4.05 - ÒFIN KẸTA: Ìwọ kò gbọdọ̀ pè Orúkọ Ọlọ́run rẹ̀ lásán
EKÍSÓDÙ 20:7
“Ìwọ kò gbọdọ̀ pè orúkọ olúwa Ọlọ́run rẹ lásán nítorí tí Olúwa kì yóò mú àwọn tí ó pè orúkọ rẹ̀ lásán bí aláìlẹ́sẹ̀ ní ọrùn”
4.05.1 - Orúkọ Ọlọ́run
Ọmọ ènìyàn kò lè wà láàyè láìsí ẹlẹ́dàá rẹ̀. A dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ènìyàn kọ ẹlẹ́dàá rẹ̀ sílẹ̀. Láti ìgbà náà ni ọmọ èníyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ayé yìí, tí o ń wá ilé rẹ̀ tí ó sọnù, tí ó sì ń fẹ́ ibi orisun ìkọ̀kọ̀ rẹ̀. Láti ìgbà yìíni ọmọ ènìyàn ti yá onírúurú ère tí ìrísí rẹ̀ banilẹ́rù jọjọ fún ara rẹ̀, èyí tí ó ń fi ìbẹ̀rù àti ìpòngbẹ ọkàn ọmọ ènìyàn hàn. Ó ń ná owó lórí agbára àlùpáídà, ìràwọ̀ wíwò àti àkọsẹ̀jayé dídá, èyí tí kò lè mú ààbò tí ó péye wá. Àwọn Mùsùlùmí máa ń lọ ju òkò àsètánì ní ìrètí pé ó ń lé sátáni jìnnà, ó sì ń pe ẹ̀mí láti ọ̀run láti dààbò bò wọ́n. Àwọn ẹlẹ́sìn Búdì ń bọ ère búdà tí ó ń fi àwọn òpè tí ó ń fí ni rérìn-ín ẹlẹ́yà.
Ìfarahàn Ọlọ́run fúnrarẹ̀ gan ní pé “Èmi ní Yaweh”, Ọlọ́run ní èyí tí ó yẹ kí ó ti fi òpin sí a ń wá Ọlọrun ká tí ọmọ ènìyàn ń ṣe. Ìfarahàn rẹ̀ nínú ìgbẹ́ tó ń jó jẹ́ ìtàn ìwásẹ̀, nítorí Ọlọ́run jẹ́wọ́ agbára àti orúkọ rẹ̀, Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ni Ọlọ́run ti fi ara rẹ̀ hàn nínú májẹ̀mú láìláí àti májẹ̀mú titun. Bíbélì sọ 638 orúkọ àti ìrísí Ọlọ́run. Nínú èdè Hébérù àti Árábíìkì, ìrísí Ọlọ́run kọ̀ọ̀kan tún jẹ́ orúkọ Ọlọ́run. Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run kìí ṣe olọ́dọdo nìkan ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ Ọlọ́run òdodo nínú ẹni ti ìwà òdodò gbogbo kóra jọ pọ̀ sí kìí ṣe ẹni mímọ́ nìkanṣùgbọ́n, ó tún jẹ́ Ọlọ́run mímọ́ tí ó kún fún ìwà mímọ́. Ìkọ̀ọ̀kan àwọn orúkọ wọ̀nyí jẹ́ ìtànsán ògo rẹ̀. Síbẹ̀ orúkọ Ọlọ́run tí ó jẹ yọ púpọ̀ ju àwọn ìyókù lọ ni Yaweh (ìgbà 6,828 ni ó jẹ yọ nínú májẹ̀mú láíláí) orúkọ yìí túmọ̀ sí alágbára tí ó ń gbéniró, Ẹni Mímọ́, Ẹni pipe, Ọlọ́rún ìwáṣẹ̀, Ẹni tí kò yí padà, tí kò sì lè yí padà nínú òtítọ́ rẹ̀.
4.05.2 - Olúwa ní Inú Májẹ̀mú Titun
Ọlọ́run di ènìyàn nípasẹ̀ Jésù ti Násárẹ́tì nínú Májẹ̀mú Titun. Àwọn áńgẹ́lì, Wòólì àti gbogbo onígbàgbọ́ jẹ́wọ́, wọ́n sì tún gbà pé “Jésù ni Olúwa” síbẹ̀, Jésù kò gbé ara rẹ̀ ga, ṣùgbọ́n nígbàgbogbo, Ó ń fi ọlá fún Bàbá rẹ̀ tí ń bẹ ní ọ̀run. Kódà, ó kọ̀ wa láti gbàdúrà pé Bàbá wa tí ń bẹ lọ́run, ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ rẹ. Nínú àdúrà yìí, ó fí ọlá ògo àti ìsọdímímọ́ fún orúkọ Bàbá rẹ̀ sáájú àti lékè gbogbo orúkọ mìíràn. Ìfarahàn Ọlọ́run bàbá nípasẹ̀ Jésù tí gbé ìmọ̀ wa nípà Ọlọ́run sókè dáadáa.
Jésù pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ di ènìyàn. Ó parí 1ṣẹ́ ìgbàlà láàrín Ẹmi Mímọ́ náà àti gbogbo ẹlẹ́sẹ̀ nípasẹ̀ ikú rẹ̀ lórí igi àgbélèbú tí ó kún fún ìtìjú. “Nítórí náà Ọlọ́run pẹ̀lú sì tí gbé ẹ ga gidigidi, ó sì tí fí orúkọ kan fún un tí ó borí gbogbo orúkọ pé, ní orúkọ Jésù ní kí gbogbo eékún kí ó máa kúnlẹ̀, àwọn ẹni tí ń bẹ ní ọ̀run, àti àwọn ẹni tí ń bẹ ni ilẹ̀ àti àwọn ẹni tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ àti pé kí gbogbo àhọn kí ó máa jẹ́wọ́ pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run Bàbá” (Fílípì 2:9-11). Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń fi ìyìn fún ojúlówó orúkọ Jésù gan láti ìgbà yìí wá, ó sì ń mú u dá wa lójú pé òun ni Olúwa. Bákan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ fi dá wa lójú ìsọ̀kan tí ó wà láàrín Ọlọ́run Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́. Ìsọ̀kan ìfẹ́ pipe tí ó ń sọ títóbi/pàtàkì Ọlọ́run wa. Dáfídì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nípa ìfìhàn yìí: Olúwa wí fún Olúwa mí pé, ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi ó fí sọ àwọn ọ̀tá rẹ̀ di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ (Orin Dáfídì 110:1).
4.05.3 - Kí ni ó túmọ̀ sí láti mọ orúkọ Ọlọ́rin
Bí àjòjì ènìyàn bá wọ ìlú kan, inú rẹ̀ yóò dùn láti ní àdírẹ́sì ẹnikan tí ó mọ̀ níbẹ̀. Ó lè pẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti bèèrè fún ìtọ́nà àti ìrànlọ́wọ́. Ẹni ìdùnnú ni ọkùnrin náà tí ó mọ orúkọ Ọlọ́run gidi tí ó sì tún pa nọ́mbà ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́ (Orin Dáfídì 50:15). Kí o sì képè mi ní ọjọ́ ìpọ́njú; èmi ó gbà ọ́, ìwọ ó sì máa yìn mi lógo. Olúwa wa tí ń bẹ lọ́run kò sùn, bẹ́ẹ̀ni ó ń fi ìtara dúró dé ohùn ìpè tí ẹ̀mí wa.
Gbogbo ìbápàdé wa pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́ ń fi ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú ẹ̀sẹ̀ hàn ketekete, bí a ṣe wà ní àwa nìkan àti ìsọnù wa.Títóbi mímọ́ rẹ̀ ṣe àfihàn bí ìwà mímọ́ wa ṣe kéré tó, ó si tún ṣe àfihàn àìnáání ènìyàn tìwa. Dídára Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti lé jẹ́wọ́ ẹ̀sẹ̀ wa àti pẹ̀lú, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ fí oró ìgbésógo wa hàn. Mímọ orúkọ Ọlọ́run mú kí ó ṣe ẹ́ ṣe fún àwọn oníròbínújẹ́ọkan wà ni ìbàṣepọ̀. pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ìgbàgbọ́ wa tí ó ń gbòòrò síi nínú Ọlọ́run mú wa ní gbòngbò síi nínú òfin kẹta bí ó ṣe sọ wí pé, “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ”, níbi tí ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ ‘rẹ̀’ tí fí hàn pé Ọlọ́run, Ẹni Mímọ́ nì, fí ara hàn pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá rẹ̀, àwọn ẹlẹ́sẹ̀, àwọn tí kò péye àti àwọn aláìlágbára. Ó fún wọn ní ìdánilójú òtítọ́ rẹ̀ àti ààbò rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú titun tí wí, ó sọ wa/mú wa wọ inú ẹbí Ọlọ́run, níbi tí Jésù tí jẹ́ orí tí àwa sí jẹ́ ẹ̀yà ara tí ó ń ṣiṣẹ́ fún ara kan nínú ẹ̀mí. Ọlọ́run Baba fẹ́ wà ní ọkàn kan pẹ̀lú ẹ̀mí kan pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lé ṣiṣẹ́ láti gba ìran búburú yìí là. Nínú àánú rẹ̀, ó fún wọn ní àsẹ láti gbàgbọ́, kí wọ́n ṣe ohun gbogbo ní orúkọ rẹ̀.
4.05.4 - Pípe Orúkọ Olúwa ní Àsán
A ń gbé nínú ayé tí oríṣìísíṣìí àfihàn láti inú Bíbélì ní ipa lórí rẹ̀. Síbẹ̀, ènìyàn díẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn. Bí ènìyàn kò bá máa gbé níwájú Ọlọ́run nígbà gbogbo, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò máa lo orúkọ Olúwa lásán. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń lo orúkọ yìí láì sí ìyàtọ̀, à fí bí ẹni pé wọ́n ń san owó lórí ohun tí kò níye lórí. Kó dà, àwọn onígbàgbọ́ pàápàá lé mú Ẹ̀mí Mímọ́ bínú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ asán wọn. Wọ́n jẹ́ aláìlérò nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run. Òfin kẹta ṣe ìkìlọ̀ ó tún gbà wá níyànjú nípa pipe orúkọ Olúwa ní asán.
Àwọn onígbàgbọ́ aláìlérò kan máa ń sọ̀rọ̀ orúkọ Ọlọ́run láì fí ọlá fún nígbà tí wọ́n wí pé, Ọlọ́run o! pẹ̀lú Ọlọ́run! Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n dàbí àwọn ọmọdé tí wọ́n ń fí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ṣeré, wọ́n á kàn pè nọ́mbà kan láì bá ẹni tí ó sáré wá láti gbà ìpè náà sọ̀rọ̀ kankan. Ó dájú pé, bí wọ́n bá tẹ̀síwájú ní síṣe báyìí, inú yóò bí irú ẹni tí a ń pè bẹ́ẹ̀ yóò sì kọ̀ láti gbọ́ irú aago ìpè tí ó ń dàá láàmú bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run gbọ́ nígbà tí a pè é. Kínni èrò rẹ̀ nígbà tí ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀? Bí ó bá ló orúkọ rẹ̀ ni ìlò aláìlérò, ìyẹn fihàn bí ìgbé ayé rẹ̀ níwájú Olúwa ṣe kéré tó.
4.05.5 - Mùsùlùmí ń Sọ̀rọ̀ Orúkọ Allah
Mùsùlùmí yẹ kí ó sọ̀rọ̀ orúkọ Allah nígbà gbogbo, nírètí pé òun yóò di ẹni ìdáláre, kí á sì ríi gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣe é fí ọkàn tán, olódodo àti onígbàgbó, ó gbàgbọ́ pé bí òun ṣe ń sọ̀rọ̀ orúkọ Allah tó bẹ́ẹ̀ni Allah ń ṣe àforíjìn fún ẹ̀sẹ̀ òun. Ìgbàgbọ́ yìí mú èbò ìsìn tó kéré tí pipe orúkọ Allah lófo/lásán jẹ́ lára rẹ̀. Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé Mùsùlùmí kò ní ìbàṣepọ̀ ojúkojú pẹ̀lú Allah. Ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Allah dàbí kíkùn ẹrú si ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ọ̀gá rẹ̀; bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ó to ọgọ́rùn ún mẹ́jọ mílíọ̀nù (800 million) Mùsùlùmí ní kò ní ìmọ̀ Àrábíkì. Ó ṣe ni láàánú àwọn kan pẹ̀lú máa ń ka àdúrà Olúwa láìni àròjinlẹ̀ kíkùn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní àwọn ìjọ kan máa ń kàá ní àkókò ìjọ́sìn wọn.
4.05.6 - Àdúrà Ìyèméjì àti Àríyànjiyàn tí kò Nílárí
Kò sí Mùsùlùmí tí ó ń ka kéhú ní ìkà aláìlérò, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kírísíténì ní wọ́n ń ka àdúrà gẹ́gẹ́ bí orin tí ìyá máa fí ń rẹ ọmọ té. Báwo ní á ó ṣe képe Ọlọ́run láì ní ìrètí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ tàbí kí á máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nígbà tí a ń ronú nípa okòwò wa tàbí àwọn ohun mìíràn tí kò ṣe pàtàkì? Bí ó bá jẹ́ pé fún àpẹẹrẹ, a ní oore-ọ̀fẹ́ láti bá ààrẹ orílẹ̀ èdè wa sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ṣé a kò tí ní ronú ohun tí a ó sọ kí á sì gbé e yẹ̀wò dáadáa kí a tó sọ ọ́? Síbẹ̀, Ọlọ́run kò ṣe pàtàkì sí wa tó ọmọ ènìyàn. Bí ènìyàn bá gbàdúrà láì ronú, irú ẹni bẹ́ẹ̀ gan Ọlọ́run.
Àwọn onímọ̀ Bíbélì nígbà mìíràn máa ń wá ní bèbè ìṣelòdì sí òfin kẹta, tí wọ́n sì ń tí pá bẹ́ẹ̀ mú Ẹ̀mí Mímọ́ bínú nígbà tí wọ́n bá kọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ìrísí àti iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run bí ìgbà tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́nsì láì ní ìmọ̀ lára ìwàláàyè Ọlọ́run. À kò lé ní èròngbà, ìṣọ lásán nípa Ọlọ́run níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run kìí ṣe ohun aláìlẹ́mìí. Ẹ̀mí ní Ọlọ́run, tí ó sì ń bá wa gbé nígbà gbogbo. Ó ń gbọ́ ìtakùrọ̀sọ wa bẹ́ẹ̀ ni ó mọ́ èrò ọkàn wa láti ọ̀nà jínjìn. Nítorí ìdí èyí, ìmọ̀ nípa ẹ̀kọ́ Bíbélì tí kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run òun ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run nínú, láìsiyèméjì ń yọrí sí ìṣelòdì sí òfin kẹta.
4.05.7 - Ìlò Orúkọ Ọlọ́run ní Ìlò Ẹ̀ṣẹ̀
Ègbé ní fún ẹnikẹ́ni tí ó mọ̀ọ́ mọ̀ lọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run po, yẹ̀yẹ́ rẹ̀ tàbí fí ṣe àwàdà! Wọ́n a máa pẹ̀gàn orúkọ tí ó borí gbogbo orúkọ láì fí ìbẹ̀rù hàn tàbí fí ọ̀wọ̀ fún un. Nítorí ìdí èyí, à kò gbọdọ̀ darapọ̀ mọ́ àwọn tí ó ń fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe yẹ̀yẹ́. Dípò bẹ́ẹ̀, kí á bá irú àwọn ẹlẹ̀gàn bẹ́ẹ̀ wí, kí á sí dìde fún Ọlọ́run. Àwọn ònkọ̀wé àti ọ̀nkọ̀tàn mọ rírì ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, wọ́n sì máa ń lò wọ́n nínú iṣẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n wọn kìí lò ọ̀rọ̀ bíi “ẹ̀ṣẹ̀”, ọ̀run àpáàdì tàbí “sègbé”, wọ́n fún irú àwọn ọ̀rọ̀ báwọ̀n yìí ní ìtumọ̀ tí ayé. Ọ̀rọ̀ wọn yóò padà wa sórí wọn, yóò sì dá wọn lẹ́bi.
Ọmọ ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà máa ń bínú sí ara wọn, nínú ìbínú wọn yìí, wọ́n máa ń gégùn ún fún ara wọ́n pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run, Allah tàbí Jésù. Wọ́n túra tàbí sọ̀rọ̀ ègbé àti àwọn kókó ẹ̀sìn mìíràn láìronú nípa wọn. Ìránṣẹ̀ Ọlọ́run kan kọjá lára ọkùnrin abánikọ́lé kan, ó sì gbọ bí ó tí ń gégùn ún àti sèpè, ó wá bíi pé ṣe bẹ́ẹ̀ náà ní ó ṣe máa ń gbàdúrà sókè tó? Ọkùnrin abánikọ́lé yìí kò mọ́ ohun tí yóò sọ, ó wá dáhùn pẹ̀lú ìbínú pé kìí ṣe àdúrà ní òun ń gbà. Ìránṣẹ̀ Ọlọ́run wá sọ fún un wí pé, ṣùgbọ́n mọ gbọ́ pé ó ń pé orúkọ Ọlọ́run, ní èyí tí ó sì dájú pé Ọlọ́run yóò dá ó lóhùn. Ọkùnrin yìí kò mọ ohun tí yóò ṣe mọ́, ó dáwọ́ iṣẹ́ dúró.
Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn máa ń lo ọ̀rọ̀ ègún fún ara wọn tàbí ẹbi wọn láìkà sí ìkórira ńlá ní ó wà lẹ́hìn àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Jésù ka irú àwọn ọ̀rọ̀ ègún báyìí sí ìpànìyàn nítorí pé wọ́n bu àwòrán Ọlọ́run nínú ènìyàn kù.
4.05.8 - Ìkìlọ̀ Ọlọ́run: Ìjìyà Tí Ó Rorò
Òfin kẹta jẹ́ ìkìlọ̀ tí ó ṣe kókó, “Ọlọ́run kò ní sàì fìyàjẹ ẹnikẹ́ni tí ó lo orúkọ rẹ lásán”. Pẹ̀lú gbogbo ìkìlọ̀ yìí, àwọn ènìyàn kan sì ń lo orúkọ Ọlọ́run láti fí bo iṣẹ́ ibi wọn mọ́lẹ̀, wọ́n sì ń mọ̀ọ́mọ̀ lo orúkọ rẹ̀ láti ṣe àwíjàre fún ara wọn. Ègbé ni fún ọkùnrin náà tí ó pé orúkọ Olúwa lásán láti fí bo irọ́ àti àgbàbàgebè mọ́lẹ̀! Àwọn ènìyàn kò gbá ara wọn gbọ́ mọ́ ní ayé òde-òní nítorí pé wọ́n kò sọ òtítọ́ mọ́ kódà nígbà tí wọ́n bá tún búra ní orúkọ Olúwa. Jésù pàápàá tilẹ̀ sọ fún wá pé a kò gbọdọ̀ búra, kí a jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ni wa jẹ́ bẹ́ẹ̀ni, kí bẹ́ẹ̀kọ́ wa pẹ̀lú sì jẹ́ bẹ́ẹ̀kọ́. Nítorí pé ohunkóhun tí ó bá ju èyí lọ, ọ̀dọ̀ ẹni búburú/ibi nì ni ó ti wá (Matteu 5:37). Bí a bá búra tí á sì paró, a kò paró fún ènìyàn nìkan ṣùgbọ́n fún Ọlọ́run pẹ̀lú. Ìbúrà èké wà ní abé òfin kẹta tí ó kìlọ̀ fún wa nípa pipe orúkọ Olúwa lásán. Ìdí nìyí tí Bíbélì fí sọ wí pé “Ìbẹ̀rù Olúwa ní ìpilẹ̀sẹ̀ ọgbọ́n”. Gbogbo wa ni a nílò ìbẹ̀rù Olúwa kí á máa ba à subú sínú ẹ̀sẹ̀.
Ọlọ́run kórira ẹni tí ó mọ òun síbẹ̀ tí kò képe òun ní àkókò ìpọ́njú tàbí retí ìdáhùn rẹ̀ tàbí ìtọ́ni òun ṣùgbọ́n tí ó lọ tààrà sí ọ̀dọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ tí ó pé orúkọ Olúwa lásán, tí ó pé ara rẹ̀ ní arínuróde tí ó mọ ànà, òní àti ọ̀la. Nìnú ìwé Deuteronomi 18:9, Ọlọ́run wí pé, “Nígbà tí ìwọ bá dé ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ fí fún ọ, kí ìwọ kí ó má ṣe kọ́ àti ṣe gẹ́gẹ́ bíi ìwà-ìríra àwọn orílẹ̀-èdè wọn nì”. (Lefitiku 20:6) pẹ̀lú sọ wí pé “Àti ọkàn tí ó bá yípadà tọ àwọn tí ó ní ìmọ̀ àfọ̀sẹ, àti àjẹ́ láti ṣe agbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́hìn, àní èmi ó kọjú mi sí ọkàn náà, èmi ó sì ké ẹ kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀”. Ó tún jẹ́ ohun àìgbọdọ̀ ṣe láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú òkú tàbí láti gbá ìmọ̀ràn lọ́wọ́ wọn. Irú ẹ̀sẹ̀ báyìí láìṣe àníàní máa ń ya ènìyàn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, kí ó sì sí ọkàn ènìyàn sí ọ̀dọ̀ èsù àti àwọn ẹ̀mí rẹ̀. Ní ojú Ọlọ́run irú áìsòdodo báyìí dàbí èdsẹ̀ àgbèrè, ó dàbí ìjọlójú tí ọkùnrin tí ó ṣe aláìsòtítọ́ sí aya rẹ̀ mú bá a nípa níná owó aya rẹ̀ sírí àwọn alágbèrè obìnrin níta. Kò jẹ́ ohun tí ó yanílẹ́nu pé Olúwa pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ní àgbèrè tí ẹ̀mí (Lefìtìku 20:6) àti irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni “ènìyàn ibi àti ìran alágbèrè”.
Ní ilẹ̀ Àfríkà àti Àsíà, àwọn ènìyàn máa ń ṣe oògùn láti fí dáabòbo ara wọn lọ́wọ́ ibi. Wọ́n máa ń ṣan ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lórí rẹ̀, wọ́n sì gbékẹ̀lé wọn. Wọ́n tún máa ń kọ lẹ́ta pẹ̀lú oògùn láti lé ṣe àseyọrí lẹ́nu okòwò wọn, wọ́n tún ṣe oògùn ìfẹ́ láàrin lọ́kọ láya. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ń ṣe irú àsà yìí kò mọ Ọlọ́run nítòótọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ máa ń ṣe àfihàn agbára àlùpáìdà, èèwọ̀ àti ìbá òkú sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ móhùn-máwòrán. Àwa gẹ́gẹ́ bí Kírísítẹ́nì rí àfihàn àti irú ẹ̀kọ́ báyìí gẹ́gẹ́ bí igbógun tì Sàtánì lórí àwọn ọkàn tí ó wò ó. Kò sí ohun tí wọ́n ń ṣe jù pé wọ́n ń sí ọ̀nà ọrùn àpáàdì sílẹ̀ lọ. Síbẹ̀ Ọlọ́run kilo fún wa nípa àwọn ewu wọ̀nyí tí ó ń yà wá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ní ojúkojú. Jésù nìkan ní ó le tú irú àwọn ọkàn bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìgbèkun tí wọ́n wà. Wíwọ̀ ìràwọ̀, kíka ílà ọwọ́ tàbí didró nínú òfurufú láti pé ẹ̀mí àìrí jẹ́ ọ̀nà àbùjá sí ọ̀run àpáàdì. Àwọn alásọtẹ́lẹ̀ wà ní àwọn ilé ìtura ní orílẹ̀-èdè India tí wọ́n ń dúró láti sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn èrò tí ó wá sí ilé ìtura. Wọ́n tún ya àwọ̀rán ojú tí ó ń fí ọfà wọlé li lé ojú búburú kúrò lára ẹni. Àwọn mìíràn fí irú oògùn yìí kọ́ sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn, bàtà ẹṣin lórí ilé wọn, tàbí kọ́ igi láti lé ibi dànù- irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbàgbọ́ púpọ̀ nínú agbára òkùnkùn jú agbára ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, Bàbá wọ́n tí ń bẹ lọ́run lọ. Wọ́n wá nínú ìgbèkùn agbára ayé ìsinsìnyí nítorí àwọn àṣà yìí.
4.05.9 - Ìsọ̀rọ̀ Òdì sí Ọlọ́run
Àwọn ènìyàn mìíràn máa ń ṣe àṣejù nígbà tí wọn bá ń pé orúkọ Ọlọ́run nípa fífi Ọlọ́run àti Krístì búra. Wọn darapọ̀ mọ́ àwọn tí wọ́n ń ṣe ìlòdì sí orúkọ Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́. Sàtánì jẹ́ ọ̀tá àtijọ́ tí Ọlọ́run. Ìsọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run jẹ́ ìdarapọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀mí àìmọ́ tí ó ń tú jade láti ọ̀run àpáàdì. Bí ẹnikan bá ní láti ka lẹ́ta gígùn nínú èyí tí wọ́n tí fí orúkọ Krístì gégùn ún, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò fojú winá ọ̀run àpáàdì. Ìwé (Lefìtíku 24:14-16) kà báyìí: “Mú ẹni tí ó ṣe ìfibú nì wá sẹ́hìn ìbùdó; kí gbogbo àwọn tí ó sì gbọ́ ọ kí ó fi ọwọ́ wọn lé orí rẹ̀, kí gbogbo ìjọ ènìyàn kí ó lé sọ ọ́ lí òkúta. Kí ìwọ kí ó sì sọ fún àwọn ọmọ Ìsráélì pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá fí Ọlọ́run rẹ̀ bú yóò ru ẹ̀sẹ̀ rẹ̀. Àti ẹni tí ó sọ̀rọ̀ búburú sí orúkọ Olúwa ni, pípa ní kí á pa á; gbogbo ìjọ ènìyàn ni kí ó sọ ọ́ lí òkúta pa nítòótọ́; àti àlejọ̀ àti ìbílẹ̀, nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀ búburú sí orúkọ Olúwa, pípa lí a ó paá”.
A ní láti ní ìtẹríba, kí á tún kó ara wa ní ìjánu nígbà tí á bá ń bá tàbí dá asọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run lẹ́jọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó kún fún ẹ̀mí àìmọ́, ya afọ́jú tọ́bẹ̀ tí ó fí jẹ́ wí pé nígbà tí wọ́n rò pé àwọn ń sìn Ọlọ́run, ń ṣe ní wọ́n dojú ìjà kọ Ọlọ́run àti Messaih Rẹ̀ (Johannu 15:19-21; 16:1-3). Àwọn amòye ẹ̀ṣìn ní wọ́n dájọ́ ikú fún Jésù pẹ̀lú ẹ̀rí pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run pé wọ́ jẹ́ amòye ẹ̀ṣìn, wọ́n kò mọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run Alààyè. Nínú ìlàkàkà wọn fún Ọlọ́run, wọ́n sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Àmì Òróró Rẹ̀. Wọ́n tutọ́ sí i lójú, wọ́n lù ú lẹ́sẹ̀ẹ́ lórí. Àwọn adarí àwọn ènìyàn ìgbà nì kò mọ̀ tàbí gbà Olúwa wọ́n, tí ó wà pẹ̀lú wọn. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́, wọ́n sì kàn án mọ́ Àgbélèbú. Ó ṣe ni láàánú pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn tún kọ̀ ọ́.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọkùnrin Jákọ̀bù, àwọn Mùsùlùmí rò wí pé, àwọn sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run bí àwọn bá gbá àwọn òrìṣà gbọ́ àti kíkan Jésù mọ́ àgbélèbú. Wọ́n gbà ìjẹ́rìí irọ́ àwọn Júù gbọ́, wọ́n tako ìgbàgbọ́ wọ́n nínú Ọlọ́run Mẹtálọ́kan. Wọ́n gbìn oró ìkórira sọ́kàn sí ọmọ Ọlọ́run tí a kàn mọ́ àgbélèbú. Wọ́n ń fí ìsọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run Bàbá, Ọmọ àti Ẹmí Mímọ́ hàn nípasẹ̀ ìkórira wọ́n sí ẹ̀kọ́ nípa Mẹtálọ́kan. Bákàn náà, ẹ̀ṣìn Hindu kọ àṣẹ Krístì Olúwa nípa kíkà á kún ọ̀kan nínú àwọn òrìṣà.
Àwọn apadàsẹ́hìn Kírísítẹ́nì kan tílẹ̀ mú ìsọ̀rọ̀ òdì sí yìí tóbẹ̀ tí wọ́n fí ń sìn èsù. Ní àkókò ìjọsìn wọn, wọ́n á ṣe àjọyọ̀ ńlá, wọ́n á sì tún fí ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí Sàtánì. Wọ́n yí ọ̀rọ̀ àti ìtumọ̀ Àdúrà Olúwa padà bí wọ́n ṣe ń sìn Sàtánì. Báyìí ní agbára òkùnkùn ṣe ń ká ẹni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ kọ ìgbàlà Ọlọ́run nípasẹ̀ Kírísítì.
Ṣùgbọ́n nínú Kírísítì ní ilé ìṣọ́ tí ọ̀run àpáàdì kò lè wọ̀ wà. Olùṣọ́ àgùntàn rere wa wí pé, “Àwọn àgùntàn mí gbọ́ ohùn mi, èmi sì mọ̀ wọ́n, wọ́n a sì máa tọ̀ mí lẹ́hìn: Èmi sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun; wọ́n kì ó sì ṣègbé láìláí, kò sì sí ẹni tí ó lé já wọn kúrò lí ọwọ́ mi. Bàbá mi, ẹni tí ó fí wọ́n fún mi, pọ̀ jù gbogbo wọ́n lọ: kò sì sí ẹni tí ó lé já wọ́n kúrò lí ọwọ́ Bàbá mi. Ọ̀kan lí èmi àti Bàbá mi jásí”. (Johannu 10:27-30).
Àwọn Júù fẹ́ láti pa òfin kẹta yìí mọ́ débi wí pé wọ́n bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ní orúkọ Ọlọ́run Alágbára yálà nípa àsìṣe tàbí àfòjúfọ̀. Gbogbo wa ní a mọ̀ lẹ́tà mẹ́rìn tí ó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ní èdè Hébérù ni YHWH. Li ọdún 300 lé a tó bí Krísitì àwọn Júù máa ń gbìyànjú láti yẹra fún lílọ̀ Àdónáì nígbàtí wọn bá ń ka Bíbélì nítorí ìwà mímọ́ rẹ̀ ‘Jèhófà’ jẹ́ ọ̀rọ̀ àtọwọ́dá ènìyàn tí ó jẹ yọ láti ìpaṣẹ̀ fífi ìró fáwélì tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ ‘Adonái’ bọ inú ìró kọ́ńsónántì “YHWH”. A kò tíì ṣẹ̀dá èyí bí kò ṣe bí ìwọ̀n ọdún bíi 1520 lẹ́hìn ikú Olúwa wa. A lérò pé “Yahweh” gan ni ojúlówó bí a tí ń pè é.
Elẹ́yìí lé mú kí a bèèrè yìí: Ṣé ó tọ́ láti pe orúkọ Ọlọ́run rárá? Báwo ní ó ṣe yẹ kí á pe orúkọ Ọlọ́run kí á máa ba à subú sínú ewu ìdájọ́ Rẹ̀?
4.05.10 - Sísọ̀rọ̀/Pípe Orúkọ Ọlọ́run bí ó ti yẹ/tọ́
Òfin kẹta kò sọ wí pé kí á máa pe orúkọ Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀mí tí ó tọ́. Ìlérí ńlá ni èyí, “Ìwọ kò pe orúkọ Olúwa ni asán bí ó bá lò ó pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ọkàn ọpẹ́”. Olúwa yóò lo ẹ̀rí ìgbàgbọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà fún ìrònúpìwàdà àti ìwẹ̀nùmọ́ ní ayé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Orúkọ rẹ̀ kò ní agbára àlùpáyìdà tí a le lò fún ìfẹ́ ọkàn wa tàbí bí a tí fẹ́. Olúwa alààyè ń dá bírà nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èrò ọkàn àti ìlànà rẹ̀. Àpóstélì Pétérù sọ fún ọkùnrin arọ nì, “Ní orúkọ Jésù Kírísítì tí Násárétì, dìde kí ó sì máa rìn”. Ó tún sọ ọ́ síwájú síi fún àwọn alàgbà àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn, “Ní orúkọ Jésù Kírísítì tí Násárétì ní ọkùnrin tí ó dúró níhìn yìí ṣe di pipe” (Ìṣe Àwọn Àpóstélì 3:6,16; 4:10). Ẹ jẹ́ kí á jẹ́ kí ìmọ̀ wa nípa orúkọ àti agbára Jésù jìnlẹ̀. Schlatter, gbajúgbajà, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì, fí ọkàn kọ́ gbogbo májẹ̀mú títun ní èdè Gíríìkì, ṣùgbọ́n lẹ́hìn gbogbo èyí ó tẹ ìwé kan jáde tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, Ṣé Àwa Mọ Jésù? A kò gbọ́dọ̀ fí ẹnu yẹpẹrẹ pe orúkọ Jésù, ṣùgbọ́n kaka bẹ́ẹ̀ kí á mọ Olúwa wa dáadáa kí á dàgbà sókè dáadáa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ àdúrà. Ẹ jẹ́ kí á ronú jìnlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, lẹ́hìn èyí Ọlọ́run yóò bá wa sọ̀rọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó jìnlẹ̀ dáadáa lọ́kàn wa.
Ó ń ràn wá lọ́wọ́ li jẹ́ ajẹ́rìí tó kójú òsùnwọ̀n nígbà tí á bá le kà láti orí odidi orí tàbí ẹsẹ Bíbélì láti yálà Májẹ̀mu Láìláí tàbí Títun, nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ agbára, ó sì ń fún wa ní ìmọ̀ ẹ̀mí mímọ́. Ìbùkún ni fún ọkùnrin tàbí obìnrin náà tí gbogbo èrońgbà àti ìrònú rẹ̀ kún fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Síwájú síi, àwọn ẹ̀rí àwọn onígbàgbọ́ àti ìtàn ìgbé ayé àwọn ìrànṣẹ́ Ọlọ́run lè rànwálọ́wọ́ láti mọ isẹ́ àti orúkọ Ọlọ́run dáadáa, tí yóò sì tún mú ìgbàgbọ́ wa le síi. A ó di aláyọ̀ tí a bá ń ṣe àsàrò nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédé, àwọn ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú yóò di aláyọ̀ nípaṣẹ̀ ẹ̀rí ìgbàgbọ́ wa.
Nígbà tí a bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a kò wà ní àwa nìkanmọ́, kaka bẹ́ẹ̀ a ń mọ Ọlọ́run síwájú àti síwájú síi. A le pè é tààrà nítorí pé a mọ orúkọ rẹ̀. Ó ń bá wa sọ̀rọ̀ láti inú Bíbélì, àwa sì ń dáa lóhùn nípasẹ̀ àdúrà wa. Oore-ọ̀fẹ́ ńlá ni eléyìí pé a lé bá Ẹlẹ́dàá wa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sẹ̀ àìsàn, ìsòro àti ìpọ́njú wa gbogbo, kí ó sì gbọ́ wa. Ìmọ̀ràn tirẹ̀ sàn jù tí oníwòsàn ara tàbí tí ọkàn lọ. Ó fẹ́ràn wa jù bí àwọn bàbá wa nínú ayé ṣe fẹ́ wa. Ó dárí gbogbo ẹ̀sẹ̀ wa jìn wá nípasẹ̀ ikú Jésù, Ó sì fún wa ní agbára ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú wa.
4.05.11 - Yínyin Ọlọ́run Pẹ̀lú Gbogbo Ọkàn àti Inú Wa
Njẹ́ a ń yín Ọlọ́run kí á sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ láti inú ọkàn wa wá bi? Ẹ jẹ́ kí a rántí pé Ọlọ́run alágbára yìí bàbá wa ni, Ọmọ bíbí Rẹ kan ṣoṣo ní ṣe Olùgbàlà, tí Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ Olùtùnú ayérayé àti ọkàn wa, ẹ jẹ́ kí a kún fún ọpẹ́. Dípò kí a sìn Ọlọ́run nínú ẹ̀rù àti ìwárìrì, ẹ jẹ́ kí a sìn ín gẹ́gẹ́ bí ọmọ tí ó ń yọ nínú iṣẹ́ bàbá rẹ̀ fún ìrètí ìbùkún àti àṣepé iṣẹ́ ìgbàlà Rẹ. Nítorí pé a kò ní láti kú síńu ẹ̀sẹ̀ síbẹ̀ mọ́ ṣùgbọ́n, a wà láàyè títí láí nínú Kírísítì. Nítorí náà, bí ó kò bá lé dárapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ akọrin láti kọrin, ìwọ náà lé dá orin kọ fún raà rẹ. Bí ó kò bá sì lé kọrin pẹ̀lú ètè re, ó lé kọ ọ́ nínú ọkàn rẹ. Bí ẹnikẹ́ni bá pé orúkọ Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú ìgboyà nínú àdúrà tàbí nínú orin ìyìn, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń fí ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run alágbára, inú Ọlọ́run pẹ̀lú máa ń dùn bí a bá ń yìn ín logo.
Tí a bá rí ẹnikẹ́ni tí kò mọ Ọlọ́run tàbí tí ọkàn rẹ̀ yìgbì, tàbí tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń dá a lẹ́bi àwọn ẹ̀sẹ̀ ìkọ̀kọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ níláti ṣe àmúlò ìmọ̀ràn Àpóstẹ́lì Pétérù: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ Olúwa, a ó gbà á là” (Ìṣe Àwọn Àpóstẹ́lì 2:21). A ní Oore ọ̀fẹ́ láti bá Ọlọ́run bàbá wà sọ̀rọ̀ tààrà ní orúkọ Jésù, Yí ó sì dá wa lọ́hùn. A súnmọ́ Ọlọ́run nítorí pé òun pẹ̀lú tí súnmọ́ wa. Orúkọ Ọlọ́run bàbá wa fí dá wa lójú gbogbo ìbùkún tí a pèsè sílẹ̀ fún wa ní ọ̀run. Orúkọ Jésù mú ìpìlẹ̀ ọ̀run àpáàdì nítorí pé ó ṣẹ́gun ẹ̀sẹ̀, ikú àti èsù. Ẹ̀mí Mímọ́ ń fí ògo fún Ọmọ Ọlọ́run nítorí pé ní orúkọ rẹ̀, ó tún fún wa ní ààbò, ìwá mímó, àyọ̀ àti alàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn tí ń tán ìtànsán ògo rẹ̀ sí ayé lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan rọ oore ọ̀fẹ́ kún oore ọ̀fẹ́ lé wa lórí. Tá ni ẹni náà tí kò ní fí ọpẹ́ fún Bàbá tàbí fí ìyìn fún Ọmọ tí yóò gbà àdúra pẹ̀lú agbara Ẹ̀mí Mímọ́? Fí ara rẹ sílẹ̀ fún Ẹ̀mí ìtùnú Olúwa rẹ, nígbà yìí ní ìwọ yóò mọ bí Ọlọ́run ṣe ń gbọ́ àdúrà rẹ̀. Rú ẹbọ ìyẹ̀ ní orúkọ Jésù tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà ní ojú bàbá rẹ. Dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ kí ó sì yìn ín nítorí tí ó fẹ́ ọ, ó gbà ọ́ là, ó sì tún fún ọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.
4.05.12 - Ìjẹ́rìí Ìgbàgbọ́ sí àwọn Ẹlọ̀míràn
Ẹ̀dá wo ní ó lé panumọ́ nígbà tí ọkàn rẹ̀ bá ọpẹ́ àti ìyìn? Tàbí táni ó lé fí ìrírí ìgbàlà rẹ̀ pamọ́ nígbà tí Ọlọ́run kí ẹ̀dá gbogbo ní ìgbàlà? Wíwá àwọn asáko rí kìí ṣe bí a bá fẹ́, ṣùgbọ́n Jésù Olúwa fún ra rẹ̀ pa á lásẹ fún wa láti jáde wàásù ìhìnrere fún gbogbo ènìyàn. Ìṣẹ́gun Jésù Kírísítì àti títóbi rẹ̀ gbọdọ̀ di pípolongo. Àpóstẹ́lì Pétérù gbà wá níyànjú pé: “Kí ẹ sì múra tán nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lọ́hùn tí ń bèèrè ìrètí tí ó bẹ nínú yín” (Pétérù Kìíní 3:15). Jésù pẹ̀lú kílọ̀ fún wa pé: “Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn òun li èmi ó jẹ́wọ́ pẹ̀lú níwájú Bàbá mi tí ń bẹ lí ọ̀run. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì ṣé mi níwájú ènìyàn, òun náà lí èmi ó ṣe pẹ̀lú níwájú Bàbá mi tí ń bẹ lí ọ̀run”. (Matteu 10:32-33).
Nígbà tí ó rẹ Àpóstẹ́lì Paul nítorí àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá Ọlọ́run, Olúwa fi ara hàn án ní òru láti tùú nínú, “Má bẹ̀rù, sá à máa sọ, má sì ṣe pa ẹnu rẹ mọ́: Nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dide sí ọ láti pa ọ́ lára: nítorí mọ lí ènìyàn pípọ̀ ní ìlú yìí”. (Ìṣe Àwọn Àpóstẹ́lì 18:9-10). Ó fí dá a lójú pé, “Èmi yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn Júù àti lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí pẹ̀lú tí mó ń rán ọ sí nísins1nyìí láti sí wọn lójú kí o sì mú wọn láti inú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àti láti ọwọ oagbára Sátánì wá sí ọwọ́ agbára Ọlọ́run kí wọ́n kí ó lé gbà ìdárìjín ẹ̀sẹ̀ wọn, kí wọ́n sì jẹ́ ajogún pẹ̀lú àwọn tí wẹ̀mọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi” (Ìṣe Àwọn Àpóstẹ́lì 26:17-18).
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àjínde rẹ̀, Jésù yọ̀nda agbára àṣẹ rẹ̀ àwọn ìjọ ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ tí wọ́n ti ara wọn pa mọ́lé, “Gẹ́gẹ́ bí Bàbá tí rán mi, bẹ́ẹ̀ lí èmi sì rán yí. Nígbà tí ó sì tí wí èyí tán, ó mí sí wọn, ó sì wí fúwọn pé, Ẹ gbà Ẹ̀mí Mímọ́: ẹ̀sẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jìn, a fi jìn wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dá dúró, a dá wọn dúró” (Jòhánnù 20:21-23). Tí ó bá fí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí sọ́kàn, tí o sí ronú lórí wọn, ìwọ yóò gbà okun àti ìtọ́ni sí ọ̀nà tí ó tó jùlọ láti wàásù ìhìnrere láàrín àwọn aláìgbàgbọ́ tí wọ́n ń ṣe àtakò àti àwọn asáko kèfèrí.
4.05.13 - Ṣíṣe Iṣẹ́ ní Orúkọ Olúwa
Nígbà tí Olúwa bá bá wa sọ̀rọ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a sì dá a lọ́hùn nípasẹ̀ àdúrà, ìyìn àti ìjẹ́wọ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀ níwájú àwọn ọ̀rẹ́ àti ọ̀tá pẹ̀lú, nígbà náà ni a ó ní ìrírí àṣẹ tí ń bẹ nínú orúkọ yìí. Ní orúkọ Jésù ní àwọn Ìṣe Àwọn Àpóstẹ́lì mú aláìsàn lára dá, lé ẹ̀mí èsù jáde, jí òkú dìde. Jésù fúnra rẹ̀ pàsẹ ìdákẹ́ rọ́rọ́ fún ìjì òkun nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sọ ìsù àkàrà márùn-ún di púpọ̀ fún ẹgbẹ̀rún ènìyàn. Ó fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tò ronúpìwàdà jìn, ó sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun rẹ̀. Jésù wí pé, “Bàbá mí ń ṣiṣítí di isinsìnyìí, èmí sì ń ṣiṣẹ́” (Jòhánnù 5:17). A kò sọ̀rọ̀ pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ó tún ṣiṣẹ́ láti/nínú àìlera wa gbogbo. Nígbàkúùgbà tí Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́ bá ń gbé nínú ọkàn onígbàgbó, Ọlọ́run há manu nínú irú ayé bẹ́ẹ̀. Kò tilẹ̀ kan bí ọmọ náà ti lé kéré tó níwọ̀n tí ó tí jẹ́ Bàbá fúnra rẹ̀ ní ó ń ṣe àsepé iṣẹ́ rẹ̀.
Gbogbo ìjínhìnrere òtítọ́ ni ó dá lórí ẹ̀rí ìgbé ayé àwọn onígbàgbọ́: A ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, a sì tún ń ṣe ìlòdì síi bákannáà. Ẹ̀mí Mímọ́ ń kún wa fún ìwà mímọ́ àti ó sì ń sọ́ wá di mímọ́ nítorí pé òun pẹ̀lú jẹ́ mímọ́. Ohun àkọ́kọ́ tí Jésù kọ́ wa nínú àdúrà Olúwa ni kí a fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa pẹ̀lú ẹnu àti ìwà wa. Àdúrà wa yóò jẹ́ iró bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rí wa kì yóò jẹ́ òdodo bí ayé wa bá tako agbára Ọlọ́run tí a kò sì fi ìrẹ̀lẹ̀ ótọ́ hàn.
Nítòótọ́, a ń ṣe sí ara wa, ṣùgbọ́n a ń wà ní ìròbìnújẹ́ níwájú Ẹ̀mí Mímọ́ náà. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kìí ṣe ohun pàtàkì ní ojú Ọlọ́run, Kí a sì máa rántí nígbà gbogbo pé a ń mú Ọlọ́run bínú pẹ̀lú àwọn àìṣedéédé wa gbogbo. Ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Mímọ́ ń gbé inú aronúpìwàdà ènìyàn li tù ú nínú, àti láti mú dá a lójú pé ẹ̀jẹ̀ Jésù wè ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbógbó (Jòhánnù Kìíní 1:19). Ọ̀rọ̀ Bàbá fún wa ní ìgboyà láti ní ìgbàgbọ́, kí á sì gbé ní orúkọ Ọlọ́run mẹ́talọ́kan. A ni ìrírí ìwẹ̀nùmọ́ wá nípasẹ̀ ẹ̀mí ìfàyàrán àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ rẹ̀.
Njẹ́ o tilẹ̀ mọ orúkọ Ọlọ́run, ṣé òye orúkọ rẹ̀ yé ọ bí? Njẹ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀ ń bẹ ní ahọ́n rẹ̀ bi? Ṣé Ẹ̀mí Olúwa ń gbé inú rẹ? Nígbà náà nìkan ní o lé pé orúkọ Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́ bí ó ti yẹ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti ìfẹ́. Njẹ́ kí Olúwa gbà ọ́ lọ́wọ́ pipe orúkọ rẹ̀ lásán, kí ó mú ọ dé ipò láti yìn ín pẹ̀lú ayọ̀ ní ọjọ́ rẹ gbogbo.