó wá láàárín àwọn ènìyàn tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn tí ó kẹ̀yìn síi ni a lè rí láàárín ìyàlẹ̀ fún ìjẹníya àti ìlérí ìbùkún nínú òfin kejì. Níbí yìí, léèkansi, Ọlọ́run pé ara rẹ̀ ní “Ẹmi” èyí tí ó túmọ̀ sí pé Ó jẹ́ alààyè pẹ̀lú ewù àti oore-ọ̀fẹ́ láti sọ̀rọ̀. Ó tẹnumọ́ ọ pé òun ni Ọlọ́run olótítọ́, tí kò yípadà, tí ó sì wà ní ìkáwọ́ ohun gbogbo. Ó fí májẹ̀mú ayérayé sọ wá pọ̀ mọ́ ara rẹ̀, Ó sì ń réti pé kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìtẹríbá pipe àti òtítọ́.

Ọlọ́run fẹ́ kí a ni ìfẹ́, ó kò fún wa lái pín ìtẹríba wa fún òun pẹ̀lú òrìsà, olùdásílẹ̀ ẹ̀sìn kan, ọba kan tàbí wúrà òun fàdákà. Òun nìkan ní Ọlọ́run, kò sì sí Olùgbàlà mìíràn.


4.04.7 - Àwọn tí ó Kórira Ọlọ́run yóò Subú

Ègbé ní fún àwọn tí ó dégàn ìfẹ́ Ọlọ́run tàbí tí ó fí ọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. Wọ́n dàbí ẹka tí a ké kúrò lára àjàgà. Wọ́n a rẹ̀, wọn á sì gbẹ, ìgbẹ̀yìn wọn à sì jẹ́ iná ayérayé. Tí á bá kọ̀ láti dúró nínú Ọlọ́run, ẹni tíi ṣe orísun wa, a dá ẹ̀sẹ̀ ńlá tí ẹ̀mí nítorí pé a fí àyè gbà ẹ̀mí àjèjì, òrìsà tàbí agbára àìmó laaye nínú ayé wa tàbí kí á sọ arar wa di ọlọ́run kéékéékéé (demigodis).

Ọlọ́run kò pín ògo rẹ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni àyàfi ọmọ rẹ̀ àti ẹ̀mí rẹ̀. Kò sí asẹ̀dá mìíràn, òun nìkan ní adájọ láti atètèkósẹ àti títí ayé.Tí ènnìyàn bá kọ̀ láti yípadà sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí ó ń wo Ọlọ́run mìíràn tàbí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo, ìgbéraga á gbé irú ẹni báyìí, irú ẹni bẹ́ẹ̀ á wá di ènìyàn búburú. A sì máa wá ọ̀nà láti ji àwọn ènìyàn lẹ́sẹ̀ dípò kí ó sìn wọ́n. Ẹni tí kò bá fẹ́ràn Ọlọ́run, kò lè fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ̀. Irú wọn kò sì ní ní òye tó kún nípa ayé àti àwọn ìsòro ẹ̀mí nítorí pé, wọ́n kò ní ìpìlẹ̀ tó ye kooro. Àsẹ̀yìnwá, àsẹ̀yìnbọ̀, ẹ̀rí ọkàn wọn kò ní siṣẹ́ bí ó tí yẹ, ẹ̀kọ́ wọn à sì bàjẹ́. Wọn á wá di asòdì, irú wọn á sì wá buu ju ẹranko lọ nínú ìlàkàkà wọn lòòrèkóòrè láti jéèyàn.

Ọlọ́run gbà àwọn tí ó pinnu láti ya ara wọ́n kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láti subú, lẹ́yìn tí ó ti kìlọ̀ fún wọ́n, tí ó sì fí ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wọn. Ọlọ́run sì fà wọ́n lé ìfẹ́kúfẹ̀éọkàn wọn lé wọ́n lọ́wọ́ láti pa wọ́n run. Ọba Sóòlù àti Júdásì Ìsìkárọ̀tì jẹ́ àpẹẹrẹ tí a lè tọ́ka sí. Ìwà Ọlọ́run fún ìdájọ yìí wà fún olóríjorí àti orílẹ̀-èdè. Èsù lè tàn àwọn tọkọtayà láti ṣe ibi nínú èyí tí ó lè sàkóbá fún ìgbé ayé àwọn ọmọ wọn. Báyìí, ni ní àwọn ọmọ á ṣe jogún àìwàbíọlọ́run láti ìran dé ìran. Ìdílé tí owú tàbí ahun tí gogò yóò kún fún ìfarahàn àwọn nnkan wọ̀nyí nínú ìwà wọn. Bákan náà ní àyọrísí ẹlẹ́yìí nínú ìdílé tí ó kún fún àìgbàgbó tàbí àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú ìwàláàyè Ọlọ́run. Ẹ̀mí ìdílé máa ń farahàn nínú ayé àwọn ọmọ wọn. ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìdílé ni ó tí kópa nínú ìwà àfọ̀sẹ tàbí agbára àjẹ́ pẹ̀lú ìrèti ìwòsàn tàbí wíwá ojúùtú sí ìsòro tó ó dojúrú. Gbogbo àwọn nnkan wọ̀nyí ní Jésù bẹnu àtẹ́ lù síbẹ̀ kò ta ẹnikẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà nù. Yàlà bẹ́ẹ̀, ó fí tayọ̀tayọ̀ gbà wọ́n, ó sì tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú ègún sátánì. Jésù sọ pé, “Tí ọmọ bá sọ ọ́ di òmìnira, wà á di òmìnira nítòótọ́” (Jòhánù 8:36). Agbára àti àsẹ Kírísítì kọjá wa. Òun nìkan ni ó lè já gbogbo ìdè èsù.

Ọlọ́run kọ́ wa pé ìdílé tí ó bá ṣé ọkàn rẹ̀ le yóò gbà ìjẹníyà láti ìran ìkẹta dé ìkẹrin àyafi tí àwọn ènìyàn ìdílé yìí bá ronúpìwàdà nítòótọ́, tí wọ́n sì yí padà sí Ọlọ́run. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àwọn ọmọdé àti àgbá a máa jẹ́ èso àhunpọ̀ ìran aláíwàbíọlọ́run. Síbẹ̀síbẹ̀, a kò ní láti dá wọ́n léjó ṣùgbọ́n kí a gbà wọn, kí á sì fìfẹ́ hàn sí wọ́n. ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti Mùsùlùmí ní ó tí jilẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ àwọn bàbá ńlá wọn tí ó lòdì sí tàbí tako ọmọ Ọlọ́run. Wọ́n ń gbé nínú àpapọ̀ ìdè ẹ̀sẹ̀, wọ́n sì kọ olùgbàlà ayayé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di òmìnira kúró nínú irú àwọn agbára tí ó lòdì sí Kírísítẹ́nì báyìí gbọ̀dọ̀ kọ̀ ìbásepò àtíjó pẹ̀lú wọn sílẹ̀, kí ó sì gé gbogbo ìbásepò àṣà nítorí Jésù. Nígbà tí á bá sì sẹ́ àwọn agbára ààbò ìdílé àti tí orílé-èdè, ní a ó wá ríi dájú pé lóótọ́, Ọlọ́run ni bàbá wa. Yóò gba akọ́so ojó ìwájú wa. Ó sì máa ń mú dá wa lójú lóòrèkóòrè pé, “Emi ni Olúwa Ọlọ́run rè, bàbá tí ó fẹ́ràn títí. Mo mò ọ́, mo tí pé ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, tèmi ni ò ó ṣe, gbékẹ̀lé mi, kí ó sì kọ gbogbo ìbásepò ibi àti tí àìmọ́ sílẹ̀ pátápáá. Gbẹ́kẹ̀lé òtítọ́ àti àsẹ mi, wà á sì dí òmìnira, a ó sì pa ọ mọ́ títí ayé”.


4.04.8 - Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ìbùkún fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run

Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ Ọlọ́run, tí ó sì bọ̀wọ̀ fún un, yóò ṣe asàrò nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, á sì máa gbé nínú okun rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ bí oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ fún wa ṣe jilẹ̀ tó máa yìn ín nígbàgbgbo fún ìdándè àti sùúrù rẹ̀. À ń fí ìfẹ́ wa hàn sí nípa dídúpé lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa. Onígbàgbọ́ tí ó moore yóò ní ìsura nínú agbára, ìbùkún àti ìtọ́sọ̀nà nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoójúmọ́. Kínní èrò yín nípa ìyàwó tí ó gbá lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀ láìka ohun tí ó wà nínú rẹ̀ tí ó sì pa á mọ́? A ó sọ pé irú ìyàwó bẹ́ẹ̀ kò fẹ́ràn ọkọ rẹ̀. Nítorí ìyàwó tòótọ́ yóò máa sàfẹ́ẹ̀rí láti gbọ́ tàbí ka lẹ́tà ọkọ rẹ̀. Nígbàkúgbà tí ó bá sì gbà lẹ́tà yóò já a lẹ́sẹ̀kẹṣẹ̀, yóò kà á lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà, á sì ronú lórí àwọn ìlà kọ́ọ̀kan tí ó gba àkíyèsí títí á fí há gbogbo rẹ̀ sórí. Tí a bá nìfẹ̀ẹ̀ Ọlọ́run, a ó ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ bí ẹni pé lẹ́tà ìfẹ́ tí a kọ̀ sí wa láti ọ̀run ni. A ó máa kà wọn lóòrèkóòrè, a ó sì há àwọn ẹ̀kọ́ tí ó ṣe pàtàkì sórí. Ọkàn wa yóò kún fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí yóò máa fún wa ní agbára láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

Tí àwọn òbí bá gbàdúrà nítòótọ́ fún ìdílé wọn, wọ́n ń fa ìbùkún Jésù sórí àwọn ìdílé wọn. Àwọn ọmọ kí yóò sì dàgbà sínú ìwàbíọlọ́run ṣùgbọ́n, wọ́n á ní ìpìlẹ̀ tó dúró. Dájúdájú, àwọn òbí kò lè fí ipá mú àwọn ọmọ wọn láti gbàgbọ́ nínú olúwa kírísítì, tàbí bí wọ́n fí lílú dá wọ́n nídè kúrò nínú ibi. Ṣùgbọ́n àpẹẹrẹ òbí aláyọ̀ àti onífẹ̀ẹ́ á máa gbà ọkàn wọn bí wọ́n tí ń ríi. Àwọn ọmọ máa ń rání ìwà àwọn òbí wọn ju ọ̀rọ̀ wọ́n lọ. Ojú àwọn ìyá sì ń sọ̀rọ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wọn lọ bí ìfẹ́ wọn tí kọjá ìsà-òkú.

Ọlọ́run pàsẹ ìbùkún sórí àwọn tí ó fẹ́ ẹ títí dé iran ẹgbẹ̀rún. Ìlérí yìí sì fún àwọn òbí ní ìtùnú ńlá tí wọn bá nílọ̀ láti tó àwọn ọmọ wọn ní àkókò tí ó kún fún ìdánwò àti àìwàbíọlọ́run. Agbára Ọlọ́run wọnú òkùnkùn bí ìmólẹ̀ tí wọnú yààrà tí òkùnkùn wà. Àwọn ogún tí ẹ̀mí fún ìdílé kan yóò pọ̀ sí nígbà tí àwọn òbí bá jẹ́ onígbàgbọ́ tó ń gbàdúrà.

Njẹ́ ó tí gbìyànjú láti sí iye àkókò tí ó wà nínú ìran ẹgbẹ̀rún? Tí a bá mú ọdún mẹ́ẹ́dọ́gbọ̀n fún ìran kan, a ó rí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ́dọ́gbọ̀n ọdún tí ó kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún Ọlọ́run tórí onígbàgbó kan. Tàbí tí a bá fí ojú ọmọ ọmọ nínú ìdílé ńlá kan wò ó, a ó rí àwọn ọmọ tí ó pọ bí òwó àwọn ọmọ ogun ẹ̀mí. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni yóò sì di alábùkún fún nípasẹ̀ àwọn òbí olótítọ́ àti onígbàgbọ́. Ọlọ́run mú dá àwọn tí ó fẹ́ lójú pé gbogbo onígbàgbọ́ òtítọ́ yóò jẹ́ orísun ìfẹ́ fún ogórùn-ún ènìyàn. Ọmọlẹ́yìn Kírísítì tòótọ́ kìí rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orísun ìwàbíọlọ́run ṣùgbọ́n wọn a máa rí ara wọ́n gẹ́gẹ́ bí ipa fún oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, Ọlọ́run fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ láìbéèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn.

Tí a bá tí ní ìrírí ipa ìbùkún àwọn òbí wa nínú ara tàbí nínú ẹ̀mí lórí ayé wa, nígbà yìí ni a tó lè mọ rírí àwọn àṣà ayé yìí. A gbọ́dọ̀ rí ipa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ní ipa lórí ayé abúlé tàbí ìlú kan tàbí àwọn ènìyàn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgọ́rùn-uń ọdún sẹ́yìn. Àwọn ènìyàn ń rú ẹbọ ọpẹ́, wọ́n sì ń sìn ara wọn níbi tí Jésù tí tú àwọn ènìyàn sílẹ̀. Tí Ọlọ́run bá lè ní ipa lórí àṣà kan nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀, àwọn ìdílé, ilé-ìwè, ètò ọrọ̀ ajé àti ètò òsèlú yóò gbà ìfọwọ́tọ́ jú òye ènìyàn lọ.

Njẹ́ ó tígbìyànjú láti ṣe ìsírò iye àkókò tí ó wà láàrín ẹgbẹ̀rún ìran? Tí a bá yan ọdún márùndínlógbọ̀n fún ìran kan, á jẹ́ wí pé a ní ìbùkún Ọlọ́run fún ẹgbẹ́rún márùndínlógbọ̀nọdún gẹ́gẹ́ bí èrè tí a jẹ́ láti ara onígbàgbọ́ òtítọ́ kan ṣoṣo. Tàbí tí a bá rò ó nípa tí àwọn ọmọ ọmọ nínú ìdílé ńlá kan, a jẹ́ wí pé a ó ní ogunlọ́gọ̀ ọmọ tí ó tobi bíi ọmọ ogun ti ẹ̀wú, gbogbo àwọn tí a ó bùkún fún nípasẹ̀ àwọn òbí tí wọ́n gbàgbọ́ tí wọ́n sì tún jẹ́ olùgbọràn. Ọlọ́run fi da àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ lójú pé, gbogbo onígbàgbọ́ òtítọ́ yóò jẹ́ orisun ìfẹ́ sí ọgọ́rùn ún ènìyàn. Ọmọlẹ́hìn Jésù kan kò jẹ́ sọ wí pé òun ni orisun ìwà bí Ọlọ́run fúnrarẹ̀, kaka bẹ́ẹ̀ ó rí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà sí oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.Nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀, Ọlọ́run fi oore ọ̀fẹ́ kún oore ọ̀fẹ́ aláìlódìwọ̀n fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì gbà á gbọ́.

Tí a bá tí ní ìrírí ipa tí ìbùkún ti ara àti ti ẹ̀nú àwọn òbí wa ní lórí ayé wa, nígbà náà a ó mọyì oríṣìírísìí àṣà àgbàyé. Tí o bá rí ibi tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ní ipá lórí abúlé, ìlú àti àwọn ènìyàn ní nnkan bí ọgọ́rùnún ọdún sẹ́yìn, ìwọ yóò ní ìmọ̀lára rẹ̀. Níbi tí àwọn ènìyàn ti gba ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ Jésù, wọ́n ń ṣe ìdúpé wọ́n sì ń sin ara wọn. Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run lè ní ipa lórí àṣà kan ọwọ́ Èmí Mímọ́, ìdílé, ilé ẹkọ́, okowo ati oṣelú pẹ̀lú nípá lórí wọn jù òye wa lọ.

Ìdàkejì ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn orílẹ̀ èdè tí ó ń bọ òrìṣà tí ó ní àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ lára bí èyí tí wọ́n ń bọ ní India tàbí àwọn tí wọ́n ń bọ àwọn alálẹ̀ bí ti China tàbí Áfírikà níbi tí ìbọ̀rìṣà àti agbára àlúpàyídà wà fún ìdáàbòbò. Àwọn agbègbè yìí kún fún ìbẹ̀rù, ìsùrú àti ìpayà. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní wọ́n fí ògo obìnrin wọ́lẹ̀ nítorí pé a o fún ọkùnrin ní tipá. Ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà máa ń dènà ìlọsíwájú, tí àwọn òtòṣì yóò sì tún máa tòṣì síì. Ti ó bá wọ ìlú kan tí ó jẹ́ ti Mùsùlùmí, Hínolù tàbí Kírísíténì ní kánkán ní ìwọ yóò mọ irú ẹ̀mí tí ó ń darí agbègbè bẹ́ẹ̀, kódà ẹranko ní ìmọ̀lára boya ìnà búburú ni wọ́n nà wọ́n tàbí wọn ṣe ìtójú wọn ni.


4.04.9 - Ìsọnísókí Ìpínyà tó ṣe Kókó

Àwọn ìbùkún tí ó wà nínú gbígba àwọn òbí ẹni gbọ́ fi ara hàn nínú àwọn ohun tí ó jẹ yọ lára oníkálukú tàbí ìdílé gẹ́gẹ́ bí èsolèrè ìfẹ́ aláìlábàwọ́n àwọn òbí wa àgbà sí Ọlọ́run. Irú àwọn òbí àgbà báyìí gba àdúrà kíkan, wọ́n ṣiṣẹ́ takuntakun, wọ́n sì tún gbé ìgbé ayé pipe títí ọjọ́ ogbó wọn. Lótìítọ́, ìyàtọ̀ ńlá wà láàárín àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run àti àwọn tí kò fẹ́ ẹ káàkìri àgbáyé. Tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bíi baba nítòótọ́, ìwọ yóò sinmi lé e gẹ́gẹ́ bí ọmọ, ìwọ yóò sì tún so èso ìfẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni/ẹnikan bá kọ̀ láti képe Ọlọ́run, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò sọnù kúrò nínú ìwà bíi Ọlọ́run. Kò yanilẹ́nu pé ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ń rẹ̀wẹ̀sì ní ìkẹhìn ọjọ́ tí a wà yìí. Ẹni tí ó kọ̀ láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run yóò di orisun ìwà búburú gbogbo. Ẹ̀kọ́ òdì sí Ọlọ́run ni yóò sì máa ti ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wá. Karl Marx mọ Ọlọ́run ní òwúrò ayé rẹ̀ ṣùgbọ̀n, ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó bẹ̀ẹ̀ tí ó fi si ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà, àwọn ẹni tí ohun asán ayé yìí gba ọkàn wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ kò lè wọ páradísè bí ó tí wù kí wọ́n ṣe tó ní ayé yìí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ Ọlọ́run, tí ṣe orisun ìfẹ́ àti ìyè, tí ó sì gbé ẹ̀nìyàn ga ní ìpò Ọlọ́run, gba ìbànújẹ́ sí ọkàn rẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò ri ìbìnú Ẹni Mímọ́ náà ní ọjọ́ ìdájọ́.

www.Grace-and-Truth.net

Page last modified on March 18, 2014, at 08:42 AM | powered by PmWiki (pmwiki-2.3.3)