4.07 - ÒFIN KAÙN-ÚN: Bọ̀wọ̀ fún Bàbá àti Ìyá rẹ́
ÉKÍSÓDÙ 20:12
“Bọ̀wọ̀ fún bàbá òun ìyá rẹ; kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fí fún ọ”
4.07.1 - Ẹ̀bùn/Oore Ọlọ́run: Ìdílé
Ìdílé jẹ́ píálì olówó iyebíye àti ọ̀kan lára apákan paradise. Ọlọ́ tí dá ènìyàn, lákọ àti làbọ, látí fí ògo àti ìfẹ́ rẹ̀ hàn, kí wọn kí ó máa rẹ, kí wọ́n sì tún gbilẹ̀. Ìdílé nígbà náà ní òpómúléró fún ayé ọmọ ènìyàn àti ìpìlẹ̀ fún gbogbo àṣà. Ó ń pèsè ààbò, ìpamọ́ àti ìṣọ̀kan, ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó lágbára jú gbogbo ẹ̀kọ́ títun lọ.
Gbogbo ẹ̀sìn ló gbà pé àwọn òbí yẹ ní fífi ọ̀wọ̀ fún. Ó jẹ́ ohun tí kò nìra fún ọmọdé láti fẹ́ràn, kí wọ́n sì tún bọ̀wọ̀ fún òbí wọn. Nígbà tí ètò ìgbé ayé pẹ̀lú ìmọ̀ tí kò ní Ọlọ́run nínú rẹ́, bèrè ipò tí a fí òbí sí, irú èrò yìí lòdì sí ètò Ọlọ́run fún ẹ̀dá rẹ̀ àti àṣà ètò ìronú ọmọ ènìyàn. Ọlọ́run ń pa ìdílé mọ́ pẹ̀lú òfin karùn-ún. Ó dára kí á fí ọpẹ́ fún Ọlọ́run fún dídá ìdílé, ìwásáyé àti okùn ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tí ó so ìdílé pọ̀.
Nínú òfin karùn-ún, Ọlọ́run pàṣẹ kí á fí ọ̀wọ̀ fún, kìí ṣe fún bàbá nìkan nítorí pé ó jẹ́ olórí ẹ̀bí àti ẹni tí ó ń pèsè fún ié ṣùgbọ́n fún ìyá tí ṣe akọni pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin, ó ń fí ògo Ọlọ́rún hàn ní ayé rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń gbé ẹrù ìdílé bákannáà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀. Kò yanilẹ́nu pé májẹ̀mú láíláí àti titun fí ẹnu kò lórí bíbọ̀wọ̀ fún àwọn ìyá gẹ́gẹ́ bí á tí ń bọ̀wọ̀ fún àwọn bàbá.
Òfin pípa ìdílé mọ́, kí á sì pọ́n ọn lé jẹ èyí tí ó dára tí ó sì tọ̀nà. Kódà ní ìjọba àwọn ẹranko, àwọn ọmọ náa ń tẹ̀lé àwọn ìyá wọn, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni akọ àti abo ẹyẹ máa ń dìjọ sàbá lórí ẹyin nígbà mìíràn. Àwọn méjèèjì yóò dìjọ tójú ara wọn. Èyí jẹ ètò àti ìlànà tí Ẹlẹ́dàá gbé kalẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀ ẹ́ lójú kì yóò lọ láì jìyà. Síbẹ̀ lónìí, á ń gbọ́ àwọn ohùn òdì tí ó ń tan àwọn ọmọ, tí ó sì tún mú ọkàn wọn yigbì, “má gbọ́rọ̀ sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu tàbí má tẹríba fún wọn. Dípò bẹ́ẹ̀ ronú fúnra rẹ, tẹ́ ara rẹ lọ́rùn, hùwà ìlòdì tàbí àkókò ọmọ ọwọ́ wá”. Ojú irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ dí fún àìgbọràn ayọ̀ inú wọn sì pòórá. Ipa tí ó ṣe kókó nínú ọkàn wọn tí bàjẹ́ láìpé ọjọ́.
4.07.2 - Ẹbọ àwọn Òbí
Bàbá àti ìyá ní oore ọ̀fẹ́ láti kópà nínú ìran tituun. Gbogbo ìṣẹ̀dá ọmọ ní ó jẹ ìyanu ńlá láàyè ara rẹ̀! Yálà a bí ọmọ náà pẹ̀lú ìfẹ́ àwọn òbí rẹ̀. Bí ó tí wù kí ó rí, bàbá àti ìyá kópa nínú ìṣẹ̀dá yìí. Ọlọ́run fí ọ̀wọ̀ fún wọn láti mú ohun ìní tí a dá mọ́ wọn fún ìran mìíràn láti ara ìyá. Fún ìdí èyí, ọmọ ènìyàn ní láti wólẹ̀ níwájú Ẹlẹ́dàá, jọ́sìn fún un, kí ó sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún ọmọ kọ̀ọ̀kan tí a bí sáyé.
Àwọn ìyá wa gbé wa sínú fún osù mẹ́sàn án, ní èyí tí ó jẹ́ 275 òru àti ọ̀sán nínú ikùn wọn. A wà ní àlàáfíì, wọ́n sì tún pèsè fún wa. A pín nínú ayọ̀, ìbínú, ìbìnújẹ́ àti ìpò rùúrù ọkàn rẹ̀. Bóyá àwọn ìyá wa tilẹ̀ gbàdúra fún wa kí wọ́n tó bí wa. Ìlànà bíbí wa ní láti mú ọ̀pọ̀ ẹ̀rù àti ìrora bá a.
Bàbá àti ìyá lè bá wa gbé fún ọdún díẹ̀. Wọ́n ń wọ bí ọwọ́ ẹsẹ̀ àti ara wa ṣe ń dàgbà, wọ́n sì ń dáhùn sí ẹ̀rín àti ìrora wa. Wọ́n tún lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá fún ìwà láàyè àti ìdàgbà sókè wa. Bí àwọn òbí wa bá ń dágbà lábẹ́ àṣẹ Jésù, ó dájú pé wọ́n ó tí àwa náà sí ọwọ́ baba tí ń bẹ ní ọ̀run, kọ́ wa ní òfin rẹ̀, wọ́n yóò sì rọ̀ wá láti ní ìgbàgbọ́ nínú Ẹlẹ́dàá àti Olùsọ́àgùntàn rere. Lọ́rọ̀ kan, wọ́n wò wá, fẹ́ wa, wọ́n tún bùkún wa jú bí a tí lérò lọ. Wọ́n ń ṣe ìtójú wa lọ́sàn án àti lóru. Wọ́n sa ipá wọn láti pèsè oúnjẹ àti aṣọ fún wa. Wọ́n fí èrò nípa ẹ̀kọ́ àti òrẹ́ wa gbà ọkàn wọn. Nígbà tí á ń sàárẹ̀ tàbí òjòjò, wọ́n ń fí ọgbọ́n òye wọ́n wò wá ní ibùsùn wa. Wọ́n ń yọ̀ pẹ̀lú wa bẹ́ẹ̀ ní wọ́n ń sọkún pẹ̀lú wa nígbà tí á ní ìpọ́njú.
4.07.3 - Àwọn Ìsòro Ìdílé
Okùn tí ó nípọn wà láàrin àwọn òbí àti àwọn ọmọ wọn tí ó ṣe okùnfà ìfẹ́ àti ìgbẹkẹ̀lé nínú ara wọn. Síbẹ̀ a kò gbé ní paradise mọ́. Kò sí ọmọ tí ó pẹ́ nínú ara rẹ̀, àwọn òbí pẹ̀lú jẹ̀bi níwájú Ọlọ́run. Nítorí nnkan ayé pẹ̀lú ìdáríjìn ara ẹni nígbàgbogbo kò sí àlàáfíà tí ó lè pẹ́ nínú ìdílé, tí kò tí sí ìdáríjìn àti sùúrù. Ìdápadà àláàfíà kò lè wáyé nínú ìdílé láìsí ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ìtọrọ ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. Ìbùkún ni fún àwọn ọmọ tí á tọ pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìdáríjìn láti ọwọ́ àwọn òbí wọn.
Kìí ṣe iṣẹ́ àwọn òbí nìkan láti tọ́ àwọn ọmọ ni ọ̀nà ìgbàgbọ́ níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ pàṣẹ pé kí gbogbo ọmọdé wá sọ́dọ̀ òun láti gbà ìbùkún. Àwọn òbí nílò láti sọ ìwúlò àti iṣe pàtàkì Jésù fún àwọn ọmọ wọn, kó wọn láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n mọ pàtàkì àwọn ìlérí rẹ̀ gbogbo. Bàbá àti ìyá ní iṣẹ́ kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ṣe, ṣùgbọ́n kò gbọ́dọ̀ fí dandan tí ìgbàgbọ́ tí wọn lè àwọn ọmọ wọn lórí tàbí fí dandan mú wọn láti gbàgbọ́. Ọmọ kọ̀ọ̀kan ní láti yàn bóyá láti gbà Ọlọ́run gbọ́ tàbí ìdàkejì. Síbẹ̀síbẹ̀, ó dára fún àwọn ọmọ láti mọ́ pé ìbùkún àwọn òbí wọn wà fún ìrandíran.
Àwọn òbí kò gbọ́dọ̀ kẹ́ àwọn ọmọ wọn rà tàbí tọ́ wọn láti ya ọ̀lẹ. Wọ́n kò gbọ́dọ̀ rán wọn láti ṣe ohun tí ó nira fún ọjọ́ orí wọn. ó dára láti fún ọmọ ní àkókò tí ó tó láti ṣe ìsṣe ọmọdé wọn! Ilé ẹ̀kọ́ lílọ tàbí iṣẹ́ kíkọ́ ṣe pàtàkì ṣùgbọ́n, kò ṣe kókó jùlọ fún títọ́ ọmọ. Ó ṣe pàtàkì kí á gbìn ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìbẹ̀rù Ẹlẹ́dàá sínú wọ́n láti fún wọn ní ẹ̀rí ọkàn, kọ́ wọn ní ìpọ́nra ẹni lé, òtítọ́, ìjáfáfá àti ìwà mímọ́. Ó ṣe pàtàkì fún àwọn òbí láti máa ní àkókò fún tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àti láti fetí sílẹ̀ sí ìbèèrè àti ìsòro wọn. Lékè ohun gbogbo, ó ṣe pàtàkì fún òbí láti gbàdúrà láìdáké fún àwọn ọmọ wọn láti dí àtúnbí, kí wọ́n sì gbé ìgbé ayé wọn nínú/pẹ̀lú Jésù.
Àwọn ọmọ máa ń yájú tàbí gbójú oro sí àwọn òbí wọ́n bí wọ́n bá tí ń bàlágà, tí wọ́n sì ń di ọ̀dó. Irú ìdàgbà sí òmìnira yìí ń ìpèlè tí ẹni tí ó ti tójú bọ́, a kò sí gbọ́dọ̀ ta ko èyí. Bí òbí bá tí jọ̀wọ́ àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ fún Ọlọ́run mẹ́talọ́kan tẹ́lẹ̀, wọ́n a tọ wọ́n lẹ́hìn pẹ̀lú sùúrù ni àwọn àkókò ọdún ìjàyà wọ̀nyí láìsí pé á ń ṣọ́ wọn káàkiri. Àwọn ògo wẹẹrẹ pẹ̀lú níláti yọ̀nda ara wọ́n li ka àwọn ìwé akọ́nilẹ́kọ̀ọ́, ní ọ̀rẹ́ òtítọ́, yíya àwọn ètò tí ó dára lórí móhùn-máwọ̀rán, darapọ̀ mọ́ àwọn ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Kírísítẹ́nì níbi tí wọ́n tí ń kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jìnlẹ̀. Fífi ipá mú àwọn ògo wẹẹrẹ láti gbé ìgbé ayé àtijọ́ yóò fa ìsọ̀tẹ̀, líle ọ̀kan àti títí ìlẹ̀kùn ọkàn wọn pátápátá.
Gẹ́gẹ́ bí òbí a níláti máa rántí ìkìlọ̀ Jésù, “Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó yá fún un kí a so ọlọ ńlá mọ́ on lí ọrùn, kí á rìí sínú ibú omi òkun” (Máttéù 18:6). Mímú ènìyàn kọsẹ̀ kò túmọ̀ sí ìfìhónúhàn tàbí ìbínú ṣùgbọ́n sísi wọ́n lọ́nà láti purọ́, jalẹ̀ tàbí pé kí á gbà wọ́n láàyè láti ṣe ohun tí kò dára láì sọ ewu tí ó wà níbẹ̀ fún wọn. ìtọ́ sọ́nà pipe wá láti mú ìbèrù àti ìfẹ́ Olúwa nìkan.
Ní ayé olóye wíwò ìmọ̀ sáyẹ́nsì ti wa yìí, àwọn òbí lè dábí ẹni tí kò dákanmọ̀ sí àwọn ọmọ wọn. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà pàápàá ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń dàgbà lọ́wọ́, bàbá tàbí ìyá lè má lè kọ tàbí ka ìwé. Èyí kò fún irú ọmọ àwọn òbí bẹ́ẹ̀ tí ó ka ìwé láàyè láti gbéraga sí wọn tàbí ṣe ẹlẹ́yà wọn. Ìrú ìwà báyìí kìí ṣe àìnítẹ́ríbà nìkan ṣùgbọ́n òpè àti àgọ̀. Oore ọ̀fẹ́ mọ̀-ón-kọ, mọ̀-ón-kà kò fí ènìyàn hàn bí ọlọgbọ́n tàbí ènìyàn pàtàkì. Ìmọ̀ ìwé gígà kò bùkún ìwà rere tàbí ìwà mímọ́ ọmọ ìlé ìwé. Àṣẹ òbí lórí ọmọ kò dúró lórí ọ̀pọ̀ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí á gbà tàbí iye owo tí á kó jọ. Àṣẹ wọ́n ní ìpìlẹ̀ lórí ìfẹ́ Ọlọ́run àti bí wọ́n bá ṣe pẹ̀ tó nípò àdúrà fún àwọn ọmọ wọn níwájú ìtẹ́ oore ọ̀fẹ́. Ìpò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bàbá tí gbìn ìfẹ́ aláàánú sí ọkàn àwọn òbí. Ìrúbọ Kírísítì tí ṣẹ̀dá iṣẹ́ àti ẹbọ àláìlẹ́gbẹ́ sínú àwọn òbí àti àwọn ọmọ fún ara wọn.
4.07.4 - Mímú Òfin Karùn-ún Ṣe
Báwo ní àwọn ọmọ ṣe lè fí ọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn? Ẹ̀rí ọkàn wa ń rán wa létí láti fẹ́ wọn, kí á sì fí ọ̀wọ̀ fún wọn nítorí pé àwọn ni wọ́n ṣe iyebíye júlọ tí a mọ̀ tàbí ní ní ayé. Eléyìí ní nínú ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbọ́ràn, ìfara ẹni jìn àti kí á máa fí ààyè gba èrò tí ó ní kọ́lọ́fín nínú. Ọmọ kò ggbọ́dọ̀ na ìyá tàbí bàbá rẹ̀ bóyá àmọ̀ ọ́ mọ̀ ṣe tàbí nípa èèsì. Ọmọ kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ àfójúsùn ìdílé ṣùgbọ́n Olúwa nìkan. Jésù kọ fún wa ní kọ́kọ́rọ́ sí ìgbé ayé ìdílé tí ó wuyì nígbà tí ó wí pé, “Ọmọ ènìyàn kò wá kí a ṣe ìránsẹ́ fún un, bí kò ṣe láti ṣe ìránsẹ́ fún ni, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” (Máttéù 20:28). Ọmọ Ọlọ́run gbà àwọn òbí àti àwọn ọmọ níyànjú láti kíyèsára láti pa ìlànà yìí mọ́ ní ìgbé ayé ìdílé.
Njẹ́ ojúse ọmọ sí òbí parí nígbà tí ọmọ bá tí ní ìdílé tirẹ̀? Rárá o! Nígbà tí àwọn òbí bá di ogbó, tí ọpọlọ àti agbára wọn jóbà, wọn nílọ̀ àánú àti ìkẹ́ jù tí àtẹ̀hìn wa lọ. Ọmọ ọkùnrin àti ọmọ obìnrin lè fí àwọn àkókò kan jìn àwọn òbí wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú tí ṣe irú ìfaradà bẹ́ẹ̀ fún wọn nígbà tí àwọn pẹ̀lú wà ní ìkókó. Kò sí ilé ìtọ́jú arúgbó tí ó lè dípò ìfarajìn ọmọ sí òbí ní irú àkókò yìí nípa ẹ̀bùn tí ó jọjú, owó ìlàkàkà wọn sí arúgbó.
Òfin karùn-ún ní àkọ́kọ́ tí ó sọ ìlérí ní pàtó lẹ́hìn tí ó tí sọ májẹ̀mú Ọlọ́run bí i tí Baba fún wa. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣe ìtọ́jú àwọn òbí rẹ̀ ní ìlérí ẹ̀mí gígùn ní ayé láìsí kíkùn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún. Ìgbàkúùgbà tí á bá pa ògo òbí mọ́ tí òbí àti àwọn ọmọ ń gbé ní ọ̀nà Ọlọ́run, wọn yóò ní ìrírí ìmúṣẹ ìlérí yìí papọ̀.
Ọlọ́run kọ̀ ó fún wa pé kí á ṣe ẹlẹ́yà àwọn òbí wa àti àwọn tí wọ́n wà ní ipò àṣẹ. Èyí tíí ṣe èébú, ẹjọ́ èké, àgbàbàgebè àti ẹ̀tàn. Ṣé Jésù kò sọ wí pé, “Níwọ̀n bí ẹ̀yìn tí ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí tí ó kéré jùlọ ẹ̀yin tí ṣe é fún mi” (Máttéù 25:40).Ṣé ó rántí ìtàn búburú tí Absalom tí ó dìtẹ̀ mọ́ bàbá rẹ̀, Dáfídi? Ó parí pẹ̀lú ikú àwọn ọlọ̀tẹ̀ (Sámúẹ́lì kìíní 15:1-12; 18:1-18).
A kà nínú ìwé (Eksodu 21:15-17) “Ẹni tí ó bá sì lu bàbá tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pà á… Ẹni tí ó bá sì bú bàbá tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pá á” (Ìwé Òwe 20:20) sọ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bú bàbá rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ fitílà rẹ̀ ni a ó pa nínú òkùnkùn bìrí” (Deuteronomu 21:18-21) sọ wí pé, “Bí ọkùnrin kan bá ni ọmọkùnrin kan tí ó ṣe agídi àti aláìgbọ́ràn, tí kò gba ohùn bàbá rẹ̀ gbọ́ tàbí ohùn ìyá rẹ̀ àti tí àwọ ná an, tí kò sì fẹ́ gba tí wọn gbọ́ … kí gbogbo àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ kí ó so ó ni òkúta pa …” “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìlòdí àti ọ̀tẹ̀ sí àwọn òbí rẹ̀ láì ronúpìwàdà du sí gbogbo ènìyàn. Àlàáfíì ìlú dúró lórí ìfẹ́ àti ìgbọ́ràn àwọn ọmọ ní ayé ijọ́hun àti nísinsìnyí!
Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ketekete, kìí ṣe fún àwọn ọmọ nìkan ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún àwọn òbí pẹ̀lú. Àwọn ọmọ kìí ṣe ohun ìṣeré fún àgbàlagbà níwọ̀n ìgbà tí ó ṣe pé Ọlọ́run fún wọn tọ ní. Níhìn ín ìlérí Jésù wá sí ìmúṣẹ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀, “Níwọ̀n bí ẹ̀yin tí ṣe é fún ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí tí ó kéré jùlọ ẹ̀yin tí ṣe é fún mi” (Máttéù 25:40). Apostẹ́lì Paulù pẹ̀lú kìlọ̀ fún wa nípa mímú àwọn ọmọ binú àti dí elẹrù pa wọ́n (Éfésù 6:4; Kólóssè 3:21). Kò yẹ kí òbí ní ojú àánú jù tàbí kí wọ́n jẹ́ aláìbìkítà pẹ̀lú. Wọ́n kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìkà tàbí alagídí ènìyàn. Wọ́n níláti mọ́ pé àwọn ọmọ ń hù ìwà tí wọ́n jogún lára wọn. Síbẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá àti àìlere kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí á ní ìtẹ́lọ́rùn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn ṣùgbọ́n èyí yẹ kí ó sọ òbí di onírẹ̀lẹ̀. Ìrẹ̀lẹ̀ yìí ń mú ọkan tutu/pẹlẹ́ tí yóò mú àwọn ọmọ wọn hùwà bí ó ti tọ́.Nítorí ìdí èyí, òbí àti àwọn ọmọ nílọ̀ láti gbàdúrà sí Jésù fún ọkàn ìrònúpìwàdà àti ìṣọdimímọ́.
4.07.5 - Àwọn tí a yí lọ́kan padà láti inú ẹ̀sìn Islámúù àti àwọn òbí wọn
Ìdí kan ṣoṣo péré ní ó wà fún àwọn ọmọ láti má gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu; bí wọ́n bá ní kí wọ́n hùwà lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Bíbélì sọ ọ́ ketekete pé, “Àwa kò gbọ́dọ̀ máa gbọ́ tí Ọlọ́run jù tí ènìyàn lọ” (Ìṣe Àwọn Àpóstẹ́lì 5:29). Lónìí ní ayé àwọn Mùsùlùmí àti tí àwọn Júù, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ní kò tẹ̀lé ìgbàgbọ́ àwọn bàbá wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣe alábàápàdé Jésù wọ́n sì tí gbà á ní Olúwa wọn. Ní èyí tí ó fá ìgbọ́kàn sókè tí ó roni lára nítorí pé wọn tí ni ìrírí ìyípadà ẹ̀mí àti ara, nítorí tí a da ìfẹ́ Ọlọ́run sínú ọkàn wọn nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Ó mú kí wọ́n fẹ́tàn òbí wọn jù tí àtẹ̀hìnwá lọ. Wọ́n nílò ìmọ̀ láti mú kí wọ́n tẹramọ́ iṣẹ́ rere wọn yàtọ̀ sí kí wọ́n kàn máa sọ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Sùúrù jẹ́ ìwà/iṣẹ́ rere àti pé àwọn ọmọ nílò láti gbàdúrà gan fún àwọn òbí wọ́n tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, kí àwọn pẹ̀lú lè yípadà pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́. Kí wọ́n gbìyànjú láti bẹ̀ wọ́n wò lóòrékóòrèè, nítorí òbí wa ní ó fẹ́ràn wa jùlọ ní gbogbo ayé.
Ṣùgbọ́n bí àwọn òbí bá fí gbogbo agbára tako Ẹ̀mí Jésù, tí wọ́n sí fí agbára mú àwọn ọmọ wọn láti ṣẹ́ Olùgbàlà wọn nípa gbígbìyànjù láti pa wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ àwọn Mùsùlùmí tí wọ́n ń pè ni Ṣẹ̀ríà, àwọn ọmọ ní láti yapa. À ní láti bá ẹ̀mí àtakò sí Kírísítẹ́ní nínú irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ wí kí á sì kọ̀ ọ́. Ṣùgbọ́n, á gbọ́dọ̀ fí ọ̀wọ̀ fún òbí, kí á sì fẹ́ràn wọn dénú nígbà gbogbo. Síbẹ̀ ọ̀rọ̀ Jésù tọ́ wa sọ́nà, “Ẹni tí ó bá fẹ́ bàbá tàbí ìyá jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi” (Máttéù 10:37). Bí òbí bá jẹ́ aláìmọ́ tàbí ìkà sí àwọn ọmọ wọn nítorí ẹ̀sìn, a jẹ́ pé inú ẹ̀dùn, àṣà ìṣàkóṣo tàbí àìlèdádúró nípa ìsúná jẹ́ àwọn ohun tí á lè ló láti yìí ìpinnu àwọn ọmọ padà. Ìdí nìyí tí Jésù fi pa wa laṣẹ láti yẹra pátápátá fún gbogbo ẹbí tí ó lòdì sí ìhìnrere Jésù kí wọ́n má ba à mú wa kúrò lójú ọ̀nà ìgbàgbọ́. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, á ní láti lọ pátápátá kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wa fún ìgbà díẹ̀ kí á lè ráyè jọ̀wọ́ ara wa pátápátá fún Jésù. Nígbà tí èyí bá sẹlẹ̀, ó máa ń dun àwọn òbí àti àwọn ọmọ pẹ̀lú, síbẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run ga jù ìmọ̀ lára tí a ní fún àwọn ẹni ọkàn wa nínú ayé.
A pẹ́ onígbàgbọ́ nínú ìjọ láti fí ara wọn jìn fún ríran àwọn tí a yí lọ́kan padà tí wọ́n ṣe aláìní lọ́wọ́ ní kánkán àti kí wọ́n yọ̀nda ara wọn gẹ́gẹ́ bíi bùrọ̀dá, àntí, ìyá tàbí bàbá fún wọn. Elẹ́yìí lé jẹ́ mọ iṣẹ́ kíkọ́ tàbí ìwé kíkà, ó sì lè jẹ mọ́ ìgbéyàwó nígbà tó bá yá. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ awọn òbí kìí tí lópín, kódà bí ìwà ọmọ tilẹ̀ burú, ìfẹ́ ìjọ sí àwọn tí á ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kan padà kò gbọ́dọ̀ lọ́pín. Ìfẹ́ Kírísítì àti sùúrù rẹ̀ ni òduwọ̀n fún onígbàgbọ́ tí ó bá gbà àwọn tí a ṣẹṣẹ yí lọ́kan padà tọ́.
4.07.6 - Ìkádìí
Ìfẹ́ nínú ìdílé gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ tàbí àwòjíjìí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run ayérayé ní Bàbá wa, ó sì pè wá láti darapọ̀ mọ́ ẹbí rẹ̀ títí láí nínú Jésù Kírísítì. Ó wẹ̀ wá pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ọmọ rẹ̀ láti mú wa wà ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú ara rẹ̀, kí ó sì sọ wá jí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Bí á bá pàdánù àwọn òbí wa nínú ìjàmbá tàbí ìṣẹ́ aburú kan, kí a má ṣe bọkàn jẹ́ ṣùgbọ́n kí a jẹ́wọ́ pẹ̀lú Dáfídì pé, “Nígbà tí bàbá àti ìyá mi kọ̀ mí sílẹ̀, nígbà náà ni Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mi” (Orin Dáfídì 27:10). Gbogbo ìfẹ́ ènìyàn ní ó lópín, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbà wá pẹ̀lú ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ rẹ̀, ó sì gbà wá mọ́ra. Ìtàn ọmọ onínàákúnàá fi ìgbà padà aṣáko hàn wá, bí Bàbá ṣe rọ èyí agbéraga àti èyí olùfọkànsìn láti láàánú àti ìfẹ́ fún àwọn tí a gbàlà. Bàbá yìí fẹ́ràn àwọn méjéèjì, ó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ fà wọ́n mọ́ ara wọn. Ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Bàbá nìkan ní ó kù gẹ́gẹ́ bí orison àlàáfíà àti ìrọra ní ayé wa. Nígbà mìíràn Ọlọ́run fún wa ní oore ọ̀fẹ́ láti gbé ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́ ní ayé. Nítorí ìdí èyí, á níláti dúpẹ́ lọ́wọ́ Bàbá wa tí ń bẹ lọ́run fún ìdílé wa ní ayé àti fún pipe wá láti jẹ́ ọ̀kan lára ẹbí rẹ̀ tí ẹ̀mí.