4.06 - ÒFIN KẸRIN: Rántí Ọjọ́ Ìsinmi láti Yà á sí Mímọ́
ÉKÍSÓDÙ 20:8-11
“Rántí ọjọ́ Ìsinmi láti yà á sí mímọ́. Ọjọ́ mẹ́ta ni ìwọ ó ṣiṣẹ́, tí ìwọ ó sì ṣe iṣẹ́ rẹ gbogbo: ṣùgbọ́n ọjọ́ keje lí ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ; nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan, ìwọ àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin àti ohun ọ̀sìn rẹ àti àlejò rẹ tí ń bẹ nínú ibodè rẹ̀; Nítorí ní ijọ́ mẹ́fà lí Olúwa dá ọ̀run òun ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Ó sì sìnmi ní ijọ́ keje; nítorí náà lí Olúwa ṣe bùsí ijọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́”.
4.06.1 - Ọjọ́ Ìsinmi fún Yínyin Ẹlẹ́dàá
Sí àwọn Júù, ọjọ́ ìsinmi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àmì májẹ̀mú tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Yíya ọjọ́ yìí sọ́tọ̀ fún ìjọ́sìn ya àwọn ènìyàn ìgbà májẹ̀mú láíláí sọ̀tọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Títí di òní yìí ni àwọn ènìyàn ìgbà májẹ̀mú láíláí ya ọjọ́ yìí tí ó kẹ́hìn ọ̀ṣẹ̀ sí mímọ́ nípa péwọ́n kìí ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ yòókù. Wọn kìí dáná bẹ́ẹ̀ni wọn kìí rin ìrìnàjò. Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò wọ aṣọ titun tí wọ́n tójú pamọ́ fún àwọn ọjọ́ àṣè. Ọjọ́ ìsìnmi wà fún ayọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe péjọ pọ̀ jọ́sìn láti kà àwọn ẹsẹ tí a yàn láti inú Torah, kí wọ́n sí láyè wọ́n nínú agbo ìyìn.
Ní ọjọ́ Olúwa, onígbàgbọ́ yẹ kí o ní àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run ju àwọn ọjọ́ yòókù lọ kí wọ́n kọjú mọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú èrò ọkàn wọ́n, nítorí pé òun ní Ẹlẹ́dàá wọn, Olùgbàlà àti Olùtùnú wọn. Ó yẹ kí á ní àṣà kíka Bíbélì, gbígbọ́ ìwáásù gidi àti dídarapọ̀ nínú àdúrà pẹ̀lú orin ìyìn tí yóò mú wa dúró, tí yóò sì tù wá lára nínú ìpòrurù ọ̀kan wa ní ìrìn àyò wà fún àwọn ọjọ́ yóòkù nínú ọ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, yálà ọmọ ènìyàn tàbí ìsinmi rẹ̀ fojú sun ọjọ́ yìí ṣùgbọ́n Olúwa fúnra rẹ̀. Nípasẹ̀ èyí, ọjọ́ ìsinmi tí di ọjọ́ Olúwa. Ó tí ya ọjọ́ yìí sọ́tọ̀ fúnra rẹ̀, ó yà á sí mímọ́, ó sì bùkún fún un. Ọjọ́ Olúwa jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ẹ̀dá rẹ̀.
Yíya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ túmọ̀ sí pé á ń yín Ẹlẹ́dàá, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé, àwọn ìràwọ̀, ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú igi gbogbo pẹ̀lú agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó dá ẹja, àwọn ẹyẹ àti gbogbo ẹranko kékèèké àti ńláńlá. Iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ parí pẹ̀lú ìṣẹ̀dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run. Nínú ìsẹ̀dá yìí, ẹ̀dá alààye kọ̀ọ̀kan jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tí á gbé kalẹ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n àti agbára ní ìlànà ọ̀tọ̀. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì tí tú díẹ̀ nínú àdìtú tí ara ènìyàn jẹ́ agbára láti ṣe ohun àti agbára ẹ̀mí rẹ. Àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run tí dára tó! Bí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ bá dára bẹ́ẹ̀, báwó ní Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ yóò tí dára tó! ọ̀rọ̀ ènìyàn kò tó láti sọ bí títóbi, ògo àti agbára rẹ̀ ṣe tó. Ó yẹ fún sínsìn àti ìyìn láti ọ̀dọ̀ gbogbo ẹ̀dá rẹ̀.
Lẹ́hìn tí Ọlọ́run parí èrèdí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀ gbogbo, ó sinmi. Àárẹ̀ kò mú láti ibi iṣẹ́ yìí, nítorí pé Alágbára kìí sàárẹ̀, kìí tòògbé bẹ́ẹ̀ni kìí sùn, dípò bẹ́ẹ̀ ó ríi pé iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo dára, inú rẹ̀ dún sí àìníye iṣẹ́ ìyanu ńlá tí ó ti ṣe àti wí pé dáradára ni wọ́n. Ó tọ́ fún wa kí á máa yin Ọlọ́run logo lójoojúmọ́ pàápàá jù lọ ní ọjọ́ Olúwa fún iṣẹ́ ìsẹ̀dá rẹ̀ tí kò láfiwé.
4.06.2 - Pàtàkì Ìsinmi ní Ọjọ́ Ìsinmi
Ní ọjọ́ ìsinmi, á ní oore ọ̀fẹ́ láti jẹ́ àlábàpín nínú ìsinmi ọ̀run tí Ọlọ́run tí pèsè sílẹ̀ fún wa. Ó fún wa ní oore ọ̀fẹ́ fún ìdákẹ́jẹ́jẹ́ àti ìjọ́sìn. Ìdákẹ́jẹ́jẹ́ lode àti nínú níwájú Olúwa yìí ni kọ́kọ́rọ́ sí àlàáfíà. Kò sí ẹni tí ó lé tàpá sí òfin yìí láì jìyà . Àwọn orílẹ̀-èdè bí Soviet Union àtijọ́ tàbí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ní apá Gúúsù pàdánù ìfọ̀kànbalẹ̀ nítorí pé wọ́n gbìyànjú láti kọ ọjọ́ Olúwa tì. Àwọn tí kò kọbiara sí ọjọ́ yìí, tí wọ́n sí ń sáre ká nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọ, kò ní òye kíkún nípa ògo iṣẹ́ ìsẹ̀dá Olúwa. Wọ́n tí ju agbára láti ṣe àsàrò nù, nítorí èyí gbogbo iṣẹ́ wọn wọ́lẹ̀ nínú ọ̀ṣẹ̀. Gbogbo ènìyàn, kódà ẹranko nílọ̀ ìsinmi, èdá alààyè kò lè tún agbára rẹ̀ ṣe láì bá kọ́kọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ níwájú Ọlọ́run. A kò gbọ́dọ̀ lòdì sí òfin Ọlọ́run tí ó wí pé kí a yà ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́. A lé ríi pé òfin yìí kò sọ pé kí á ṣiṣẹ́ fún wákàtí márùndínlógójì tàbí ogójì nínú ọ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ọjọ́ mẹ́fà fún iṣẹ́ àṣekára kí ọjọ́ keje sì jẹ́ tí Olúwa pátápátá. Bíbélì kọ̀ wà pé ayé tí kò níṣẹ́ ní ó ń fi ààyè fún iṣẹ́ ibi gbogbo iṣẹ́ ojúmọ́ ní èrè fún ọwọ ènìyàn.
Jésù gbà wá níyànjú láti dúró ṣe àsàrò lórí àwọn koríkò ìgbé àti àwọn òdòdó mìíràn, kí á wo bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Ṣé a tí ṣe àkíyèsí iye àkókò tí wọ́n ń lò kí wọ́n tó tanná, hu ewé, kí wọ́n tó so èso? Dúró kí ó dí ojú rẹ. Kọ́ láti mọ̀ nípa àwọn agbára àti òfin ẹ̀dá òhún, ìwọ yóò sì rí lẹ́hìn wọn Ẹlẹ́dàá ọlọgbọ̀n àti ìṣe rere bíi tí Bàbá rẹ̀. Jésù dábàá pé kí a ṣe àfiwé ògo òdòdó aláwọ̀ àrànbarà pẹ̀lú ògo aṣọ ńlá àwọn olówó, kí a lé mọ̀ pé a kò ṣe ọba pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin ọba logo tó àwọn òdòdó wọ̀nyí, tí wọn yóò rọ́, wọn ó sì kú. Ọmọ ènìyàn ní ó lẹ́wà jù lọ́ nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run, ojú rẹ̀ sọ díẹ̀ nípa ògo Ọlọ́run. Ìbáṣe pé a lé yí bí a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa padà, kí a sí wọ́ eré sísá kìri, Kí á wá ààyè láti ronú! Nígbà tí a bá ṣe èyí, yóò gún wa ní kẹ́ṣẹ́ títíbi ẹwà iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí yóò lé mú kí á dupe lọ́wọ́ Ọlọ́run kí á sì yìn ín, ṣùgbọ́n, ó ṣe ni láàánú pé, orísìírísìí ètò tí ó burúkú jùlọ̀ wà ní orí ẹ̀rọ móhùn-máwòrán tí ó ń fi àwòrán oníhòhò àti oníjàgídíjàgan hàn, tí Ọlọ́run sì fẹ́ láti sí ojú wa nínú òjò, ẹ̀ẹ̀rùn, ọyẹ́ àti ọ̀gìnnìtì sí ìyànu gbogbo tí ó dá tí ó sì pa mọ́.
Nígbà tí Ọlọ́run pàṣẹ kí á pá ọjọ́ ìsinmi mọ́, ó ń bèrè pé kí ọjọ́ yìí di yíyà sọ́tọ̀, kí ọmọ ènìyàn lé lòó láti kọ́ láti dúró níwájú òun. Yíyà ọjọ́ Olúwa sí mímọ́, kìí ṣe sísinmi tàbí gbígbọ́ àti kíka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan, bí kò ṣe pé kí a yípadà síi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, kí òun pẹ̀lú lé yípadà sí wa, kí ó sì kún wa pẹ̀lú ìṣerere rẹ̀. Ó jẹ́ mímọ́, ó sì fẹ́ kí àwa pẹ̀lú jẹ́ mímọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sún síwájú síi nínú ìmọ́lẹ̀ ìfẹ́ kí á sì fí ògo rẹ̀ hàn nítorí kò sí ìsọdọ̀tun láìsí ìdákẹ́ jẹ́jẹ́.
4.06.3 - Èdè-àìyedè nípa Ọjọ́ Ìsinmi
Ọjọ́ ìsinmi pa àwọn ènìyàn inú máj ẹ̀mú láìláí mọ́ sọ́tọ̀ kúrò nínú ìbọ̀rìṣà tí àwọn orílẹ̀-èdè yókù tó yí wọ́n ká ń ṣe. Títẹramọ́ tí wọ́n tẹramọ́ ọjọ́ Olúwa yìí tún pèsè wọ́n sílẹ̀ fún wíwá Kírísítì, Olùgbàlà aráyé. Síbẹ̀, ọjọ́ ìsinmi fúnra rẹ̀ kò lè yípadà, dáàbò bò tàbí sọ àwọn tí ó paá mọ́ di ọ̀tun. Gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìlágbára ìkà àti aláììpé níwájú Ọlọ́run. Kò sí òfin tí ó lé yí ẹ̀dá ọmọ ènìyàn padà, bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìsinmi kò lé dá ènìyàn sílẹ̀ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n ó lé pa ènìyàn mọ́ kúrò nínú ìgbàgbọ́ pé kò sí Ọlọ́run. Ní májẹ̀mú titun, a kò sàjọyọ̀ ọjọ́ Olúwa fún pé kí á lé gbà oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n láti yìn ín tàbí dupe lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí pé òun ni ó dá wa. Ó di bíbí nínú ènìyàn, ó tọ̀ wá nínú Krístì, ó tọ́jú wa ju bí bàbá ṣe lé tọ́jú ọmọ rẹ̀ lọ. Fún ìdí èyí, a fẹ́ ẹ a sì tún fí ọlá fún un. Pípa òfin mọ́ kò lé gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni àsírí ìjìnlẹ̀ ìgbála wa àti dídi ẹ̀dá titun. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ìdáláre nípaṣẹ̀ òfin yóò gbà ìdálẹ́bi nípaṣẹ̀ òfin. Ṣùgbọ́n bí ó bá làkàkà, tí ó mú ọwọ́ tí Jésù nà síta sí ọ, yóò tọ́ ọ sọ́nà, yóò sì tún gbà ọ́ kúrò nínú gbogbo ìdálẹ́bi.
Ní ọjọ́ keje, Ọlọ́run sinmi. Ó wo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ gbogbo, ó sì ríi pé wọn dára. Síbẹ̀, ìsinmi tí Ọlọ́run yà sí mímọ́ pin nígbà tí ènìyàn ṣe àìgbọ̀ràn tí ó sì subú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ọlọ́run dáwọ́ ìsinmi dúró láti ìgbà yìí ní ó tí ń ṣiṣẹ́ lọ́sàn án àti lóru kí ó lé ra iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí ó sọnù padà. “Ó wí pé, ìwọ fí àìṣedéédé rẹ dá mi lí agara” (Isaiah 43:24). Jésù tún fìdí èyí múlẹ̀, “Bàbá mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi sì ń ṣiṣẹ́” (Jòhánnù 5:17). Ọ̀rọ̀ wá ká Ọlọ́run lára gan ni pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú wa, ṣùgbọ́n ọpé ní fún Ọlọ́run fún ìràpadà tí ó wà fún ẹlẹ́ṣẹ̀ nípa ètùtù ẹ̀sẹ̀ tí Kírísítì ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà ọ̀dọ́ àgùntàn Ọlọ́run gbọ́ kò ní wá sí abé ìdájọ́ òfin, dípò bẹ́ẹ̀ yóò di ẹni ìdáláre pátápátá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù. Jésù kú, a sin ín kí ó tó dí ọjọ́ ìsinmi. Ó sinmi ní ọjọ́ ìsinmi Ọlọ́run ní ibojì ọkùnrin ọlọ́lá kan. Ó jínnde ní ọjọ́ kìíní ọ̀ṣẹ̀ nípadṣẹ̀ èyí Ọlọ́run pa ìlànà ọjọ́ ìsinmi mọ́. Nípaṣẹ̀ àjínnde rẹ̀, ó gbé ọjọ́ titun mìíràn dìde ní èyí tí ó sí ìbí titun ní èyí tí ó ń gbèrú nípa oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti lórí agbára Ẹ̀mí Mímọ́, kí ṣe lórí ìdájọ́ òfin.
4.06.4 - Ṣé àwọn Kírísítẹ́nì ní ẹ̀tọ́ láti sàjọyọ̀ ọjọ́ àìkú dípò Ọjọ́ Àbámẹ́ta?
Ní ọ̀ọ̀lọpọ̀ ìgbà ní àwọn Júù àti àwọn ìjọ Seventh Day Adventists tí pé àwọn Kírísítẹ́nì níjà pé wọ́n ṣe sí òfin kẹ́rin àti pé ìbínú Ọlọ́run yóò wá sórí gbogbo ọmọ ẹ̀hìn Kírísítì nítorí pé wọ́n ń pa ọjọ́ Àìkú mọ́ dípò ọjọ́ Àbámẹ́ta. Ọmọ ènìyàn mú gbogbo ìlànà ọjọ́ ìsinmi ṣe fún wa. Ó mú gbogbo òfin ṣe fún wa. Jésù kò gbé òfin titun kalẹ̀ láti yà ọjọ́, osù tàbí ọdún kán pàtó sí mímọ́. Ó gbà àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ là, ó sì yà wọ́n sí mímọ́. Ọmọ ènìyàn kò nílọ̀ láti sin Ọlọ́run ní ọjọ́ ìsinmi tàbí nígbà àjọyọ̀ kan pàtó ṣùgbọ́n, ní ojojúmọ́. Ìdí nìyí tí Jésù fi yà ẹnikọ̀ọ̀kan sí mímọ́ tí kìí ṣe ọjọ́. “Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ń ṣe lí ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ máa ṣe gbogbo wọn lí orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Bàbá nípaṣẹ̀ rẹ̀” (Kólóssè 3:17). Iṣẹ́ yọ́wù tí a bá ń ṣe lábẹ́ ìtọ́ni Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ iṣẹ́ ìsìn sí Ọlọ́run. Ọjọ́ kan kò ṣe pàtàkì jù ọjọ́ mìíràn lọ. Jésù dá wa láre nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ iyebíye, ó sọ wá dọ̀tun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ṣẹ̀dá àwọn ènìyàn ìyàsọ́tọ̀ kìí ṣe àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀. Èrèdí tí ó fi wá sáyé ni láti ṣe ohun tí ọjọ́ ìsinmi kò lé ṣe; láti da ènìyàn titun, làti yí ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó burúkú jùlọ padà sí àwọn ẹni ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ àti láti yí ọ̀kánjúà padà sí ìránsẹẹ́ rẹ̀.
Ìdí nìyí tí Kírísítẹ́nì fí mú ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ tí Jésù jínnde láti lé ṣe àjọyọ̀ májẹ̀mú titun pẹ̀lú ìṣẹ̀dá rẹ̀ titun. Ṣùgbọ́n Jésù ń fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ sinmi nítòótọ́, kí wọ́n ṣe àsàrò lórí oore ọ̀fẹ́ tí wọ́n ní láti jẹ́ ọ̀kan nínú ìṣẹ̀dá rẹ̀ titun. Kò pàsẹ fún wa kí a pa ọjọ́ Àìkú mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò níkí á má pa ọjọ́ Àbámẹ́ta mọ́. Kò fẹ́ kí àwọn ọjọ́ tàbí àjọyọ̀ kan jẹ́ ìdènà fún wa ṣùgbọ́n ó wa láti gbà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là. Àjínde Jésù ṣe ìpìlẹ̀ ayé titun pé a kò sí lábẹ òfin ìdálẹ́bi mọ́ ṣùgbọ́n lábẹ oore ọ̀fẹ́ ìgbála Olúwa wa. Èyí kò túmọ̀ sí pé Kírísítẹ́nì jẹ́ aláìlófin. Ẹ̀mí Kírísítì tí ó ń gbé mú wa tìkálára rẹ̀ jẹ́ òfin ìfẹ́, bákannáà ó fún wa ní agbára làti mú òfin yìí ṣe. Níwọ̀n bí ọjọ́ ìsinmu ti jẹ́ àmì májẹ̀mú àtijọ́ tí kò pẹ́ tí ọjọ́ ọ̀sẹ̀ sì jẹ́ àmì ìṣẹ́gun Kírísítì tí ó jẹ́ ìpìlẹ̀ májẹ̀mú titun.
Àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ tí àwọn Mùsùlùmí kò lè sinmi ní ọjọ́ ọ̀sẹ̀ tàbí ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ tàbí ọjọ́ ìsinmi. Fún ìdí èyí, wọ́n ń kọ́ra jọ pọ̀ ní ọjọ́ Ẹtì, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa tìkararẹ̀ wà pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí ó tí ṣe ìlérí, “Nígbà tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara wọn jọ lí orúkọ mi, ní bẹ̀ lí èmi o wà lí ààrin wọn” (Mattéù 18:20). Jésù kò ní lọ̀kàn láti yan ọjọ́ kan pàtọ̀ fún ìjọ́sìn, dípò èyí ó fẹ láti yà àwọn onígbàgbọ́ sí mímọ́ nígbà gbogbo àti níbi gbogbo.
4.06.5 - Sísàjọyọ Ọjọ́ Ìsinmi
Báwo ní àwọn Kírísítẹ́nì ṣe lé yà ọjọ́ Olúwa wọn sí mímọ́? Ìfẹ́ ló mú wọn kóra jọ pò ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ fún ìjọ́sìn àti Bíbélì kíkà àti láti yìn ín nínú ìkórajọpọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́. Àwọn ọmọ wa, àlejò ilé wa, alágbàásìsẹ́ wa, kódà àwọn ohun ọ̀sìn wa gbogbo gbọ́dọ̀ darapọ̀ mọ́ wa ní ọjọ́ ìsinmi láti sinmi kí wọ́n sì pín nínú ayọ̀ àjínde tí a ń rántí ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀dá nínú wa. Èrèdí ayọ̀ àwọn Krístẹ́nì jinlẹ̀ ju tí àwọn Júù lọ. Jésù wí pé, “Nnkan wọ̀nyí ní mo tí sọ fún un yín, kí ayọ̀ mi kí ó le wà nínú yín àti kí ayọ̀ yín kí ó lé kún” (Jòhánnù 15:11; 17:13). Paul pẹ̀lú kòwé rẹ̀, “Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí, ẹ máa yọ̀” (Fílíppì 4:4) “Èso tí Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàfíà…” (Galatia 5:22). Àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ń fí ìṣedéédé ẹ̀mí ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ hàn ṣùgbọ́n, wọ́n tún sàpèjúwe ẹ̀mí iṣẹ́ wà láàrin ọ̀ṣẹ̀, wọ́n ń fihàn wá bí ìgbé ayé ẹbí Kírísítẹ́nì ṣe gbọ́dọ̀ rí.
Ṣé kí a ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀? Kírísítẹ́nì jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ pé bí àwọn ènìyàn yòókù. Wọ́n ní ara tí ó lé rẹ̀. Ìdí nìyí tí wọ́n fí ní láti nara, kí wọ́n sinmi. Wọ́n jẹ́ ẹ̀dá alààyè lásán, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run nínú ẹ̀mí bákan náà. Wọ́n ń gbé nínú ara ní ayé ṣùgbọ́n wọ́n jókòó pẹ̀lú Kírísítì nínú ẹ̀mí ní ọ̀run. Wọn kò tako ọjọ́ ìsinmi ní ojú Olúwa. Ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ kìí ṣe ọjọ́ tí á fí ń san gbèsè oòrun, bí kò ṣe láti fí ògo fún Ọlọ́run Baba, kí á sì yìn ín. Ọjọ́ yìí jẹ́ tí Ọlọ́run, kò sì yẹ kí á lòó fún iṣẹ́kísẹ́ àyàfi ojúṣe tí yó yọ ẹlòmíràn kúrò nínú ewu. Òdodo wa kò dúró lórí pípa òfin mọ́ ṣùgbọ́n lórí ikú Kírísítì, Ẹni tí ó gbìn ìlànà ètùtù yìí sí ọkàn wa. Lílọ sí ìjọ́sìn ìta gbangba àti àwọn ìpàdé ẹ̀mí mìíràn jẹ́ oore ọ̀fẹ́ tí a fifún Kírísítẹ́nì nìkan. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ó jẹ́ ọjọ́ ọ̀ṣẹ nìkàn ni Kírísítẹ́nì ó máa jẹ oúnjẹ ẹ̀mí, ó yẹ kí wọ́n mí ojoojúmọ́, láìṣe bẹ́ẹ̀ ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ìrètí wọ́n yóò tutu. Ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ fún wa ní oore ọ̀fẹ́ láti kọrin nínú ìlú, kí a gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí agbo kan, kí á sì sọ èrè ọkàn wá kí á lé wà ní ìṣọ̀kan Kírísítẹ́nì. Gbogbo onígbàgbọ́ lápapò ni ó jẹ́ ara Kírísítì. Onígbàgbọ́ kọ̀ọ̀kan kọ̀ ní ohun èlòpàtàkì fún ìṣẹ̀dá titun, bí kò ṣe pé ìkórajọpọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ tí a lé rí ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ ní pàtó.
Ìbùkún ni fún àwọn tí ó ń ṣe àbẹ̀wọ̀ àwọn aláàárẹ̀, alábọ̀ ara àti àwọn aláìní ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀. Irú àwọn onígbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kò ní wo òduwọ̀n epo mú ọkọ̀ bóyá yóò tó láti rín ọgọ́rùn ún ibùṣọ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa láti jáde kúrò nínú ilé ìjọsìn wa láti wa àwọn tí wọ́n ó kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ lọ. A pè wá láti mú wọ́n wá sí ìrònúpìwàdà nínú Kírísítì, kí wọn kí ó lè dìde kúrò nínú ẹ̀gàn àti líle ọkàn wọn. Kò sí àwáwí kankan fún wa láti máa wàásù Kírísítì fún àwọn aláìgbàgbọ́. A tún pè wá sí ìtọrẹ àánú ṣíṣẹ fún olúkúlùkù ènìyàn tàbí agbo tí ó ṣe aláìní ní ọjọ́ Olúwa; ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ fún wa ní ààyè tí ó tó láti fí ọpẹ́ fún Olúwa, jẹ́wọ àìṣedede wa kí a sì gbádurá fún àwọn ọhùn tí àwọn ẹlọ̀míràn nílò. Tí Ọlọ́run bá fún wa ní ọwọ, ó yẹ kí á ló àkókò pípéye pẹ̀lú wọn, kí a kọ orin ìgbé ọkàn sòké, orin ìyìn Kírísítẹ́nì pẹ̀lú wọn. Ẹ jẹ́ kí á bèrè lọ́wọ́ Jésù bí a ṣe le pa ẹsẹ mẹ́ta àkọ́tọ́ nínú àdúrà Olúwa ó pàápàá jù lọ ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀. Bí a bá pa ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ mọ́, a ó bùkún wa. Jésù tí pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó ń wá kí a fí ẹ̀mí Kírísítì tí ó jìnnde kúrò nínú òkú ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ kún òun.
4.06.6 - Ṣiṣe Àìya Ọjọ́ Ìsinmi sí Mímọ́
Ó jẹ́ ohun tí ó burúkú jù, pé a ń da ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ ní òpín ọ̀ṣẹ̀ jú àwọn ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ yòókù lọ. Ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀, okọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ á gbà ìgboro kan. Ilé iṣọ móhùn-máworán fí àkókò péréte fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà tí àkókò wà fún àwọn eré, abanilẹ́rù, eré oníhòhò tàbí eré àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn. Ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mìíràn máa ń ṣis ilé, nínú ọgbà àti abá nígbà tí wọn ibá tí ṣe àwọn iṣn ọjọ́ yòókù. Ní ìgbà ayé májẹ́mú láíláí, bí wọ́n bá mú ẹnikan pé ó ń ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi, ìdájọ́ ikú ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Tí a bá sí wa lójú láti rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí a ń dá ní òpin ọ̀ṣẹ̀, bóyá ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀ ní ìlú kan, yóò bá ọkàn wa jẹ́ yéye tàbí kí ó yà wá ní wèrè. Kìkì ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó kún fún ìfàyàrán àti sùúrù tí ó dúró fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Njẹ́ ó tí gbàgbé ohun tí Olúwa wí nípa ọkùnrin náà tí ó bá ba ọjọ́ mímọ́ rẹ̀ jẹ́? Tí a bá ka ìwé (Éksódù 31:14-17) a ó mọ bí ó ṣe é ṣe pàtàkì fún wa tó láti dákẹ́ jẹ́ níwájú Olúwa. (Tún wo ìwé Númérì 15:32-36) láti mọ́ ìṣe pàtàkì yíya ọjọ́ Olúwa sí mímọ́). Bóyá kí á yí ìgbé ayé wa padà, kí a sọ fún àwọn ọmọ wa láti má ṣe iṣẹ́ àtiléwá wọn ní ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ: Olúwa gbìdánwò láti fí iná sun ìlú tàbí ìletò tí kò bá pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìjọsìn àti ìsinmi (Jeremiah 17:22). A kò gbọ́dọ̀ ṣe aláìka ìkìlọ̀ yí sí. Tani ó mọ̀ bóyá ogun àgbáyé àti ìdàmú ńlá ni àìkàsí bẹ́ẹ̀ yóò dá sílẹ̀? Bíbélì wí pé; “Kí á má ṣe tàn yín jẹ, a kò lè gan Ọlọ́run; nítorí ohunkóhun tí ènìyàn bá fúnrúgbìn, òun ni yóò sì ká” (Gàlátíà 6:7). Ẹnikan kò lè rú òfin Ọlọ́run kí ó múu jẹ gbé.
Bí Jésù kò bá kú lórí àgbélèbú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó sì ru èbi ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ò bá jẹ́ aláìnírètí. Ṣùgbọ́ ikú rẹ̀ kìí ṣe oore ọ̀fẹ́ fún wa láti ba ọjọ́ Olúwa jẹ́. Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́. Ìgbé ayé rẹ̀ fí ògo fún Baba. Lẹ́hìn àjínde rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní ọ̀ṣẹ̀, Jésù fi ara hàn àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ láti ṣe àjọyọ̀ májẹ̀mú titun tí ó ní pẹ̀lú wọn.
4.06.7 - Fífi Ojú Ìrò Titun Wo Òfin
Nígbà tí a ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tí kò dára láti pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ó ṣe é ṣe kí á si ìtumọ̀ fún òfin Ọlọ́run yìí. A dá Jésù lẹ́bi ikú nítorí pé ó wo aláàárẹ̀ ṣàn ní ọjọ́ ìsinmi àti nítorí tí ó sọ wí pé Ọmọ Ọlọ́run ní òun. Àwọn olórí ẹ̀sìn tìí títí dé ojú ikú, àwọn tí gbogbo ìsapá wọn fún òfin Mósè tí sọ agbára láti fẹ́ Ọlọ́run àti ènìyàn nù. Wọ́n jẹ́ olódodo nípa tí ara nípasẹ̀ àgàbàgebè, wọ́n sì kọ etí dídi sí ìpè sí ìronúpìwàdà. Nínú ìfọ́jú wọn, wọ́n ṣe ọkan wọn le, wọn kò ṣtán láti yí ọkàn wọn padà. Wọ́n kọ Ọlọ́run Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́. Wọn kò bìkítà fún aláàárẹ̀ ní ọjọ́ ìsinmi. Nítorí náà, gbogbo wíwo mó pípa òfin ọjọ́ ìsinmi mọ́ dí ti àgàbàgebè. Abájọ tí Jésù wí fún wọn pé, “Àwọn ènìyàn yìí ń fí ẹnu wọn súnmọ́ mi, wọ́n sì ń fí ètè wọn bọla fún mi; ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi. Ṣùgbọ́n, lásán ní wọ́n ń tẹríba fún un, wọ́n ń fí òfin ènìyàn kọ́ni fún ẹ̀kọ́” (Máttéù 15:8-9).
Nínú ìgbìyànjú rẹ̀ láti kọ́ wa ní ọ̀nà títọ́ láti ya ọjọ́ Olúwa sí mímọ́, Jésù kò sọ ọ̀rọ̀ nípa pé kí a ṣiṣẹ́ tàbí kí a má ṣìṣẹ́ ṣùgbọ́, ó tẹnúmọ́ ipò títọ́ tí ó yẹ kí ọkàn wa wà níwájú Ọlọ́run. Paulu pẹ̀lú sapá láti gbé ìmọ̀ wa nípa òfin tí ẹ̀mí Kírísítì sókè. Síbẹ̀ wọ́n gàn án bẹ́ẹ̀ni wọ́n sọ o lókuta fún kíkọ́ pé àwọn onígbàgbọ́ tí kìε ṣe Júù pẹ̀lú tí kúrò lábẹ́ májẹ̀mú àtìjọ. Ó kọ́ wa pé a tí kúrò nínú ègan òfin nítorí pé a tí kú sí òfin nípaṣẹ̀ ikú Kírísítì. Nítorí ìdí èyí, òfin kò ní ipá lórí wa mọ́. Ṣùgbọ́n, Ẹ̀mí Mímọ́ tí ṣe àtúntò ìfẹ́ Kírísítì sínú wa. Òfin tí ẹnu titun ti inú ọkàn wa yìí ń yà wá sí mímọ́, ó ń sọ wá jí fún ìyìn Ọlọ́run mẹ́ta lọ́kan nínú èrọ̀, ọ̀rọ̀ àti ìsdé wa gbogbo. Nítorí náà a kò rẹ̀ wá sílẹ̀ lábé òfin mọ́ ṣùgbọ́n ó ń ṣiṣẹ́ ìronúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ pẹ̀lú agbára Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó ń gbé inú wa. Ẹ jẹ́ kí á ní i lọ́kan pé Jésù yà ènìyàn sí mímọ́ kìí ṣe ọjọ́! Ní èrèdí èyí, a mọ ìyàtọ̀ ńlá tí ó wà láàárin májẹ̀mú titun àti májẹ̀mú láíláí pẹ̀lú oyé wà nípa òfin kẹrin.
4.06.8 - Ọjọ́ Ẹtì fún àwọn Mùsùlùmí
Àwọn Mùsùlùmí fí àìlóye wọn nípa ìtumọ̀ òfin kẹrin nípa yíyan ọjọ́ Ẹtì gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìjọ́sìn wọn bẹ́ẹ̀ni wọn kọ̀ pa òfin ọjọ́ ìsinmi mọ́. Mùhámádù gbé ìgbẹ́sẹ̀ kan síwájú síi nígbà tí àwọn Júù àti àwọn Kírísítẹ́nì kọ̀ ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòólì ti wọn sì kọ láti di Mùsùlùmí. Kò gba ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lú àwọn Júù tàbí ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn Kírísítẹ́nì. Nípa ìgbìyànjú rẹ̀ láti fí ìgbàgbọ́ tirẹ̀ múlẹ̀, ó kọ ìlànà májẹ̀mú láíláí àti titun nípa yíya ọjọ́ Ẹtì gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìjọ́sìn fún àwọn Mùsùlùmí. Kò sí ìfaramọ́ kankan fún ọjọ́ yìí nínú Bíbélì bẹ́ẹ̀ni kò ní ìbáṣepọ̀ kankasn pẹ̀lú ètò ìgbàlà. Kó dà, ó jáde wá láti inú ìsòdì sí Ọlọ́run àti Olùgbàlà rẹ̀. Ọjọ́ Ẹtì kò ní ẹ̀rí tàbí ìfaramọ́ kan láti inú Bíbélì.
Àwọn Mùsùlùmí máa ń padà lọ sí ẹnu iṣẹ́ wọn lẹ́hìn àdúrà ọjọ́ Ẹtì. Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tí a máa ń gbọ́ láti àwọn Mósáálásí gbogbo ní ọjọ́ yìí máa ń jẹ́ ọ̀rọ̀ òsèlú, kò yanilẹ́nu pé ìkórira àti ìjà kò jìnnà sí ọ̀dọ̀ wọn. Yíya ọjọ́ kan sí mímọ́ tàbí yíya ara ẹni sí mímọ́ sì sókùnkùn sí àwọn Mùsùlùmú. Wọ́n ka Allah sí ẹni ńlá tí èlò ìwà mímọ́ rẹ̀ sí da aláìmọ̀ fún àwọn Mùsùlùmú àfi orúkọ rẹ̀ nìkan. Èyí fí èrèdí tí ẹ̀sìn Islam fí relẹ̀ yẹ́yẹ sí ìpele májẹ̀mú láíláí nípa ti òfin yíya ọjọ́ sí mímọ́. Wọ́n kò ní òye ìgbàlà àti ẹ̀dá titun tí ó wà nínú májẹ̀mú titun.
Ṣùgbọ́n a fi ọpẹ́ fún Ẹni tí a jí dìde kúrò nínú òkú nítorí pé ó ṣìṣẹ́ ìyanu ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn ọjọ́ ọ̀ṣẹ yóòkù. Ó jí dìde kúrò nínú òkú ní ọjọ́ kìíní ọ̀ṣè, ó sì fí ìtumọ̀ titun fún ọjọ́ náà. O! ọjọ́ ọ̀ṣẹ̀ gbogbo ìbá dàbí ìtànsán oòrùn fún ọ̀ṣẹ̀ gbogbo tí ń tàn ọ̀rọ̀ ìsọjí Olúwa wa, “òfin titun kan ni mọ fí fún yin, ki ẹ̀yìn kí ó fẹ́ ọmọnikejì yín gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́ràn yín kí ẹ̀yín kí ó sì lè fẹ́ràn ọmọnìkejì yín. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fí mọ pé ọmọ ẹ̀yín mí lọ ẹ̀yìn ìṣe, nígbà tí ẹ̀yín bá ní ìfẹ́ sí ọmọnìkejì yín” (Jòhánnù 13:34-35).