4.03 - ÒFIN KÌÍNÍ: Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú ù Mí
EKÍSÓDÙ 20:3
“Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi”
4.03.1 - Ìbọ̀rìsà Lóde Òní
Tí a bá ń gbé ní àwọn ìlú tí ó kún fún ilé-ìṣẹ́, agbára kaka ní a fí lè rí àwọn tí ó ń bọ̀rìsà, bóyá igi, okuta tàbí góòlù,síbẹ̀ ní Asia àti Áfíríkà, ó di dandan kí a ṣalábápàdé oríṣìíríṣìí òrísà pèlú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ó ń bọ wọ́n ní tòótọ́. Nínú Magasíìnì ilé-ìṣẹ́ ọkọ òfurufú kan tí ó jẹ́ tí ilé India ní wọn yá àwòrán òrìsà Durga, òrìsà ogun pẹ̀lú owo rẹ̀ méfẹ́ẹ̀fà tí ó fí ń pa ẹnikẹ́ni tí ó bá fín in ní ọ̀ràn. Egungun agbárí ènìyàn sì fọ́nká yí Durg ká. Agbára Durga pọ̀ dé ibi pé ẹnikẹ́ni tí ó bá sún mọ ọn ní iná tí ó ń jade lẹ́nu rẹ̀ yóò jó.Ó sì máa ń rẹ̀rín nígbà tí ó bá ń pa àwọn ọ̀tà rẹ̀ nípakúpa.
A tún lè rí àwòrán eerín tí wọ́n gbẹ́ ní India èyí tí ó dúró fún òrìsà Ganahati.Láti ìgbà dé ìgbà ní àwọn ẹlẹ́sìn Hindu sì máa ń fí òdòdó olóórùn dídùn sí iwájú wọn. Ní àkókò àsè pàtàkì, wọ́n a fí ìdí òdòdó ṣe eerin oníke tíí ó lè ga tó pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan tàbí méjì lọ́sọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò wá tẹ̀lẹ́ òrìsà yìí wọn ó fí sọ wọ́n sínú odò tàbí òkun pẹ̀lú èròńgbà pé, ìṣẹ́ ẹja pípa wọn yóò dára àti pé agbègbè wọ́n yóò bó lọ́wọ́ omíyalé tí ó máa ń ṣelẹ lọ́dọọdún.
Ní àkókò àsè pàtàkì, egbeegbérún màálú ní wọ́n yóò kó wọ inú tẹ́mpílì tí wọ́n yóò sì fí omi tí wọ́n tí yà sọ́tọ̀ fún wọ́n láti mú kí wọn wà ní àlàáfíà. Wọn yóò wá kùn ìwo wọn ní àwọ̀ yẹ̀ẹ̀pẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àmì ìyàsímímọ́. Tí a bá lọ sí àfonífojì Ladakh níwájú òkè Himrkyan tàbí tí a rìnrìnàjò lọ sí orílẹ̀ èdè àwọn ẹlẹ́sìn Budi, a ó rí èèrè gọ́ọ̀lù ńlá tí Buddha tí àwọn ènìyàn ń dọ̀bálẹ̀ níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ifiraẹnijì tòótọ́. Ìdá kan nínú mẹ́ta àwọn ènìyàn ayé ló sì ń bọ̀rìsà.Òdì sí òfin àkókó àwọn àbọ̀rìsà yìí gbàgbọ́ nínú agbára àwọn òrìsà yìí àti ìsọaradiààyè lẹ́yìn ikú (Àkúdàáyá). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olùgbé Áfíríkà ti Indonesia ni ó sì tún wà nínú ìdè irú àwọn àsà báyìí. Àwọn mìíràn ń sìn àwọn baba ńlá wọn tí ó tí kú. Ṣùgbọ́n tí wọn bá lè ní ìrírí agbára Jésù, ó di dandan kí á gbà wọ́n lọ́wọ́ ẹ̀rù ẹ̀mí àìmọ́, ìbọ̀rìsà àti àfọse. Wọn kò ní nílọ̀ agbára idán mọ́ tàbí ilẹ̀kẹ̀ dúdú, wọ́n ó sì ko àwọn gbogbo ọlọ́run òkú yìí sílẹ̀ nítorí pé a óò dáàbọ̀ bò wọ́n kúrò nínú gbogbo ipá èmí òkùnkùn.
Baba ọ̀run ń gbà wá lọ́wọ́ onírúurú ìbẹ̀rù àti kúrò nínú ìjẹgàba Jínnù, ó sì tú wa sílẹ̀ pátápátá kúrò nínú ipá ẹ̀mí àti agbára ọso. Èjẹ̀ Jésù ọmọ Ọlọ́run ní ààbò tó dájú lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀mí àìmọ́. Ohunkóhun tí wọ́n bá tí sọ tàbí kọ gẹ́gẹ́ bí ègún ní orúkọ agbára òkùnkùn lòdì sí àwọn tó ń sìn Jésù Olúwa wa ní tòótọ́ ní yóò di asán nípasẹ̀ orúkọ Olúwa wa. Odi agbára tó dájú ní fún àwọn tó gbà á gbọ́.
4.03.2 - Àwọn Òrìsà Ìgbàlódé
Àwọn ìlànà ìbọ̀rìsà mìíràn tí wọ àwọn orílẹ̀-èdè tí ọrọ̀ ajẹ́ wọn dára lára lónìí, níbi tí àwọn òrìsà wọ́n tí fí wọn nǹkan ìgbàlódé bíi: ọkọ̀, tẹlifísàn àt afẹfẹyẹ̀yẹ̀ rọ́pò àwọn èère òrìsà, Ènìyàn wá fí ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ìmò ẹ̀rọ ìgbàlọ́dé jù Ọlọ́run alààyè lọ. wọ́n a wọnú ọkọ̀ wọn wọ́n á sì máa jáyé káàkiri lórí ọ̀nà tí ó ń dan gbininrin, Ọkọ̀ wá tí di òrìsà fún àwọn ènìyàn òdé òní. Wọ́n tí fí gbogbo ara wọn jì fún ìgbádùn tí ó rọ̀ mọ́ elẹ́yìí. Nígbà tí àwọn ọmọ Isírẹ́lì ń jó yí ẹgbọ̀rọ̀ màálù ka ní ayé àtijọ́, ọ̀làjú ìgbàlódé ń gbósùbà fún oríṣìíríṣìí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ìgbàlódé. Àwọn tó ní wọ́n ń pa owó mọ́, wọ́n sì ń fí ara wọn jì fún ún; wọ́n á fọ, wọ́n tún lè kùn ún. Wọ́n a sì tẹ́tí gbọ́ ohùn rẹ jù bí wọn tí ń tẹ́tí sí àwọn tí ó yí wọn ká lọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó àti àkókò tí wọn kò lè ná fún àwọn aláìní ni wọn ń ná lórí àwọn ọkọ̀ yìí. Njẹ́ ènìyàn tí di ẹrú sí ìmọ̀-ẹ̀rọ ìgbàlódé? Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ní ó ń rọ́ lọ, pápá ìseré láti wò oríṣìíríṣìí eré ìdárayá ṣùgbọ́n dìẹ̀ ní ó ráyè fún ìsìn nní ilé Ọlọ́run.
Jésù kìlọ̀ fún a gidigidi nípa ìfẹ́ owó.Ó sọ wí pé “Ènìkan kò lè sìn Ọlórun àti owó, yóò fẹ́ ọ̀kan, yóò sì kọríra èkejì tàbí kí ó kọ Ọlọ́run, kí ó sì wá owó”.“Ìfẹ́ owó ní gbọ̀ǹgbò ohun ibi gbogbo” Àfojúsùn kan náà ni àwọn olówó tí a mọ̀ sí Sosálísíìmù àti Kapitálísíìmù ni.Nígbà tí àwọn Kapitálísíìmù jẹ́ olówó, àwọn Sosálísíìmù á lò ọ̀nà èrú àti ọ̀nà ipá láti fí kó ọrọ̀ jọ.Àwọn ènìyàn sì ń jó yí ẹgbọ̀rọ̀ màálù ká lọ́nìí. Ẹ máse jẹ́ kí á tàn yín je, nítorí a kò lè tàn Ọlọ́run jẹ.Kò sí ẹni tí ó lè sìn Ọlọ́run àti owó. Bí ó tílẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò lówó, síbẹ̀ ó ní ìtẹ́lọ́rùn. Ó sì kílọ̀ gidigidi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ọrọ̀, “Àwọn tí ó fẹ́ láti ni owó súbú sínú ìdáńwò àti ìkẹkùn” (Timitiu Kínní 6:9; Matiu 6: 24; 19:24).
Síbẹ̀ òrìsà kan tí gbilẹ̀ tí ó sì ń ṣe àkósó nínú àṣà àti ẹ̀sìn ní ìgbéraga wa. Gbogbo ènìyàn ní ó lè ró pé òun ní ó dára jù, tí ó lẹ́wà tàbí tí ó ṣe pàtàkì jù. Bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ò tílẹ̀ sọ ọ́ síbẹ̀, wọn fẹ́ ẹ. Gbogbo ènìyàn ní wọ́n sì máa ń ká ara sí ènìyàn pàtàkì lágbáyé. Ní àkókò kan, wọn béèrè lọ́wọ́ ọmọ ọdún mẹ́ta kan ohun tí ó fẹ́ dá lójọ́ iwájú, ó sì dáhùn wí pé òun fẹ́ di “èèrè”. Wọ́n wá béèrè pé kíni ìdí?Ó sọ pé “Kí gbogbo ènìyàn bá lè máa wò mí”.Igbéraga àti ìmọ̀taraẹniníkan wà nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn.Èyí sì jẹ òdìkejì ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Kírísítì.Jésù sọ wí pé:
4.03.3 - Sísẹ́gun Ìbọ̀rìsà
A gbọ́dọ̀ lòdì sí sìnsin àwọn Ọlọ́run kéékèèkéé yàtò sí Ọlọ́run alààyè gẹ́gẹ́ bí òfin àkọ́kọ̀ Ọlọ́run kan ní ó wà. Gbogbo àwọn ohun ayé yìí sì wà fún ìgbà dìẹ̀, Ọlọ́run níkan ní ó wà títí. Òun ní ó dá wa, gbogbo ògo, ọlá sì jẹ́ tirẹ̀. Òun ní ààrin gbùngbùn gbogbo àgbáyé.Ojojúmọ́ ní a gbọ́dọ̀ máa wó ìmọ̀taraẹni-nìkan wa palẹ̀ títí tí á óò fí ronúpìwádà tí a óò sí sìn Ọlọ́run pẹ̀lú ayọ̀. A gbọ́dọ̀ fí ara wa sí abẹ́ ìkáwọ́ Ọlọ́run. Owo ní ilé ìpawómọ́, àlàáfíà tàbí ẹ̀bùn wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ ayé wa.
Ábúràhàmù fẹ́ràn Ísákì jọ̀jọ̀, arólé àti ọmọ bíbí rẹ̀ tí ó tí ń retí.Ọmọ yìí sì dàbí ẹni pé ó jẹ́ ẹ́ lógún jù Ọlọ́run lọ. Ọlọ́run wá dán ìránsẹ́ rẹ̀ wò, Ó pàsẹ fún un láti fí ọmọ rẹ̀ rúbọ̀ sísun sí Òun. Ábúráhàmù sì setán láti ṣe èyí tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe é ṣe láti fí ọmọ rẹ̀ kansoso rúbọ̀ láti fí ògo fún Ọlọ́run nìkan. Síbẹ, Ọlọ́run kò gbà Ábúráhàmù láyè láti fí ọmọ ìlérí rẹ̀ yìí rúbọ̀ bíkòse àgbò dípò rẹ̀. Ní ipò ìrukóse irú yìí, a ṣe Ọlọ́run logo nígbà tí ó ku díẹ̀ kí Ábúráhámù pínyà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀. Ó fihàn pé òun fẹ́ran Ọlọ́run jù ọmọ rẹ̀ lọ.
Agbọ́dọ máa yẹ ara wa wò nígbagbogbo bóyá àwọn òrìsa kékeré tàbí ńlá kan wà láàárin àwa àti Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ ìwé, ìyùn, àwòrán, ìrántí, iṣẹ́, ìwà, owó, ilé àt bẹ́ẹ bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, àwọn ènìyàn lè gbà ọkàn wa.
Ìdánwò ìbọ̀rìsà tún farahàn nínúú ènìyan tí ó ń bá àwọn adarí wọn jẹ́. Nàpólíònì, Ataterki, Hitiler, Nsser, Khomeini àti àwọn mìíràn mú gbogbo àwọn ènìyàn síbẹ̀, gbogbo ìwé ati ìrántí wọn ni a jó níná, tí a sì bàjẹ́ lẹ́yìn ikú wọn. Wolì Jeremiah kilo fún àwọn ènìyan nípa fífẹ́ láfẹ́jù tàbí gbígbọ́kanlé ènìyan fún ìrànlówọ́ “Ègbé ni fún ẹni tí ó fí ènìyàn ṣe ìgbékẹ̀lé rẹ̀, tí ó sì sọ elẹ́ran aara di agbára rẹ̀” (Jeremiah 7:5).
Àwọn ènìyàn tilẹ̀ ń sọ àwọn ògbọ́òtarìgì eléré sinimá àti àwọn eléré ìdárayá di òrìsà. Àwò-má-leè mójúkúrò ni wọ́n ni ibi gbọ̀ngàn orin níwájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní papa ìseré. À gbọ́dọ̀ kíyèsára níbi, a kò sọ pé sísìn tàbí bíbọ̀wọ̀ fún àwọn ènìyàn jẹ́ ẹ̀sẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà ọdàlẹ̀ nínú ẹ̀mí ni láti fẹ́ tàbí gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn ẹlẹ́ran ara ju Ọlọ́run.
Njẹ́ Ọlọ́run kò a tí so wá pọ̀ mọ́ ara rẹ̀ pẹ̀lú májẹ̀mú ayérayé? Abálájọ tí Kirísítì fí pé àwọn ènìyàn ni “ìran panságà àti ìbi”. Nítorí wọn kò fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọ̀kan wọn, wọn kò bu ọ̀wọ̀ tó pe fún tàbí kí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkan.
Oríṣìíríṣìí ọ̀nà ní ìbọ̀rìsà pín sí ní òní nípasẹ̀ àlàfọ tí ìtàpá sí Ọlọ́run mú wá. Ọlọ́run owú ní Ọlọ́run wa, òun nìkan ni ó sì fẹ́ gba ọkàn wa. ọ̀pọ̀lọpọ̀ tàbí ìgbọràn díẹ̀ wa kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ó fẹ́ ni wá pátápátá títí ayé. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ mú gbogbo ìbọ̀rsà kúrò nínú ayé wa, kí a sì tún ìpinnu ìfaraẹnijì wa pẹ̀lú baba wa ọ̀run ṣe. Bí ara rẹ̀ léèrè pé kíní àwọn òrìsà tí ó farasìn nínú ayé rẹ̀ gan, àti pé kíní ò lè ṣe láti pa wọ́n run pátápátá?
4.03.4 - Njẹ́ Ìgbàgbọ́ Kírísítẹ́nì Lòdì Sí Òfin Àkọ́kọ́?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù àti àwọn Mùsùlùmí faramọ́ ìtumọ̀ òfin mẹ́wàá dé àyè kan. Síbẹ̀ wọ́n ń fí àbùkù kan àwọn onígbàgbọ́ pé wọ́n ń tàpá sí òfin àkọ́kọ́ láti ara wọn. “Kẹ̀fèrí ní ẹ̀yìn onígbàgbọ́” ní orin wọn, “nítorí ẹ ń rú òfin àkọ́kọ́ tí ó sì ga jù, Ẹ ń sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run nípa kíkéde pé mẹ́ta ni wọ́n, àti pé ọ̀kan nínú wọn kú lórí àgbélèbu”. Àwọn Júù àti àwọn Mùsùlùmí ń fí èsùn ìsọ̀rọ̀-òdì kan àwọn onígbàgbọ́ nítorí wọ́n gbàgbọ́ nínú ìṣòkan mẹ́talọ̀kan mímọ́.
Báwo ní Jésù fúnrarẹ̀ ṣe fèsì sí irú ẹ̀sùn yìí? Ojoojúmọ́ ní Jésù ń kojú ìkọlu yìí láti ọwọ́ àwọn ọlọ́kan lile ènìyàn. Jésù yànàná ìjọ́kan pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀ dáradára “Emi àti Baba jẹ́ ọ̀kan” (Jòhánù 10:30). Kò fí ìgbà kan sọ pé “Ẹmi àti Baba jẹ́ méjì” ṣùgbọ́n, ọ̀kan! Lẹ́yìnorẹyìn, Ó sọ wí pé, “Mo ń gbé nínú Baba, Baba sì ń gbé inú mi”. Kí wọ́n tó mú un, o gbàdúrà fún àwọn atẹ̀lé rẹ̀, “kí wọ́n bà lè jẹ́ ọ̀kan bí àwa tí jẹ́ ọ̀kan” (Jòhánnù 17:22). Àwọn ọ̀rọ̀ yìí jẹ́rìí sí ìsọ̀kan mẹ́talọ̀kan. ọ̀pọ̀ wá di ẹyọ. Jésù jẹ́rìí sí ìsọ̀kan pípé rẹ̀ pẹ̀lú Bàbá. Òye òtítọ́ yìí kò ṣe é fí ìmọ̀ ìsirò wádìí “Ẹnikẹ́ni kò lè sọ pé Jésù ni Olúwa láìjẹ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́” (Kọ̀ríntì Kínní 12:3). Òtítọ́ ayérayé ni èyí tí a kò bá ní Ẹ̀mí Ọlọ́run, àwọn ohun tí Ẹ̀mí bí idán ni yóò rí.
Jésù sọ pé, “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ mi, yóò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, bàbá mi yóò sì fẹ́ ẹ, àwa ó sì sọ̀ ọ́ wá, a ó sì ṣe ilé wa pẹ̀lú rẹ̀” (Jòhánnù 14:23). Jésù ṣèlérí fún àwọn atẹ̀lé rẹ̀ pé Ẹ̀mí Mímọ́ yóò máa gbé inú wọn. Ó sì tún ní ìdàpò pípé rẹ̀ pẹ̀lú bàbá òrun dá wọn lójú, àti wí pé àwọn mẹ́jéèjì yóò máa gbé nínú ọkàn àwọn atẹ̀lé wọn. Àwọn onígbàgbọ́ kò gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kanṣoṣo tí ó fí ara rẹ̀ hàn bí Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́. A kò rú òfin kínní nípa jíjẹ́wọ ìsọ̀kan mẹ́talọ̀kan ṣùgbọ́n a ń mú un ṣe. A tí tú Ẹ̀mí Ọlọ́run sínú ọkàn wa nípasẹ̀ ìbálàjà pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ikú Jésù Kírísítì. Ẹ̀mí òtítọ́ náà gbà wá níyànjú láti pé Ọlọ́run ní Bàbá wa, kí á sì yá orúkọ rẹ̀ sí mímọ́.Bákannáà á gbàgbọ́ nínú Jésù, á sì fí gbogbo ọkàn wa fẹ́ ẹ nítorí pé, “a tú ìfẹ́ Ọlọ́run jade sínú ọkàn wa nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí á tí fún wa” (Roomù 5:5). Ó ṣe pàtàkì kí á mọ̀ pé, a pa ìsọ̀kan mẹ́talọ̀kan mímó mọ́ fún ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì di àtúnbí nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, tí kò si bìkítà láti wá òtítọ́ ńlá yìí.
Kùránì kò fí bẹ́ẹ̀ tako ìgbàgbọ́ mẹ́talọ̀kan tí àwọn onígbàgbọ́, dípò bẹ́ẹ̀, ó tako mẹ́talọ̀kan mímọ́, èyí tí gbogbo àwọn ìjọ onígbàgbọ́ pẹ̀lú tako. Kùránì tako mẹ́talọ̀kan bàbá, ìyá àti ọmọ (Sura al-Maida 5:116). Kùránì tún tako ìgbàgbọ́ tí ó sọ pé Jésù Ọmọ Màríà jẹ́ Ọlọ́run (Sura al-Maida 5:17, 72) tàbí ìkẹta nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lásán kókó òye tí mẹ́talọ̀kan mímọ́ nínú Bíbélì ní pé Ọlọ́run ni àpapọ̀ ìsọ̀kan, ìjọkan tí ayérayé, mẹ́talọ̀kan tí bàbá ẹni tí ó sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sì ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí. A lòdì sí mẹ́talọ̀kan bàbá nínú ara, ìyá àti ọmọ, àti ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run ni Kírísítì, ọmọ Màríà, A jẹ́wọ́ Ọlọ́run Bàbá, Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run kan ṣoṣo.
4.03.5 - Kíni Májẹ̀mú Láíláí sọ nípa Mẹ́talọ̀kan?
Májẹ̀mú láíláí ní àwọn ìtókasí tí dájú sí ìsọ̀kan Ọlọ́run nínú mẹ́talọ̀kan mímọ́. Kùránì pàápàá kò lè sẹ́ elẹ́yìí. Nínú (Ìwé Orin Dáfídì 2:7, 12), a kà nípa ìfihàn Ọlọ́run nípa Jésù ní ìwọ̀n egbẹrùn-ún kan ọdún kí á tó bíi. “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ó” Ó tún kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, “Ẹ fí ẹnu ko ọmọ ni ẹnu, kí òun má baà bínú, kí ẹ sì sẹ̀gbé ní ọ̀nà”. Ìwé Isaiah 7:14. Sọ ní ọgọ́run méje ọdún sáájú ikú Olúwa wa pé, “Nítorí náà Olúwa fúnrarẹ̀ yóò fún yín ní àmì; kíyèsi, Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pé orúkọ rẹ̀ ní Ìmmánúẹ̀lì, ìtumọ̀ èyí tíi ṣe, Ọlọ́run pẹ̀lú wa”.
Ìlérí tí ó ga mìíràn wà nínú ìwé (Isaiah 9:6). “Nítorí á bí Ọmọ kan fún wa, á fí Ọmọkùnrin kan fún wa; ìjọba yóò wàléjìká rẹ̀. A ó sì máa pé orúkọ rẹ̀ ní Ìyanu, Olùdámòràn, Ọlọ́run Alágbàra, Bàbá Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà”. Àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú Májẹ̀mú láíláí wọ̀nyí ń jẹ́rìí sí irúfẹ́ ẹni tí Jésù ń ṣe àti ìsọ̀kan pípé rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run Bàbá.
Nínú (Sámúélì Kéjì 7:12-14), a sèlérí fún Ọba Dáfídì pé ọ̀kan nínú irú ọmọ rẹ̀, tí ó jade láti ara rẹ̀ yóò sì tún jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ní ìgbà kan náà. Láti ìgbà náà, orúkọ mìíràn fún Mèsáyà tàbí Ọmọ Dáfídì ni a mọ̀ sí Ọmọ Ọlọ́run. (Orin Dáfídì 110:1), sọ pé, “Olúwa sọ fun Olúwa wa, jókòó ní ọwọ́ òtún mí títí Èmi ó fí sọ àwọn ọ̀tá rẹ̀ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀”. Njẹ́ Olúwa méjì ni ó wà bi? Rara! síbẹ̀, ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe àfihàn ìsọ̀kan tí ó pé láàárín Ọlọ́run Bàbá, Ọlọ́run Ọmọ àti Ọlọ́run Ẹ̀mí Mímọ́. Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ní Ọlọ́run tí ń fí ọ̀rọ̀ jẹ́rìí pé kìí ṣe òun nìkan, “Ẹ jẹ́ kí á dá ènìyàn ní àwòrán ara wa, ní àwòrán wa” (Jẹ́nẹ́síìsì 1:26). Èyí fí hàn gbangba pé, ẹ̀rí ìsọ̀kan tí mẹ́talọ̀kan mímọ́ kí í ṣe àròsọ tí onígbàgbọ́ gbé kalẹ̀. Yálà bẹ́ẹ̀ òtítọ́ tí Ọlọ́run tí fí hàn ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún ọdún sáájú ìbí Jésù ni, Tani ó a lè lòdì sí ìfihàn Ọlọ́run?
4.03.6 - Kùránì tọ́kà sí Kírísítì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run
Kìí ṣe àwọn ìwé òfin, Orin Dáfídì àti àwọn Wòólì nìkan ní ó jẹ́rìí sí ìsọ̀kan Ọlọ́run Bàbá, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́, ṣùgbọ́n àwọn ẹsẹ kan wà nínú Kùránì pàápàá tí ó fí ìdí ẹ̀rí àwọn onígbàgbọ́ múlẹ̀. Tí gbogbo ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí yóò bá ka Kùránì pẹ̀lú ọkàn tó sí irú wọn yóò rí àrídájú àwọn ẹsẹ tí ó sọ nípa ìbí Jésù láti Ọmọ Maria. Nínú ọ̀rọ̀ Allahu ni a bí Jésù láísí ọwọ́ ẹnikẹ́ni níbẹ̀. Allahu fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ sínú Maria Wúndíá, a sì tí ipa èyí bí Jésù (Sura al-Anbiya 21:91 àti al-Tahrim 66:12).
Sura Al-Imran 3:45; Al-Nisa 4:171 àti Maryam 19:43) fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jésù jẹ́ ọ̀rọ̀ Allah ní àwòrán ènìyàn àti Ẹ̀mí láti òdọ̀ rẹ̀. Àwọn ẹsẹ Kùránì yìí ni àtúnwí tí àwọn ẹlẹ́sìn Ìsíláàmù tí ìwé ìhìnrere tí Jòhánù, “ọ̀rọ̀ náà sì di ara, ó sì ń bá wa gbé, àwa sì tí rí ogo rẹ̀” (Johánù 1:14).
A kà nínú (Sura Al-Bagara 2:87, 352 àti Al-Maida 5:110) pé á tí ró Kírísítì ni agbàra nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ láti mọ àwòrán ẹyẹ pẹ̀lú amọ̀, kí ó sì sọ ọ di ààyè nípa fífẹ́ atẹ́gun sí i. Ó ṣe dídá ara fún àwọn afọ́jú àti àwọn adẹ́tẹ̀, ó sì mú kí òkú di alààyè pípa àsẹ Àlláhù ìbásepọ̀ nínú ìse láàárín Àlláhù, Kírísítì àti Ẹ̀mí Mímọ́ yìí ni ó hàn gbangba nínú Kùránì. Kíló wá dé tí àwọn Mùsùlùmí fí ń sọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run àti Mèsáyà rẹ̀?
A kà nínú (Sura Maryan 19:21) pé “A ṣe é ní àmì fún àwọn ènìyàn àti àánú fún àwa” ohun máa ń ya ènìyàn lẹ́nu pé “Àlláhù nínú Kùránì máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run púpà, ó sì pé Kírísítì ní àánú láti ọ̀dọ̀ Àlláhù”. Èyí túmọ̀ sí pé òun ni ohun náà nípa ìṣe pàtàkì Ọlọ́run.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí nínú májẹ̀mú láíláí àti kùránì fí ìdí ìsọ̀kan mẹ́talọ̀kan hàn. A rọ̀ wá láti darapọ̀ mọ́ àwọn áńgẹ́lì láti fí iyìn fún Ọlọ́run, “Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ ni Olúwa Ọlọ́run àwọn Ọmọ ogun, gbogbo ayé kún fún ogo rẹ” (Isaiah 6:3). Àwítúnwí “Mímọ́” ní ìgbà mẹ́ta túmọ̀ sí pé, Bàbá jẹ́ Mímọ́, Ọmọ jẹ́ Mímọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ pẹ̀lú sì jẹ́ Mímọ́. Wọ́n sì jẹ́ ọ̀kan nínú gbogbo ìjẹ́mímọ́.
4.03.7 - Ìgbàgbọ́ àwọn Onígbàgbọ́ nípa Ìjọ́lọ́run Jésù
Àsọdùn kọ́, nígbà tí gbogbo àwọn Àpósítélì jẹ́rìí pẹ̀lú ohun kan nípa ìjọ́lọ́run kírísítì, pẹ̀lú ewu ikú, Pòòlù jéwọ́ ní gbangba pé, “Kírísítì ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò rí” (Kòlósè 1:15) Jòhánù gbà pé, “ọ̀rọ̀ náà di ara, ó ń bá wa gbé, àwa sì rí ogo rẹ. ogo bíi tí ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Bàbá, tí ó kún fún oorẹ-òfẹ́ àti òtítọ́” (Jòhánù 1:14). Àpósítẹ́lì Petérù jẹ́rìí pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà,” Ọmọ Ọlọ́run alààyè (Matiu 16:16).
Àwọn ìgbìmọ̀ Nicaea sọ nípa ìgbàgbọ́, àwọn Kírísítẹ́nì pé, “Kírísítì ni Ọlọrun tí Ọlọrun, ìmọ́lẹ̀ tí ìmọ́lẹ̀, Ọlọ́run náà tí Ọlọ́run náà, ọmọ bíbí tí a kò dá, tí ó ni ẹ̀dá ara kan pẹ̀lú Bàbá.
Àwọn Júù àti àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ń fi gbèdéke lé agbára àìlópín ọlọ́run pẹ̀lú ìgbàgbọ́ líle wọn. Ta ni ó lè kọ ifihàn Ọlọ́run bí ó tí wa? Ta ni ó ní ètó láti sọ pé Olọ́run kò gbọ́dọ́ ní ọmọ, kí ó sí fíi rúbọ̀ láti gba aráyé là? Ọlọ́run kò sè é mú. Kiristi ti wà sáájú ìsẹ̀dá ayé. Ó gbé àwòrán ènìyàn wọ̀ láti bá aráyé lajà pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sí dá àlàáfìà wa ọrun padà. Kiristì dí ènìyànn ta gba aráyé là. Jòhánù onítẹ̀bọmi sọ nípa ìpè Ọlọ́run yìí nígbà tí ó sọ pé “Èyí ni ọ̀dọ́ àgùntàn Ọlọ́run ẹni tí ó kó ẹ̀sẹ̀ ayé lọ” (Jòhánù 1:29). Nípasẹ̀ ẹlẹ́yìí, a sọ wá di ọmọ, a sì ń pé Ọlórún ní Baba wa ọ̀run, níwọ̀n ìgbà tí a ti dárí ẹ̀sẹ̀ wa jì. Kírístì tí sètò ìgbàlà ńlá fún gbogbo ènìyàn, kìí ṣe fún onígbàgbọ́ níkan. Ìgbàà rẹ̀ wà fún àwọn ẹlẹ́sìn Híńdì, Búdì, àwọn Júù, àwọn Mùsùlùmí àti àwọn tí kò gbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà. Ó fún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ́lé ẹ pátápátá tí ó sì gbàá ní Olúwa àti Olùgbàlà wọn ní iyè tí kò nípẹ̀kùn. Ọmọ ṣe atọ̀nà wa dé ọ̀dọ̀ Baba, Baba sì fí wa mọ ọmọ. Ọlọ́run tí fí ara rẹ̀ hàn ní àkókò ìtẹ̀bọmi Jésù ní odò Jọ́dánì. “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi” (Matiu 3:17). Ta ni ó dá ohùn ọ̀run dúró.
4.03.8 - Kí ni Ẹ̀te Òfin Àkọ́kọ́?
Ète Òfin Àkọ́kọ́ ni láti fẹ́ Ọlọ́run. Ànfààní yìí ni Mósè fíhàn nínú òfin tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, “Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti gbogbo ipá rẹ̀” (Deuteronomy 6:5). Ó sàn fún wa láti fẹ́ Ọlọ́run kí á sì wà ní ìsọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀ tàbí kí á kóríra rẹ̀, kí á sì máa gbé lòdìí sí ìfẹ́ rẹ̀. Tí bá fẹ́ Ọlọ́run, a ó máa ronú nípa rẹ̀, a ó máa fẹ́tí síi, a ó máa ṣe ohun tí ó fẹ́, gbé ìgbé ayé wa fún un, ọkàn wa yóò sì máa sàférí rẹ̀ bí ọkàn ìyàwó ṣe máa ń fà sí ọkọ rẹ̀ tí òun yóò sì máa ni fẹ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó sì ń sògò nínú ìgbéraga rí ara wọ́n bí Ọlọ́run kékeré, kíkẹ̀yin sí Ọlọ́run yóò mú kí wọ́n gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n yóò sì subú sínú ìbínú Ọlọ́run nípasẹ̀ ọ̀kan líle wọn.
Síbẹ̀ gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run ń gbé nínú ẹ̀mí Ọlọ́run. Wọ́n gbà ìdáríjì fún gbogbo ẹ̀sẹ̀ wọn, wọ́ sì ń rìn nínú agbára ẹ̀mí mímọ́. A sà wọ́n padà nínú àwòrán baba wọn, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ń gbàdúrà lójójúmọ́ pé kí orúkọ di mímọ́ nínú ayé wọn àti ìdílé wọn. Tí a bá fẹ́ Ọlọ́run nítòótó, a ó yípadà síi, a ó sì gbà oore-ọ̀fẹ́ kún oore-ọ̀fẹ́. A ń ní ìrírí ìwẹ̀nùmọ́ ọkàn lójoójúmọ́, a ń gbé ninú òmìnira àwọn ọmọ Ọlọ́run, a sì ń kópa nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀mí rẹ̀.Àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run ni tòótọ́ takété sí ìbọ̀rìsà nínú àyé wọn, wọ́n sì dúró sinsin nínú májẹ̀mú tuntun, èyí tí a fí àsírí rẹ̀ hàn nínú àkòrí ìgbàgbọ́ àti ìgbé ayé wa. “Ìfẹ́ ni Ọlọ́run, ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé nínú ìfẹ́ ń gbé nínú Ọlọ́run, àti Ọlọ́run nínú rẹ̀” (Jòhánù Kínni 4:16).